Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ránṣẹ́ pe alága EFCC, Bobrisky àti Very Dark Man

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Ile igbimọ aṣojuṣofin Naijiria ti fi iwe pe alaga ajọ EFCC, Ola Olukoyede lori ẹsun ajẹbanu ti ọgbẹni Martins Otse, ti ọpọ mọ si Very Dark Man (VDM) fi kan awọn oṣiṣẹ rẹ.

Ninu lẹta kan ti ile aṣofin naa kọ lo ti fi iwe pe alalaga EFCC, ọga agba ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria ati gbogbo oṣiṣẹ ti ọrọ naa kan lati yọju siwaju rẹ lọjọ Aje, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024.

Awuyewuye bẹ silẹ lẹyin ti Very Dark Man fi ohun idris ‘Bobrisky’ Okuneye lede, ninu eyii to ti sọ pe oun fun awọn oṣiṣẹ EFCC ni riba lati wọgile ọkan lara ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe oun ko ṣẹwọn lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nilu Eko ṣedajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun.

Yatọ si alaga EFCC ati ọga ileeṣẹ ọgba ẹwọ, ile aṣofin ọhun tun kesi Bobrisky funra rẹ, to fi mọ Very Dark Man lati yọju siwaju oun.

Ile aṣofin naa sọ pe gbogbo awọn eeyan ọhun atawọn mii ti ọrọ naa kan lo gbọdọ wa ṣalaye ipa ti wọn ko ninu ọrọ to n ja rainirain lẹ lẹnu lọọ yii.

Ẹwẹ, agbẹjọro agba Femi Falana ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun naa ati pe oun ko gba owo kankan lati fọ orukọ Bobrisky mọ ninu ẹsun ti EFCC fi kan an.

Ọmọ Falana, Folake Falana ti sọ pe ẹni iyi lawujọ ni baba oun, ati pe baba oun ati ibatan oun Falz ko lọwọ ninu ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Ṣaaju ni EFCC ti kọkọ ke si Very Dark Man lati yọju si ọọfisi oun lọna ati ṣe iranlọwọ fun un lori ọrọ naa.

Amọ Very Dark Man ti sọ pe oun ko ni yọju si EFCC nitori oun kọ lo yẹ ki wọn maa wadii rẹ bi ko ṣe awọn oṣiṣe EFCC ati Bobrisky.

Mínísítà pàṣẹ ìwádìí ẹ̀sùn rìbá gbígbà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, Falana fẹ́ gbé VeryDarkMan lọ ilé ẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Bobrisky

Minisita ọrọ abele, Olubunmi Tunji-Ojo, ti paṣẹ iwadii kikun lori ẹsun gbigba owo to n lọ lọwọ nipa awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹede yii.

Bo tilẹ jẹ pe minisita ko sọ ẹsun kan pato to fi ni ki iwadii kikun waye lori ohun to n ṣẹlẹ lọgba ẹwọn Naijiria, aṣẹ to pa naa waye lẹyin ti ọkunrin kan, Martins Otse (Very DarkMan) gbe fọnran to tu aṣiri Bobrisky sita nipa ẹwọn oṣu mẹfa ti ijọba Naijiria ran an lọ.

Ninu atjade ti minisita ọrọ abele fi sita l’Ọjọru,ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 yii, lo ti paṣẹ pe iwadii kikun lẹsẹkẹsẹ.

‘’Ẹka to n ri si ọrọ abẹlẹ lorilẹede yii koro oju si ẹsun gbigba owo ẹyin ti wọn fi n kan awọn ọgba ẹwọn lorilẹede yii.

‘’A ko ni i fi aaye gba ohunkohun to le ṣakoba fun otitọ inu, akoyawọ ati òdodo.

‘’Ko si aaye fun aikunju oṣuwọn, ajẹbanu ati riba, ẹnikẹni tọwọ ba si tẹ fun iwa ibajẹ bẹẹ ko ni i lọ lai jiya to yẹ labẹ ofin.’’

Bakan naa ni atẹjade ijọba naa ṣalaye pe Akọwe agba fun ileeṣẹ ọrọ abẹle, Magdalene Ajani, ni yoo lewaju ikọ itọpinpin ọhun, ti wọn yoo si mu abajade to kun rẹrẹ wa lẹyin iwadii wọn.

