Ohun tí a mọ̀ nípa àbẹ̀wò Sunday Igboho sí Olubadan Ladoja, ohun tó sọ nípa yíyọ orúkọ rẹ̀ kúrò nínú àwọn tí ìjọba ń wá

Oríṣun àwòrán, koiki media
Ọkan gboogi ninu awọn to n ja fun idaduro ẹya Yoruba labẹ orilẹede NAijiria,Oloye Sunday Adeyemo ti awọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti se abẹwo si Olubadan ti Ilẹ Ibadan, Kabiyesi Ọba Rashidi Adewolu Ladoja lonii ọjọ-aje.
Igboho ṣe abẹwo yii lati dupẹ lọwọ ọba alade naa fun atilẹyin rẹ lẹyin to ni ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ti yọ orukọ oun kuro lara awọn ọdaran ti orilẹede n wa nipasẹ ilakaka awọn ọbalaye kan nilẹ Yoruba
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Sunday Igboho, iyẹn Ọgbẹni Olayomi Koiki gbe jade, o ṣe alaye wi pe abẹwo naa to waye ni ile Olubadan to wa ni agbegbe Bodija ni ilu Ibadan ni akọkọ lẹyin to ni wọn fun un ni ominira rẹ pada.
BBC News Yoruba ko tii fi idi iroyin naa mulẹ boya lootọ ni ijọba ti yọ orukọ Sunday Igboho kuro ninu iwe awọn ọdaran ti ilu n wa, tabi bẹẹkọ; amọṣa eekan ọmọ Yoruba naa dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu fun igbesẹ naa.

Oríṣun àwòrán, koiki media
Atẹjade to tẹ ikọ ile-iṣẹ BBC Yoruba lọwọ tunbọ salaye wipe Olubadan, Ọba Rashidi Ladoja, Ọọni ile-Ifẹ, Kabiyesi Ọba Adeyeye Ogunwusi ati Olugbọn ti Orile-Igbọn, Ọba Francis Alao ko ipa ribiribi lori igbese bi Sunday Igboho ṣe di ominira.
Nigba ti o n sọrọ nibi abẹwo ẹṣe modupẹ ọhun, Sunday Igboho gbe osuba kare fun Olubadan Ladoja latari iranlọwọ ti wọn ṣe fun un nigba iṣoro.
O ṣe afikun pe inu awọn ọmọ Yoruba nile, loko ati ni ẹyin odi n dun wi pe Ijọba apapo darijin ohun ti ohun si le pada si orilẹede Naijiria lai bẹru.
Nigba ti wọn sọrọ, Kabiyesi Olubadan Ladoja ṣe adura fun Sunday Igboho ati awọn mọlẹbi rẹ, ti wọn si rọ'ọ lati ni ireti.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Sunday Igboho lewaju awọn iwọde kan tako wahala awọn darandarn to n gbẹmi araalu lawọn agbegbe kan nilẹ Yoruba nigba naa. Eyi ti ọpọ fi n pe fun idaduro ilẹ Yoruba labẹ Naijiria nigba naa; ki o to di wi pe awọn agbofinro kọlu ile rẹ nilu Ibadan ni ọjọ kinni, oṣu keje, ọdun 2021 nibi ti ẹmi ti sọnu, ti ọpọlọpọ dukia si bajẹ.
Lẹyin eyii ni O sa kuro ni Naijiria ki wọn to mu u lorilẹede Benin ti wọn sit u u silẹ lẹyin akoko diẹ.














