You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"N kò lérò pé mo le è di ayàwòrán ààrẹ Buhari fọ́dún mẹ́jọ, èmi kọ́ ni ayàwòràn tó dára jù ní Nàíjíríà"
Yoruba ni ori lo mọ isẹ asela, ori ẹni si lo maa n gbe alawo rere ko ni, jankan si kọ ni ori, ko sa ti gbe eeyan ni.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo maa n la kaka lati ba aarẹ to ba wa lori oye, nile ijọba Aso Rock sisẹ tabi ki wọn tiẹ wnu ile ijọba naa lasan.
Sugbọn eyi ko seesee fun wọn nitori kii se eeyan lasan lo maa n ba awọn aarẹ sisẹ papọ tabi wọ inu Aso rọck.
A si le sọ bi ori n ti Bayo Omoboriowo lẹyin gẹgẹ bii ayaworan, lo se di ẹni to n ya aworan fun aarẹ Naijiria.
Odidi ọdun mẹjọ si ni ọkunrin naa fi ya aworan ni Aso rock lasiko isejọba aarẹ Muhammadu Buhari to kọja lọ.
Ibeere ti yoo si maa gba ọkan awọn eeyan ni pe bawo ni Omoboriowo to jẹ ayaworan se rin, to fi di ayaworan fun odidi aarẹ.
Ki si ni awọn ohun ti ọkunrin naa le sọ nipa aarẹ Buhari, to ba sisẹ bii ayaworan fun odidi ọdun mẹjọ.
Idi ree ti BBC Yoruba fi se awari akikanju ayaworan naa, to si salaye ni ẹkunrẹrẹ bi isẹ rẹ se lọ ni Aso rock ati awọn ohun to mọ nipa aarẹ Muhammadu Buhari.
“Buhari jẹ ẹni ti ko fẹran ki eeyan maa se oju aye, bi ọkan tiẹ se mọ, naa ni o maa n fi wo gbogbo eniyan”
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ Bayo Omoboriowo sọrọ nipa bi aarẹ Buhari se jẹ olotitọ.
“Ohun ti mo le sọ fun yin nipa Buhari ti emi mọ ni pe o jẹ eeyan ti ọkan rẹ mọ, ti kii si fi ọkan mọ ọkan.
Ti Buhari ba ti fun eeyan nisẹ, o ti fun ẹ nisẹ niyẹn, yoo si lọ joko pẹlu igbagbọ pe isẹ to fun ẹ yẹn, wa a se tọkantọkan.
Buhari tun jẹ ẹni ti ko fẹran kii eeyan maa se oju aye, bi ọkan tiẹ se mọ, naa ni o maa n fi wo gbogbo eniyan.
O fẹ ki ẹni ti oun ba gbe isẹ fun, se isẹ naa pẹlu ọkan mimọ.
Loju temi, wọn si Buhari mu tabi pe wọn si gbọ ni.”
“N ko lero pe mo le di ayaworan Buhari, ki n maa ba jẹun ni tabili kannaa, ka dijọ maa fo ninu baalu nigba ti baba mi ko mọ alaga ijọba ibilẹ rara”
Bayo Omoboriowo, lasiko to n salaye bo se di ayaworan fun odidi aarẹ nile ijọba Aso Rock, ni isẹ Ọlọrun ni iyansipo naa jẹ.
“Mo di ayaworan Buhari pẹlu igbẹkẹle Olorun, ẹni to ba gbẹkẹle Ọlọrun kii ni itiju, Ọlọrun lo ba mi se.
Emi kọ ni mo dara julọ ninu awọn ayaworan amọ mo ri pe Ọlọrun ko gbagbe emi naa ni.
N ko lero pe mo le di ayaworan Buhari, ki n maa ba jẹun, maa ba fo ninu baalu nigba ti baba mi ko mọ alaga ijọba ibilẹ rara.
Ọlọrun ni ko gbagbe emi naa, o ranti mi ni tori lara awọn eeyan to sun mọ aarẹ Buhari julọ, emi ni mo kere julọ.
Amọ o maa n dun mi ti mo ba mu ero kan wa, ti wọn ko gba si mi lẹnu, tori lootọ ni mo kere amọ eyi ko sọ pe n ko ni ọpọlọ.”
“Irọ lasan ni pe Jubril Sudan lo di Buhari tabi pe Buhari ni Jubril Sudan”
Nigba to n sọrọ siwaju, Bayo Omoboriowo sọ afọmọ ọrọ nipa iroyin kan to n ja rain nilẹ wa lasiko ti aarẹ Buhari se aisan pe o ti jade laye, ti ẹlomiran si n dibọn bii Buhari.
Omoboriowo wa salaye nipa ahesọ ọrọ naa ati bi wọn se n pe aarẹ Buhari ni Jubril lati ilẹ Sudan.
“Ko sẹlẹ ri pe Buhari ni Jubri Sudan, abi Jubri Sudan ni Buhari, irọ ni gbogbo rẹ.
Buhari se aisan lootọ, tori ko si ẹni ti ko le se aisan, amọ niwọn igba ti ara rẹ ti ya pada, ti o n jẹun gidi, to si n lo oogun rẹ, diẹ diẹ o di dandan ko pada bọ sipo.
Nnkan to waye niyẹn, tori nigba to de pada, o beere pe nibo ni mo wa.
To ba jẹ pe kii se Jubril Sudan ni Buhari lootọ, bawo lo se fẹ mọ ẹni ti Bayo jẹ.”
“Ọjọ ti inu mi dun julọ lati ọdun mẹjọ ti mo fi ba Buhari sisẹ ni ọjọ to beere pe nibo ni Bayo wa?”
Bakan naa ni Omoboriowo sọ fun BBC Yoruba ọjọ ti inu rẹ dun julọ lasiko to ba aarẹ Buhari sisẹ fun ọdun mẹjọ.
“Nigba ti oloye Olusegun Obasanjo ati aarẹ Goodluck Jonatan wa nipo aarẹ, oun ti wọn maa sọ ni pe ‘ba mi pe ayaworan yẹn wa’
Amọ fun igba akọkọ, mo ba aarẹ kan sisẹ to da orukọ mi pe ki wọn pe mi wa, eyi mu inu mi dun.
Ninu ile ijọba Aso rock Villa yii, kii se owo ni mo ba lọ sibẹ, emi kii si se alatẹnujẹ, iyẹn kọ lo gbe mi lọ sibẹ.
Amọ mo lọ sibẹ gẹgẹ bii ọmọ Yoruba ti wọn kọ nile daadaa, ti mo si wa lara awọn to n saayan pe ki ilu yii sun mọ iwaju ni.”