Kí ló fa ìwádìí tí ẹ̀ka abẹ́lé fẹ́ẹ́ ṣe?

Fun pe o fi abuku kan naira nita gbangba ni ijọba ṣe ran Idris Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky lọ si ẹwọn oṣu mẹfa ninu oṣu kẹrin ọdun 2024 yii, ṣugbọn irisi rẹ ko jọ ti ẹni to ṣẹṣẹ jade lẹwọn nigba to de.

Ohun to tun ko Idris si wahala ni fọnran ti Very Dark Man ṣẹṣẹ fi sori ayelujara.

Ninu fọnran naa ni ohùn kan ti wọn ni ti Bobrisky ni, ti n sọ pe oun ko ṣẹwọn rara.

Ẹni naa sọ pe baba alaanu oun lo sanwo abẹtẹlẹ fun ọga agba awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria, wọn si fi oun pamọ si ibugbe itura titi ti oṣu mẹfa fi pe.

Ayẹyẹ ikini kaabọ to tẹle ipadabọ Bobrisky, ati bi awọ rẹ ṣe n dan lẹyin ẹwọn, mu ifuradani. Kalulu si n beere pe ṣe Okuneye yii si ṣẹwọn bayii.

Ṣugbọn pẹlu fọnran to tu aṣiri ikọkọ yii, eyi ti ọkunrin to gbe e sita tun ti mu ẹnu ba Amofin agba Femi Falana, pe oun naa gba owo ẹyin lọwọ Bobrisky lati le fi owo ra ẹwọn ọhun, minisita ti pe fun iwadii to nipọn.

Ẹhónú Falana, kí ló dé tí bàbá ṣe fẹ́ẹ́ gba kóòtù lọ nítorí Bobrisky?

Fọnran ohùn ti Very dark Man fi sita tun fẹsun kan Amofin agba Femi Falana ati ọmọ rẹ, Falz.

Fọnran naa sọ pe Amofin agba Femi Falana gba miliọnu mẹwaa naira lọwọ Okuneye.

Owo naa ni wọn ni Falana gba fun bi yoo ṣe ba Bobrisky gba idariji lọdọ ijọba Naijiria.

Very Dark Man fi kun un pe iyalẹnu ati idojuti lo jẹ, bi Falana tawọn eeyan mọ si ajafẹtọọ ọmọniyan, ṣe lọwọ ninu ọrọ Bobrisky lọna aitọ.

Very Dark Man sọ pe oun bọwọ fun fun lọọya agba naa gan-an tẹlẹ, ṣugbọn iwa abuku to hu yii ti sọ ọ di ẹni yẹpẹrẹ, o si tako iṣẹ amofin to gbe dani.

Awọn ọrọ bi eyi atawọn mi-in ti Very Dark Man sọ nipa Falana lo mu ki baba naa sọ pe oun yoo pe e lẹjọ, bi ko ba pa ọrọ naa rẹ, ko si tọrọ aforiji laaarin wakati mẹrinlelogun.

Ìwà ìkà àti ìbanilórúkọjẹ́ ló kún inú ọ̀rọ̀ tí Very Dark Man sọ nípa Amòfin Falana

Ninu lẹta kan ti Taiwo Olawanle, kọ lorukọ Falana and Falana Chambers lori ọrọ yii, wọn ṣalaye pe ohun ti Very Dark Man kọ nipa amofin agba Femi Falana kun fun ibanilorukọ jẹ ati iwa ika .

Amofin Olawanle ṣapejuwe ọrọ to wa loju opo Instagram Very Dark Man gẹgẹ bi ohun ti ko bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.

O ni bo ti le wu ki oju opo naa jẹ ibi ti kaluku ti le sọ ero ọkan rẹ to, iyẹn ko sọ pe ki eeyan maa sọ ohun ti ko ri bẹẹ.

‘’Ojuṣe rẹ ni lati ri i pe ohun to o fẹẹ sọ nipa ẹnikeji jẹ ootọ, o ko ni idi kankan labẹ ofin lati tabuku ẹnikẹni lori irọ nipa sisọ ohun ti ko ri bẹẹ.

