You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òṣèré tíátà, Tope Osoba rawọ́ ẹ̀bẹ̀ lórí àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn tó ń ba fínra
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Tope Osoba ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣe ìrànwọ́ fún òun lórí ààisàn jẹjẹrẹ ọyàn tó ń bá a fínra.
Nínú fídíò kan tí òṣère náà fi sójú òpó Instagram lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ló ti ṣàfihàn ara rẹ̀ lórí ìbùsùn ilé ìwòsàn.
Tope Osoba lóri ìkànnì náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti ràn-án lọ́wọ́ nípa fífun ní ẹ̀bùn owó àti àdúrà tí wọ́n fi ń ránṣẹ́ si àmọ́ tó ní òun ṣì nílò owó láti fi ṣe ìtọ́jú ara òun síi.
Ṣáájú ni gbajúmọ̀ òṣèré, Foluke Daramola ti kọ́kọ́ gbé fídíò kan sájú òpó Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ díẹ̀ sẹ́yìn pé òṣèré kan wà tó nílò owó mílíọ̀nù mẹ́wàá sí mílíọ̀nù méjìlá náírà láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn.
Nínú fídíò náà ni Foluke Daramola ní òun kò lè ṣe àfihàn ojú òṣèré náà nítorí ó ti ṣe iṣẹ́ abẹ lórí jẹjẹrẹ ọ̀hún nígbà kan rí àmọ́ àwọn dókítà ní ó ṣì nílò láti ṣe iṣẹ́ abẹ mìíràn nítorí jẹjẹrẹ náà kò ì tiì tán pátápátá.
Ó ní òṣèré ná[kò bá fi ojú hàn àmọ́ ó ní àwọn ìyáìyá tó ti dàgbà tí ìròyìn náà yóò sì bàwọ́n lọ́kàn jẹ́, tí nǹkan sì lè ṣe wọ́n tí wọ́n bá gbọ́ nǹkan tó ń ṣe é.
Ṣùgbọ́n nígbà tó di ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá ni Foluke Daramola gbé fídíò Tope Osoba níbi tó ti ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn èèyàn láti ran òun lọ́wọ́.
Tope Osoba nínú fídíò náà ní òun ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwon èèyàn tó ti ran òun lọ́wọ́ tí àwọn fi ṣe iṣẹ́ abẹ.
Ó ní òun ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ nítorí àwọn ìtọ́jú kan wà tí òun nílò láti ṣe lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà àmọ́ tí kò sí owó lọ́wọ́ òun mọ́.
Ó ní ó ṣe pàtàkì fún òun láti ṣe àwọn ìtọ́jú náà kí ara òun tó lè bọ̀ sípò bó ṣe yẹ.