‘Àwọn òṣìṣẹ́ ní Fásitì Covenant ń fipà bá akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lòpọ̀ kẹ̀?’ Ohun tí à mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Yetunde Olugbenga
- Role, Senior Journalist
Ile ẹkọ giga Fasiti Covenant ti ni pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun pe iwa fifi ipa ba awọn ọmọ ile ẹkọ wọn lopọ latọwọ awọn olukọ n ṣẹlẹ.
Ẹsun yii gba ori ayelujara kan ni ọjọ Aje to si ti n wu ọpọlọpọ ọrọ jade. Tori eyi ni ọpọlọ awọn to ti jẹ akẹkọ ri nibẹ wa n jade lati sọ iriri wọn nipa ẹsun yii.
Igbimọ awọn to ti kawe jade ni Fasiti naa sọ fun BBC ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ pe awọn ti ri ifisun naa ni nnkan bii o le ọsẹ kan ti awọn si ti kan si awọn alaṣẹ ile ẹkọ.
“Nigba ti iroyin naa gba oju opo Twitter kan ni ọjọ Kọkanlelogun Oṣu Kọkanla ọdun 2022, a ti gbọ ọ lati ọsẹ to kọja lọgan la si ti kara bọ ọrọ naa, a ba wọn sọrọ a si jẹ ki wọn ni oye ohun to yẹ ki wọn ṣe,” igbimọ awọn akẹkọjade lo sọ bẹẹ ninu atẹjade wọn.
Òṣiṣẹ kan ti gba idaduro lẹnu iṣẹ

Oríṣun àwòrán, ODA
Igbimọ naa jẹ ko di mimọ pe ọkan lara awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ ti gba idaduro lẹnu iṣẹ.
Wọn ṣalaye pe “bi a ṣe ti n ba awọn alaṣẹ Fasiti ni gbolohun, a gbọ pe ọkan lara awọn ti wọn n pe orukọ rẹ jade lọpọ igba lori awọn ọrọ to n jẹyọ lori ayelujara ti foju wina igbimọ afinijofin lọsẹ to kọja.
“Awọn alaṣẹ ile ẹkọ ti gba iṣẹ lọwọ”. Amọ wọn ko fi orukọ tabi oju rẹ han.
Ẹwẹ, awọn igbimọ aṣoju awọn akẹkọjade yii ti ṣeleri lati tẹsiwaju lati ri awọn afikun iroyin nipa iṣẹlẹ naa.
Nigba ti ileeṣẹ BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lori ọrọ naa, Abimbola Oyeyemi to jẹ agbẹnusọ wipe awọn ko tii rii ki ẹnikẹni wa fi ẹsun kan ni agọ awọn yala latọ̀dọ awọ́n alaṣẹ ile ẹkọ naa ni tabi latọdọ ọmọ ile ẹkọ kankan.
Ẹsun tun ta ba adari ẹsin! Bawo ni ọrọ naa ṣe tan ka ori ayelujara?

Oríṣun àwòrán, COVENANT UNIVERSITY
Iroyin naa bẹrẹ si ni tan ka lẹyin ti eeyan kan lori Instagram pariwo pe awọn oṣiṣẹ kan ni Fasiti naa maa n fi ilọkulọ ibalopọ lọ oun pe o tun fipa ba oun lopọ.
Koda awọn oṣiṣẹ ti wọn lọ ẹsun naa mọ lẹsẹ pọ latori awọn alabojuto gbọngan, titi de ibudo ilera ile ẹkọ atawọn ẹṣọ alaabo gan to fi mọ awọn to n ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ẹsin ninu ijọ.
Ṣe ni ọpọlọpọ ẹsun wa n gori ara wọn debi pe oṣiṣẹ ti wọn tun ni o wa nidi amojuto fifi akẹkọ to ba n rufin jofin naa tun fara gba ninu ẹsun ifipabanilopọ. Iru iroyin bayii ko ṣẹṣẹ maa waye lorilẹede Naijiria leyi ti aarẹ Muhammadu
Buhari gan sọrọ pe iru iwa aburu yii ti pọju.
Bi ẹ ko ba gbagbe, a ti gbe akanṣe iroyin jade lori bibere ibalopọ lati fun akẹkọ ni maaki (sex for grade), iroyin lori ifipabanilopọ ati bẹẹ bẹẹ lọ ti awọn akẹkọọ kaakiri Naijiria si n sọ oriṣiriṣi nipa rẹ.
Ninu oṣu Kẹta ọdun to kọja ni olukọ Fasiti Covenant yii kan naa ko si gbaga ọlọpaa latari pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan lopọ ninu ọfiisi rẹ.