‘’Fun idi eyi, a fẹẹ ki o pa ọrọ kobakungbe ti o kọ soju opo naa rẹ, ki o si tọrọ aforiji fun ohun ti ko si idi kankan fun ti o kọ .

‘’Bi o ko ba ṣe awọn nnkan wọnyi laarin wakati mẹrinlelogun, a maa tẹle aṣẹ Amofin Falana lati gbe ọ lọ sile ẹjọ.

Bakan naa la si maa beere owo itanran lọwọ rẹ pẹlu, fun ibanilorukọjẹ ati irọ pipa.’’

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Bobrisky tún wọ gàù EFCC, ó fẹ̀sùn àjẹ́bánu N15m kan òṣìṣẹ́ àjọ náà, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

O dabi ẹni pe gbajumọ ọkunrin to maa n mura bi obinrin, Idris Okuneye ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky tun ti kanjangbọn ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria lẹyin ti ajọ naa ranṣẹ pe e wi pe ko wa sọ tẹnu rẹ lori fọnran kan to ti lu ori ayelujara pa ninu eyi ti o ti sọ pe awọn oṣiṣẹ EFCC gba miliọnu mẹẹdogun naira lọwọ oun.

Bobrisky ati gbajugbaja alẹnulọrọ ori ayelujara, Martins Otse, tawọn eeyan mọ si VeryDarkMan ni EFCC sọ pe ki wọn wa sọ tẹnu wọn tori VeryDarkMan lo gbe fọnran ọhun sita.

Loṣu Kẹjọ to lọ ni Bobrisky gba itusilẹ lọgba ẹwọn lẹyin oṣu mẹfa to lo lẹwọn.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni adajọ Abimbola Awogboro sọ Bobrisky sọgba ẹwọn lẹyin to jẹbi ẹsun ṣiṣe owo naira baṣubaṣu.

Ohun ti Bobrisky sọ ninu fọnran ti VeryDarkMan gbe sita ree...

Ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ana ni VeryDarkMan ṣe fidio kan ninu eyi ti o ti sọ ọpọlọpọ ọrọ nipa awọn ohun ti o ṣẹlẹ lẹyin ti EFCC fẹsun ṣiṣe owo naira baṣu baṣu kan Bobrisky.

Ninu fọnran ti VeryDarkMan ṣe yii ni o ti fi ọrọ ti Bobrisky sọ lori foonu pẹlu ẹnikan nibi to ti sọ pe awọn oṣiṣẹ EFCC kan sọ foun pe EFCC yoo yọ ẹsun kiko owo lọ si oke okun lara awọn ẹsun ti wọn fi kan oun toun ba le san miliọnu mẹẹdogun.

VeryDarkman fẹsun kan EFCC pe kete ti ajọ naa gba miliọnu mẹẹdogun ti wọn beere lọwọ Bobrisky tan ni wọn yọ ẹsun jiji owo ko lọ soke okun kuro ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an lootọọ.

Bobrisky ṣalaye ninu fọnran naa pe ‘’bayii ni mo bẹrẹ si ni pe ọpọ awọn ọrẹ mi lori foonu wi pe ki wọn ran mi lọwọ pẹlu owo.

Lẹyin o rẹyin, awọn ọrẹ mi da owo jọ fun mi titi ti owo naa fi pe N15m ti EFCC sọ pe ki n mu wa.

Bayii ni mo ṣe san miliọnu mẹẹdogun yii ti ajọ naa si yọ ẹsun jiji owo ko lọ oke okun kuro ninu ẹsun ti wọn kan mi.

Lẹyin naa ni wọn sọ pe ẹsun ṣiṣe owo naira baṣu baṣu nikan ni mo maa jẹjọ lori rẹ.’’

Mo ti n lọ sọgba ẹwọn ki baba isalẹ mi to pe mi pe mi o ni ṣẹwọn - Bobrisky

Bobrisky tun ṣalaye ninu fọnran ohun rẹ ti VeryDrakman gbe jade wi pe oun ti wa loju ọna si ọgba ẹwọn nigba ti baba isalẹ oun pe oun lori ago pe koun ma foya tori oun o ni wọ inu ọgba ẹwọn.

‘’Bayii ni baba isalẹ mi sọ fun mi pe oun yoo ṣeto ile to dara kan fun mi ti ko jina sọgba ẹwọn.

