You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Speaker Kevin McCarthy: Ilé aṣòfin Amẹ́ríkà yẹ àga nìdí Kevin McCarthy, Olórí ilé náà
Kevin McCarthy ti padanu ipo rẹ gẹgẹ bi olori ile aṣojuṣofin -igba akọkọ ree tí olori ile to jẹ ẹgbẹ Republican yoo fidirẹmi ninu idibo a-ko-ni-igbagbọ-ninu-rẹ-mọ to waye ni gbagede ile aṣofin naa lọjọ Iṣẹgun.
Ibo igba o le mẹrindinlogun (216) si ibo igba o le mẹwaa (210) ni wọn fi yọ ọ gẹgẹ bi olori ọmọ ẹgbẹ to pọju nile labẹ aṣofin ọhun labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Republican ni ilẹ Amẹrika.
Awọn kogberegbe kan ninu ẹgbẹ rẹ lo dibo yọ ọ lẹyin ti wọn fi ẹsun kan an pe o lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọmọ ile asofin agba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat lati ṣe iranwọ fawọn ileeṣẹ ijọba kan.
A ko le sọ pato ẹni tí yoo soju gẹgẹ bi Olori ile bayii.
Ogoji ọjọ ni apapọ ile ni lati fẹnuko ki edeaiyede ma baa bẹnu ijọba kọlẹ lorilẹede naa.
Iṣẹ nla wa niwaju ẹnikẹni to ba gba ipo Olori ile lẹyìn rẹ
Aṣofin ẹgbẹ oṣelu Republican to n soju Florida, Matt Gaetz, to tun jẹ wọlewọde Trump lo lo irinṣẹ awọn aṣòfin kan ti wọn kìí sábà lo lati fi da aba lọjọ Aje pé ki Olori ile,McCarthy fi ipo silẹ.
O fẹsun kan an pe o ṣe adehun bonkẹlẹ pẹlu White House lati tẹsiwaju ipese iranwọ fun Ukraine pẹlu bi idunadura ṣe n lọ lọwọ l'ọna ati dènà ki ijọba ma dẹnukọlẹ lopin ọsẹ.
Ọgbẹni McCarthy ni oun ko jẹbi ẹsun yi.
Níbi ipade kọkọ awọn oloselu Republican lọjọ Iṣẹgun lẹyìn to padanu ipo rẹ Ọgbẹni McCarthy sọ pe n ko gbero lati du ipo Olori ile mọ.
O pada sọko ọrọ sí Ọgbẹni Gaetz to ni "ka rimi lo n ba kiri."
"Wọn ni mi sinu ni,ko ni nkankan ṣe pẹ̀lú ìnáwó"
Bayii ni McCarthy ṣe salaye fún awọn akọroyin.
O ní awọn e-mail kan ti Ọgbẹni Gaetz fi ránṣẹ nipa inawo lasiko aigbora-eni-ye to n lọ lọwọ "kò pọnle gẹgẹ bi ọmọ ile aṣofin"
O fi kun pe awọn alakatakiti ọmọ ẹgbẹ to pawọpọ yọ òun nipo naa kii ṣe oniwa pẹlẹ.
Loṣu Kini lo di Olori ile lẹyìn idibo wakati mẹẹdogun níbi tí Ọgbẹni Gaetz ati awọn alatako mii kọ lati ṣe atilẹyin rẹ.
Kí o ba le ri atilẹyin wọn, Ọgbẹni McCarthy gba pé ki ọmọ ile kan ṣoṣo lanfaani lati da aba pé ki wọn yọ oun nipo.
Eyi gaan sí ní ohun tí Ọgbẹni Gaetz pada ṣe lẹhinwa.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Republican 210 lo satilẹyin fún t'awọn mẹjọ mii sí dibo tako pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat ninu idibo to waye lọjọ Iṣẹgun.
Ibo àtakò kan to jẹ iyalẹnu leyi to wa lati ọdọ ọmọ ẹgbẹ Republican to n soju South Carolina Nancy Mace.
O sọ lẹyìn idibo pé " Mo n wa Olori ile ti yoo sọ ootọ fún awọn ọmọ orilẹede Amẹrika,ti ile aṣofin ati awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji yóò sí le fi ọkàn tan "
Olori ọmọ ẹgbẹ Democrat nile aṣofin Hakeem Jeffries ti ṣaaju sọ ninu iwe kan to kọ s'awọn akẹgbẹ rẹ pe oun ko ni pese ibo tí McCarthy nilo ko fi ma fidirẹmi.
Aṣòfin obìnrin Pramila Jayapal,to n soju iwọ oorun Ariwa Washington naa sọ ọrọ ṣaaju idibo pe "ẹru tí wọn di kalẹ awọn náà ni wọn onfi orí arawọn rú."
Nise ni ile to kun fọfọ pa lọọlọ bi àwọn aṣòfin ṣe n retí èsì idibo.
Steve Womack aṣofin to n soju Arkansas labẹ àsìá ẹgbẹ Republican lo kede pe "bayii ipo Olori ile ti ṣi silẹ"
Ṣaaju aarẹ tẹlẹ ìyẹn Donald Trump di sọ lójú opo ayelujara pe ẹgbẹ Democrat lo yẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ Republican doju ija kọ dipo arawọn.
Aṣoju Republican lati North Carolina Patrick McHenry, to dibo atilẹyin fún Ọgbẹni McCarthy ni wọn fí ṣe adele Olori ile.
O kede isinmi ọsẹ kan ki ilé tó lè pada wa sí ijoko.
Ko daju bayii boya yoo ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbara to bá ipo náà wa lati le fi dari idibo.
Bo ti lẹ jẹ pe wọn lero idibo mii lati yan olori ni ọjọ kọkànlá oṣù kẹwàá.
Aṣoju Republican Louisiana Steve Scalise ati to Minnesota Tom Emmer ni orúkọ wọn jẹyọ lati rọpo Ọgbẹni McCarthy.
Ko ti sì eyi to sọ ninu wọn pe oun nifẹ sí ipo ọhun.
Ki ni ileeṣẹ aarẹ Amẹrika sọ si iṣẹlẹ naa?
Akọwe ìpolongo White House Karine Jean Pierre sọ ninu atẹjade kan pe aarẹ Joe Biden lero pé ile yoo tete yanju idibo Olori tuntun tori pe "awọn ipenija to n koju ilẹ wa ko le duro pẹ"
Àwọn Olori ile ẹgbẹ Republican meji to jẹ k'ẹyin Paul Ryan ati John Boehner fi ipo silẹ nitori ede aiyede pẹlu awọn akẹgbẹ wọn.
Ẹẹmeji pere ṣaaju tẹlẹ ni wọn lò Ilana aba tí wọn fi yọ McCarthy.
Ni 2015 ati 2010 ni wọn mu aba yi wa amọ pabo lo já sí ní igbà mejeeji.
O dori akayin McCarthy ni akara d'epo ti wọn sì ri aba naa lo lati fi yẹ aga nidi rẹ.