Ilé ìgbìmò aṣofin Niger bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti fòfin dé ìbálòpọ̀ láàárín akọ sí akọ.

Ẹgbẹ kan ninu awọn aṣofin ni orilẹede Niger ti ṣe atilẹyin fun abadofin ti o n pe fun ifiyajẹ ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abo. Pupọ ninu awọn eeyan ni orilẹ ede Niger lo jẹ Musulumi, amọ ti ko sí ofin kankan ti o dena ibalopọ laarin ẹniyan ara kan naa bayii. Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ni orilẹede naa sọ pe ibalopọ-laarin eya ara kan naa lodi si ẹsin ati aṣa orilẹ-ede naa.

Abadofin naa ni Nana Djibou Harouna gbe kalẹ niwaju alakoso Ile-igbimọ aṣofin nibi ijokoo ile naa to waye ninu ọsẹ.

Iyaafin Harouna ṣapejuwe ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abo gẹgẹ bi “iṣoro ti o kan gbogbo awujọ ni orilẹ-ede naa."

O sọ pe awọn ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun awọn ọmọ orilẹ-ede naa lati mọ iha ti wọn kọ ki awọn to gbe aba ọhun siwaju ile.

O fi kun pe awọn ti gba atilẹyin awọn ara ilu, ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede naa si fọwọsi.

Ko i tii si gbedeke igba tawọn aṣofin naa maa fi jiroro lori abadofin ọhun ati iru ijiya ti wọn fẹ fi sinu ofin naa.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ile-ẹjọ kan ni Maradi da awọn ọdọbinrin meji lare fun awọn ẹsun to jọmọ ibalopọ laarin obinrin si obinrin nitori ko si ofin ti o han gbangba to gbogun ti ibalopọ laarin eya ara kan naa.