Gbogbo ìlérí tí mo ṣe lásìkò ìpolongo ìbò ni mà á múṣe - Aiyedatiwa
Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Orimisan Aiyedatiwa ní ìjáwe olúborí òun níbi ètò ìdìbò náà túmọ̀ sí pé òun gbọdọ̀ mú àlékún bá iṣẹ́ tí òun ń gbé ṣe fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà.
Aiyedatiwa ló sọ èyí nígbà tó n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nààijíríà, INEC kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò sípò gómìnà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ó ní gbogbo ìbú àti òró ìpínlẹ̀ Ondo ni òun ṣe àbẹ̀wò lásìkò tí òun ń ṣe ìpolongo ìbò, tí èyí sì jẹ́ kí òun mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà ń fẹ́.
Ó sọ pé kí àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà lọ fi ọkàn balẹ̀ nítorí òun máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn èèyàn náà rí èrè ìṣèjọba àwaarawa.
Ó fi kun pé gbogbo bí nǹkan ṣe rí ní àwọn agbègbè tí òun dé lásìkò ìpolongo ìbò ni òun mọ̀ tí òun yóò sì ri pé gbogbo àwọn tó nílò àtúnṣe ni ọwọ́ ìjọba yóò dé.
“Ní gbogbo ìlú tí mo dé lásìkò ìpolongo ìbò, mo rí bí ọ̀nà wọn ṣe rí, mo rí bí àyíká tí wọ́n ń gbé ṣe rí, mo gbọ́ oùn wọn, tí mo sì fèsì sí gbogbo ìbéèrè wọn.
“Mo ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n ní ìrètí nínú mi ni wọ́n ṣe dìbò fún mi, gbogbo nǹkan tí mo ṣèlérí lásìkò ìpolngo ìbò náà ni mà á ṣe fún wọn.”