Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Agbébọn kọlu ibùdó ọmọ ogun Naijiria, wọn pa sọ́jà ni Borno
Haa, gbami-gbami o yẹ agba kẹ!
Ibudo ologun Forward Operation, ẹka 153 ni wọn kọlu lọjọ Aje ana.
Aago mẹta oru la gbọ pe wọn de, wọn pa ṣọja, wọn tun gbe awọn kan wọgbo lọ.
Wọn dana sun ọkọ ayẹta ileeṣẹ ologun, ko nnkan ija wọn lọ
Ki lawọn ologun wa ri ṣe.
Alaye wa loju opo BBC. COM/YORUBA.
,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,
Ajọ JAMB ti loun yoo ṣe atunyẹwo esi idanwo UTME ọdun yii ti ọpọ akẹkọọ ti fidi rẹ mi.
Iyẹn daa o.
Agbẹnusọ JAMB, Fabian Benjamin, ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ boya lati ọdọ ajọ naa ni nnkan ti wọ wa
Ati ki tun ni
Awọn akọṣẹmọṣẹ alayẹwo ti wa lẹnu ẹ.
,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,,
Ìjọba UK kéde ìlànà tí yóò dínà àwọn tó fẹ́ wọ ilu naa
Itumọ
Ko si aye lati maa gba awọn olutọju arugbo lati okeere mọ
Haa
Idanwo ti yoo fi han pe o gbọ, o le kọ, ka ede Gẹẹsi di dandan.
Lati mọ iyoku....

