Ọlọ́pàá míì tún rí ẹ̀wọ̀n he lórí ikú George Floyd l'Amẹ́ríkà

Ilé ẹjọ́ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti sọ ọlọ́pàá Minneapolis kan, J Alexander Kueng sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta àbọ̀ fẹ́sùn wí pé ó lọ́wọ́ nínú ikú George Floyd.

Nínú oṣù Kẹwàá ọdún yìí ni Kueng gbà wí pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn lílọ́wọ́ nínú ikú Floyd.

Kueng wà lára àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó kúnlẹ̀ sí ẹ̀yin George Floyd ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà nínú oṣù Karùn-ún ọdún 2020 títí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.

Ikú Floyd fà awuyewuye káàkiri àgbáyé lọ́dún náà lọ́hùn-ún nítorí ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni àwọn ọlọ́pàá náà hù.

Nínú oṣù kẹrin ọdún 2021 ni ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ sọ ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ rí kan, Derek Chauvin sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún fẹ́sùn wí pé ó kúnlẹ̀ lé Floyd lọ́rùn ju wákàtí mẹ́sàn-án lọ.

Nínú oṣù kejì ọdún yìí ni ilé ẹjọ́ ní Kueng àti àwọn ọlọ́pàá méjì mìíràn Thomas Lane àti Tou Thau jẹ̀bi wí pé wọn kò kọbi ará sí ìlera Floyd.

Fídíò tó gba orí ayélujára nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ṣàfihàn Kueng àti Lane tí wọ́n ń ran Chauvin lọ́wọ́ láti mú Floyd dání.

Bákan náà ni wọ́n tún gbìyànjú láti lé àwọn ènìyàn kúrò kí wọ́n má kà á ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sílẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹjọ́rò ẹbí Floyd ní ìdájọ́ dùn mọ́ àwọn nínú nítorí ó túmọ̀ sí pé Floyd rí ìdájọ́ òdodo gbà.

Wọ́n ní ọkàn àwọn n balẹ̀ báyìí wí pé ikú Floyd kò lọ lásán.