O ni oun yoo pe ọga ọgba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọgba ẹwọn ni Naijiria to wa l’Abuja nipa ọrọ naa.

Lẹyin naa ni wọn gbe mi lọ sinu ile kan, wọn si sọ fun mi pe n ko gbọdọ jade titi ti ọjọ to yẹ ki n fi wa lẹwọn yoo fi pe.

Wọn ni ọga agba to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn yii yoo gba miliọnu meje naira,’’ Bobrisky ṣalaye.

VeryDarkMan wa kepe ọga agba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn ni Naijiria pe ko wa sọ tẹnu rẹ lori ọrọ naa.

Bobrisky tun sọ pe akọrin takasufee Falz the Bad Guy naa sọ fun baba rẹ Femi Falana to jẹ agbẹjọro agba nipa oun.

O ni Falana sọ pe oun le bẹbẹ wi pe ki ile ẹjọ foju aanu wo oun lori ọrọ naa.

Falana sọ pe ‘ijọba apapọ le darijin mi, o ni oun yoo kọ ẹbẹ naa ranṣẹ si minisita eto idajọ ni Naijiria ẹni ti yoo gbe e lọ siwaju aarẹ fun ibuwọlu.

Ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe ọkunrin naa ni miliọnu mẹwaa naira loun maa gba ki oun to le ṣiṣẹ naa.’’

VeryDarkMan wa sọ pe awọn aṣiri ti Bobrisky tu sita yii fihan pe iwa ibajẹ ko le tan nilẹ kiakia lorilẹede Naijiria.

O wa kepe ajọ EFCC lati ṣe iṣẹ iwadii lori awọn ẹsun to jẹ jade ninu ọrọ ti Bobrisky sọ.

EFCC bẹrẹ iwadii lori ẹsun ti Bobrisky fi kan awọn oṣiṣẹ ajọ naa

Ẹwẹ, alaga ajọ EFCC, Ọgbẹni Ola Olukayode ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori ẹsun ti Bobrisky fi kan awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan ninu fọnran ti VerDrakMan gbe jade wi pe wọn gba N15m lọwọ oun ki ajọ EFCC le yọ ẹsun kiko owo lọ si oke kuro ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Alaga EFCC sọrọ yii ninu atẹjade to fi lede loju opo Facebook ajọ naa lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Ni bayii, ajọ EFF ti wa ranṣẹ pe Bobrisky fun ra rẹ ati VeryDarkMan to gbe fọnran naa sita lati wa sọ tẹnu wọn lori ẹsun ti Bobrisky fi kan awọn oṣiṣẹ EFCC.

Ajọ EFCC fi da araalu loju pe iwadii kikun yoo waye lori ọrọ naa, bakan naa si ni ajọ EFCC yoo sọ abajade rẹ faye gbọ.

Ọgbẹni Olukayode ni ajọ EFCC yoo maa tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ rẹ pẹlu otitọ, igboya ati aiṣegbe lẹyin ẹnikan.

Bobrisky sọrọ lori fọnran ohun rẹ ti VeryDarkMan gbe jade

Bobrisky ti sọ pe irọ to jina si otitọ ni fọnran ohun oun ti VeryDarkMan gbe jade ninu eyi ti o ti sọ pe awọn oṣiṣẹ EFCC kan gba N15m lọwọ oun ki wọn le yọ ẹsun jiji owo ko lọ soke okun kuro ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Bobrisky fi ọrọ naa lede loju opo ayelujara rẹ wi pe oun o fun oṣiṣẹ EFCC kankan lowo.

‘’Mo ti gbọ nipa fọnran kan to lu ori ayelujara pa eyi tawọn kan ti ṣe ẹda ohun mi wi pe mo ni mo san N15m fun ajọ EFCC, ati wi pe mi o lọ sẹwọn rara.

Irọ nla nio! Mi o sanwo kankan fun ajọ EFCC o.

Mo lọ sẹwọn, ọjọ mi si pe pere pere ki n to jade lọgba ẹwọn.

Mo fẹ ki gbogbo eeyan kọ eti ikun si iroyin ẹlẹjẹ yii,’’ Bobrisky ṣalaye.