Ìjọba Ìpínlẹ̀ Zamfara ṣàlàyé ìdí tó fi gbé ọjà màálù tìpa n'íjọba ìbílẹ̀ méje

Aworan gomina Zamfara David Lawan atawọn maalu

Oríṣun àwòrán, David of the Night/Facebook/Google

Ijọba ipinlẹ Zamfara lapa guusu ariwa orilẹede Naijiria ti ṣalaye idi to fi gbe awọn ọja ti wọn ti n ta maalu tipa nipinlẹ naa.

L’Ọjọru ni ijọba kede pe oun ti ti awọn ọja naa ni ijọba ibilẹ meje lawọn ibi ti ijọba ti sọ pe wọn n da maalu ti wọn ji gbe pọ mọ awọn ẹran mii.

Kómiṣọna eto iroyin ati aṣa, Mannir Haidara Kaura, sọ fun BBC pe ijọba gbe igbesẹ yii lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ naa.

O fikun ọrọ rẹ pe iwadii awọn ẹṣọ eleto abo fidi rẹ mulẹ pe niṣe lawọn janduku to n ji maalu awọn eeyan maa n tawọn ẹran naa lọja lati le maa ṣiṣẹ ibi wọn lọ.

Kaura ṣalaye pe lootọọ ni ọrọ eto abo lagbara, amọ, kọmiṣọna naa gbagbọ pe igbesẹ ijọba yoo dina mawọn janduku ole to n ji maalu awọn araalu gbe lọ ta.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba ipinlẹ Zamfara yoo ti ọja maalu pa tori awọn ole aji ẹran ẹlẹran ta.

Loṣu Kẹsan an to kọja lọ, ijọba ti iru ọja bẹẹ meje pa lori ẹsun kan an nigba ti iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju.

Zamfara jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ti eto abo ti mẹhẹ ni Naijiria nibi tawọn janduku agbebọn ti n ṣe ikọlu sawọn araalu, ti wọn n fẹmọ wọn ṣofo ti wọn ṣi tun n ji ẹran wọn lọ.

Ijọba gbagbọ pe igbesẹ rẹ yoo pada so eso rere nigbẹyin gbẹyin.