You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣíṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rọ̀ mí lọ́rùn àmọ́ ọ̀kánjúà ni mo fi bẹ̀rẹ̀ "make up", ibi tó bámi dé rèé - Gbenga Olabisi
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní tí ọmọdé bá máa jẹ́ àṣàmú, kékeré ló ti máa ń ṣẹnu ṣámúṣámú.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ arákùnrin yìí, Oluwagbenga Olabisi rí nítorí tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo lòwò arákùnrin yìí gan ló yẹ kí a máa pè bẹ́ẹ̀.
Ìdí ni pé kò fẹ́ẹ̀ sí okoòwò kan tí Olabisi kò fẹ́ẹ̀ dágbálé, bí ó ṣe jẹ́ olópò tó ń dáná lóde àríyá náà ló tún máa ń kọrin.
Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí Olabisi tún máa ń ṣe iṣẹ́ mímú gbọ̀ngàn ayẹyẹ rẹwà ẹyọ tí a mọ̀ sí decoration.
Bákan náà ló tún máa ń ṣe ojú lóge ìyẹn "make up", ṣe adarí ètò ayẹyẹ èyí tí a mọ̀ sí MC.
Pabambarì rẹ̀ ni pé Gbenga Olabisi jẹ́ akọ́ṣẹ́mọsẹ́ nípa ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ nítorí ohun tí ó lọ kọ́ nílé ẹ̀kọ́ gangan nìyẹn.
Nígbà tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò rẹ̀, Olabisi ni láti ìgbà tí òun ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá, tí òun wà ní ipele àkọ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ girama ni òun ti bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ yìí díẹ̀ díẹ̀.
Olabisi ni iṣẹ́ àwọn tó ń mú gbọ̀ngàn ayẹyẹ rẹwà ni òun fi bẹ̀rẹ̀ nígbà náà kì òun tó tẹ̀síwájú láti lọ kà nípa ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga.
Ó ní láti ìgbà náà ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi gbogbo àwọn iṣẹ́ mìíràn èyí tí òun ń ṣe kún-un tí òun sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níbi tí òun bá àwọn iṣẹ́ náà dé lónìí.
Bákan náà ló gba àwọn ọ̀dọ́ lámọ́ràn láti má jókòó tẹtẹrẹ, kí wọ́n máa sọ́nà bí ọ̀nà wọn yóò ṣe tètè là láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wojú ẹnikẹ́ni.
Ó fi kun pé bí ènìyàn bá ń wá ọ̀nà onírúurú ìpèníjà ni onítọ̀hún máa là kọjá nítorí náà kì àwọn ọ̀dọ́ òde òní ma jẹ̀ẹ́ kí ìpèníjà wọn da omi tútù sí wọn lọ́kàn láti ṣe òun tí ọkàn wọn ń fẹ́.