Emi ati Ṣeyi Makinde ko ni adehun lati fa kọmisana kankan kalẹ - Florence Ajimobi

Arabinrin Florence Ajimobi ti o jẹ aya Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, oloogbe Abiola Ajimobi, bu omi pa ahesọ ọrọ to n lọ kaakiri wi pe ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti fun un ni anfani lati fa Kọmisana kalẹ fun saa ikeji ijọba rẹ.

Ṣaaju ni iwe iroyin kan n tọka rẹ lori ayelujara wi pe Makinde fun idile Ajimọbi ni anfani lati fa Kọmisana meji kalẹ ggẹ bi ara ọmọ igbimọ iṣejọba tuntun ti gomina naa n ṣa jọ fun ibẹrẹ saa rẹ keji lori oye.

Ṣugbọn atẹjade kan ti Bolaji Tunji, akọwe iroyin fun Arabinr Florence Ajimọbi, fi sita ṣalaye pe irọ lasan ati pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa.

Atẹjade naa ni, "Iroyin yii ṣe ajọji si wa. A n fi idi rẹ mulẹ wi pe ko si iru adehun bẹẹ nigba kankan.

Arabinrin Ajimọbi fi ọwọ apọnle mu Gomina nitori o ni awọn ohun amuyẹ adari rere gẹgẹ bi o ṣe n gbiyanju lati mu iṣokan waye ki alafia le jọba ni ipinlẹ naa, ṣugbọn awọn olubi ẹda lo n gbe iroyin ofege kiri".

Aya gomina ana ni ipinlẹ yọ naa wa ke si awọn to n fọn iroyin ofege naa kaakiri pe ki wọn lọ ree ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ nitori ko si ere meji to le ti inu rẹ jade ju edeaiyede lẹgbẹ oṣelu APC.