Ta ni Bournemouth ṣẹ̀ tí Liverpool fi di ẹrù ìyà 9-0 rù wọ́n?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool tayọ ni ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Bournemouth pẹlu goolu mẹsan si odo.
Ifẹwọnsẹ akọkọ ti Liverpool yoo bori ni saa liigi 2022/2023 niyi lẹyin ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mẹta ṣiwaju.
Goolu mẹsan si odo ni goolu to pọju ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo lati igba ti liigi premiership ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ lọgbọn ọdun sẹyin.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ṣaju ifẹsẹwọnsẹ naa, akọnimọọgba Liverpool, Jurgen Klopp ṣalaye pe ibẹrẹ wọn ko tii ri bi awọn ṣe fẹ lẹyin ti wọn gbe ta ọmi meji ki Manchester United to na wọn lọjọ Aje ni papa iṣire Old Trafford.
Awọn ẹgbẹ agbabọọlu wo lo ti na alatako wọn ni mẹsan an si odo ki o to kan Liverpool?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Manchester United lo kọkọ na ikọ agbabọọlu miran pẹlu goolu mẹsan an si odo nigba ti wọn koju Ipswich lọdun 1995 ati Southampton lọdun to kọja.
Bakan naa ni Leicester city na Southampton ni mẹsan si odo lọdun 2019.
Diaz, Firmino ba awọn jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Diaz gba meji wọle ni iṣẹju kẹta ati ikarundinlaadọrun, firmino pẹlu gba meji wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkanlelọgbọn ati ikejilelọgọta.
Elliot (Iṣẹju kẹfa), Alexander-Arnold (Iṣẹju kejidinlọgbọn), Van Dijk (iṣẹju karundinlaadọta), Freitas Gouveia Carvalho (iṣẹju ọgọrin).
Bakan naa ni aṣiṣe de ba Mepham, agbabọọlu Bournemouth to gba bọọlu si ile ara rẹ.












