Adájọ́ sọ ọjọ́ tí Trump yóò gba ìdájọ́ lórí ẹ̀sun rìbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile-ẹjọ kan niluu New York, orilẹede America, ti sọ pe oun yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹsun sisan owo riba ti wọn fi kan aarẹ tuntun ti wọn dibo yan, Donald Trump ṣaaju ọjọ ibura rẹ.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni ile-ẹjọ naa sọ pe oun yoo gbe idajọ rẹ kalẹ.

Ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni ilẹ Amẹrika yoo bura fun Trump gẹgẹ bi aarẹ tuntun ti araalu dibo yan, ṣugbọn ki ni ireti rẹ yoo jẹ ninu idajọ to n bọ lọna yii?

Onidajọ Juan Merchan to n gbọ ẹjọ naa sọ pe oun ko nii ran Trump lẹwọn, tabi wi pe ko san owo itanran, ṣugbọn toun yoo tu silẹ, to si tun kọ ọ sinu aṣẹ rẹ wi pe aarẹ ti wọn dibo yan naa le farahan nile-ẹjọ tabi lori ikaani ayelujara lati gbọ ẹjọ rẹ.

Trump lo ti gbiyanju lati lo anfaani aṣeyọri idibo rẹ lati fi da ẹjọ naa nu.

Aarẹ ti wọn dibo yan naa ti kọ ọ sori ikanni ayelujara rẹ wi pe, aṣẹ onidajọ naa jẹ ti oṣelu ti wọn fẹẹ fi tako oun, to si n pe ẹjọ naa ni eyi ti wọn fẹẹ fi tabuku oun.

Inu oṣu Karun, ọdun to kọja ni wọn fi ẹsun mẹrinlelọgbọn kan Trump nipa ṣiṣe ayederu iwe owo okoowo to to ẹgbẹrun lọna aadoje owo dọla $130,000 (£105,000) fun oṣere kan ti wọn pe ni Stormy Daniels.

Wọn ni ẹsun naa lo ni nnkan lati ṣe pẹlu bo ṣe n gbiyanju lati tẹri owo to gbe fun agbẹjọro rẹ igba naa, Michael Cohen ri, ẹni ti wọn sọ pe nigba to ku diẹ si eto idibo ọdun 2016 lo san owo fun oṣere naa lati paa lẹ́nu mọ nipa ibaṣepọ to ni pẹlu Trump.

Aarẹ ti wọn dibo yan naa ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun naa, ati pe oun ko jẹbi wọn, to si jẹ ko di mimọ pe erongba ẹsun naa ni lati ṣe ipalara fun ipinnu ipolongo eto idibo aarẹ ọdun 2024 toun ni.

Ninu ọrọ to kọ sori ayelujara Truth Social rẹ lọjọ Satide, Trump sọ pe aṣẹ onidajọ naa "tako ofin wa, ati pe bi a ba gba a laaye lati fẹsẹ mulẹ, yoo jẹ opin si ipo aarẹ gẹgẹ bi a ṣe mọ."

Agbẹnusọ Trump, Steven Cheung ti ṣaaju ṣapejuwe aṣẹ naa gẹgẹ bi 'idunkooko."

"Wọn gbọdọ gba Aarẹ Trump laaye lati tẹsiwaju ninu eto igbajọba, ko si bẹrẹ sii lo ipo rẹ gẹgẹ bi aarẹ, lai ni idiwọ laarin ọjọ to ku, tabi pe oun to ba tako eyi, idunkooko ni," Cheung sọ bẹẹ.

"Ko gbọdọ si idajọ kankan, ati pe Aarẹ Trump yoo tẹsiwaju lati maa ja lodi si awọn ogun wọnyi, titi wọn yoo fi ku tan."