You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NIMC ṣe àfikún iye owó ìforúkọsílẹ̀ àti àtúnṣe NIN
Ajọ to n ri si nọmba idanimọ ni Naijiria, NIMC, ti kede pe oun ti ṣe afikun iye owo ti awọn araalu yoo maa san fun iforukọsilẹ ati atunṣẹ kaadi idanimọ NIN wọn lati asiko yii lọ.
NIMC lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo X rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ko mẹnuba iye ti wọn n gba tẹlẹ ati iye ti araalu yoo maa san bayii ninu atẹjade naa ti agbẹnusọ rẹ, Kayode Adegoke, buwọlu, o ni awọn eeyan yoo ri maa ri iye owo naa loju opo ayelujara rẹ lonii ọjọ Ẹti.
NIMC sọ pe igbesẹ ọhun ko ṣẹyin itiraka rẹ lati tẹ awọn ọmo Naijiria lọrun, lai gbe bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe ri lọwọ yii sẹgbẹ kan.
Atẹjade ọhun sọ pe "Lati nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin ni a ko ti ṣe afikun iye owo ti a n gba amọ a ti ṣatunṣe si eyii latari bi nnkan ṣe ri lode oni.
"Afojusun afikun tuntun yii ni lati ri daju pe awọn ọmọ Naijiria lanfaani lati ba wa dowopọ lọna ti ko ni pa iṣuna wọn lara.
"Lẹsẹkẹsẹ ni afikun tuntun yii yoo bẹrẹ."
Atẹjade naa tẹsiwaju pẹlu ikilọ pe ẹnikẹni ninu awọn aladani to n ba ajọ naa ṣiṣẹ ko gbọdọ gba ju iye owo ti awọn ba kede lọ, ati pe ẹnikẹni to ba tapa si ofin naa yoo jẹ iya to tọ, awọn si le gbẹsẹle iwe ẹri rẹ.
Ajọ naa tun rọ araalu lati fi ẹjọ ẹnikẹni to ba gba ju iye owo ti awọn kede lọ sun lori ila [email protected] ati nipa pipe ẹrọ ilẹwọ 08155015388.