You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn agbébọn ṣekúpa ẹ̀gbọ́n "Pawpaw" ṣá kọmíṣọ́nà ládàá ní Imo
Awọn afurasi agbebọn kan ti ṣekupa ẹgbọn gbajugbaja elere tiata, Osita Iheme ti ọpọ mọ si PawPaw ni Ubomiri nigba to kọwọ rin pẹlu kọminsọna Martin Eke nipinlẹ Imo.
Chidi Iheme ni awọn agbebọn naa sina bọlẹ fun, ti wọn si tun fi ada ṣe kọmisọna naa lese nigba ti wọn lọ ṣe iponlogo ibo fun oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ile asofin, Akarachi Amadi, ni ijọba ibilẹ Mbaitoli
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC ni awọn agbebọn ni wọn furasi pe wọn jẹ awọn ẹgbẹ adijagbara IPOB, ti wọn koruju si bii awọn eeyan ipinlẹ Imo ṣe kọ eti kun si ikede konile gbele ti wọn fi sita.
Nigba to ba awọn mọlẹbi kẹdun, agba oloselu ni ipinlẹ Imo, Darlington Irobi ni o ṣe ni laanu pe awọn agbebọn ọhun pinnu lati gbe igbesẹ naa buburu yii.
O ni bu ẹnu atẹlu bii awọn agbebọn naa ṣe kọlu Kọminsọna, ti wọn si fi ada saa ni isakusa, ti wọn si tun ṣekupa Chidi Iheme.
Ninu atẹtaje to fi lede fun awọn akọroyin, Irobi koroju si ikọlu naa, to si gba adura fun awọn mọlẹbi ologbe ati awọn to farapa.
Bakan an nipinlẹ Imo, awọn agbebọn ji oyibo meji to jẹ ọmọ orilẹede Germany lọ lẹyin ti sina bolẹ fun awọn ọlọpaa meji to n ṣo awọn arinrin ajo naa.
Awọn ara agbegbe to ba ileeṣẹ iroyin alabẹle sọrọ ni awọn agbebọn ọhun wa pẹlu ọkọ mẹta, ti wọn si ṣekupa awọn ọlọpaa ki wọn to palẹmo awọn oyinbo naa.
Gbogbo akitiyan wa lati ba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo jasi pabo.