Mercy Aigbe ló fà mí sókè nígbà tí mi ò jẹ́ nǹkankan, Olóore mi ni – Adeniyi Johnson

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Adeniyi Johnson ti kede akẹgbẹ rẹ, Mercy Aigbe, gẹgẹ bii ọkan lara awọn oloore rẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Eledua fi ibeji lantilanti ta idile Johnson lọrẹ.

Ayọ ọmọ tuntun naa lo waye lẹyin ọdun meje gbako ti Johnson ati aya rẹ ti n wa ọmọ, ti gbogbo igbiyanju wọn si n ja si pabo.

Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ ni Adeniyi Johnbson ti kan sara si Mercy fun bo ṣe fa a lọwọ soke ninu iṣẹ tiata.

O ni “Oun ni ẹni akọkọ ti yoo fun ni ipa to yanranti ninu ere, oun si ni ẹnikan ṣoṣo to ni igbagbọ ninu ẹbun mi.”

“O mu mi lasiko ti mi o jẹ nnkankan ati nigba ti ẹnikẹni ko ri mi.’

Johnson tẹsiwaju pe Mercy lo mu oun jade lati inu ẹrẹ, ti ko si sọ ireti nu lori ohun ti oun le ṣe gẹgẹ bii bii oṣere.

O tẹsiwaju pe “Ko ti mi loju lati sọ pe mo jẹ ọkan lara awọn ti o tọ dagba nidi iṣẹ tiata Yoruba.”

“Mercy Aigbe, mi o fi owo ranṣẹ si ọ o, amọ mo n fi akoko yii funrere ohun ti o ṣe fun mi.”

Lẹyin naa lo ke si ọkọ Mercy, Kazim Adeoti lati ba oun dupẹ lọwọ rẹ fun ohun to ṣe fun oun.