Èèyàn mẹ́tàdínlógún jáde láyé bí afurasí kan ṣe ṣíná ìbọn fún wọn mọ́lé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀ èdè South Africa ní àwọn ń wá àwọn afurasí ọ̀daràn tó ṣokùnfà ikú èèyàn mẹ́tàdínlógún lásìkò tí wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún wọn .

Ọlọ́pàá ní agboolé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú Lusikisiki, ìlà oòrùn Cape ní ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn náà ti wáyé.

Wọ́n ní àwọn afurasí apaayàn náà ṣokùnfà ikú obìnrin méjìlá àti ọkùnrin kan ní ilé kan, tí wọ́n sì pa obìnrin mẹ́ta mìíràn àti ọkùnrin ní ilé kejì.

Bákan náà ni wọ́n fi kun pé ẹni tó farapa wà ní ẹsẹ̀ kan aye, ẹsẹ̀ kan ọ̀run ní ile ìwòsàn tó wà.

Mínísítà fọ́rọ̀ ọlọ́pàá South Africa, Senzo Mchunu ni ìgbàgbọ́ wà pé yóò yọjú sí agbègbè ìkọlù ọ̀hún.

Iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní South Africa ní mọ́lẹ́bí àti alábàágbélé ni àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìlú Nyathi, Ngobozana ní Lusikisiki.

Wọ́n ní àwọn èèyàn náà ló péjọ sáwọn ilé náà láti gbáradì láti kópa ayẹyẹ ìbánikẹ́dùn fún ìyá kan àti ọmọ rẹ̀ táwọn èèyàn kan ṣekúpa ní ọdún kan sẹ́yìn.

Ìròyìn ní lásìkò tí wọ́n ń kó àga àti àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n máa fún àwọn tó bá kópa níbi ayẹyẹ náà lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni wan ṣekúpa wọn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá South Africa, Brigadier Athlenda Mathe sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Newzroom Afrika pé èèyàn mọ́kàndínlógún ló sùn ń lọ́wọ́ lásìkò tí ìkọù náà wáyé ní àwọn ilé tí àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí.

Mathe sọ pé àwọn mẹ́fà ló móríbọ́ lọ́wọ́ ikú nínú ilé kan nínú kan – obìnrin mẹ́rin, ọkùnrin kan àti ọmọ oṣù méjì tí wọ́n ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe kò farapa. Àmọ́ kò sí ẹni tó yè ní ilé kejì.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò ì tíì lè fi ìdí ìkọlù náà múlẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní àwọn ikọ̀ àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àti pé àwọn ti ránṣẹ́ pe àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ lẹ́ka ààbò láti Pretoria láti ṣe ìrànwọ́ fún ìwádìí, kí ọwọ́ le tẹ àwọn tó ṣiṣẹ́ náà ní kíákíá.

Ọ̀kan lára ìgbìmọ́ aláṣe South Africa, Xolile Nqatha ní òun gbàdúrà kí ọkùnrin tí ẹ̀mí kò bọ́ lára rẹ̀ gbádùn kíakíá, kí ó lè tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.

Ó ní ó ṣeéṣe kí àwọn tó ṣe iṣẹ́ náà jẹ́ èèyàn mímọ̀ fún àwọn tí wọ́n pa.

South Africa jẹ́ ọ̀kan lára orílẹ̀ èdè tí ìpànìyàn ti máa ń wọ́pọ̀ jùlọ gẹ́gẹ́ ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Ko dín ní èèyàn 27,000 tí wọ́n pa lọ́dún 2022 nìkan.