Ọwọ́ tẹ obìnrin tó ta ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún kan àti oṣù mẹ́fà ní ₦‎600,000 nípìnlẹ̀ Ogun

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣikun ofin mu obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Olaide Adekunle, lori ẹsun pe o ta ọmọ rẹ ni ₦‎600,000.

Iroyin ni ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii ni afurasi naa ta ọmọ ọdun kan ati oṣu mẹfa ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Abimbola Oyeyemi, sọ pe ọwọ tẹ obinrin ọhun lẹyin ti ọkọ rẹ, Nureni Rasaq, fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa kan to wa niluu Sango.

Oyeyemi ni Rasaq sọ pe ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii ni afurasi gbe ọmọ wọn, Moridiat Rasaq jade, amọ ti ko pada sile pẹlu ọmọ naa.

O fi kun un pe obinrin naa ko le ṣalaye ibi ti ọmọ ọhun wa ati bo ṣe di awati lẹyin to gbe e kuro nile.

Lẹyin naa ni wọn fi ṣikun ofin mu afurasi ọhun lati sọ tẹnu rẹ.

Oyeyemi sọ siwaju sii pe afurasi naa sọ fun awọn ọlọpaa lasiko iwadii pe ṣe loun ta ọmọ naa fun ẹnikan to wa l’Eko ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (₦‎600,000).

O ni: “Nigba ti a bere lọwọ rẹ eredi to fi ta ọmọ ọhun, o ni oun ya owo lọwọ banki alabode kan ti o si ṣoro fun oun lati san owo naa pada, ti awọn oṣiṣẹ banki ọhun ko si fi oun lọkan balẹ.”

“Lẹyin naa, o salọ siluu Eko lati lọ maa ta omi inu ọra.”

“Ibi to ti n kiri omi inu ọra lo ti pade ọkunrin kan to mu u lọ si ọdọ obinrin to ra ọmọ ọhun.”

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa ti ni ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran fun iwadii ni kikun, ki obinrin naa si le foju bale ẹjọ laipẹ.