Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, mọ̀lẹ́bí ṣàlàyé ohun tó wáyé láàárin afurasí àti bíṣọ́ọ́bù tó gún pa l'Osogbo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileeṣẹ ọlọpaa npinlẹ Osun ti ṣalaye ohun to waye ni pato laarin bisọọbu to di oloogbe lẹyin ti wọn gun pa, Shina Olaribigbe ati afurasu to gun bisọọbu naa pa, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Adebowale.

Ninu alaye agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemi Opelola lasiko to n ba ikọ BBC News Yoruba sọrọ jẹ ko di mimọ pe ọmọ ijọ ni tokotaya naa jẹ ni ile ijọsin oloogbe niluu Osogbo ṣugbọn ọkọ ti kuro ni ile ijọsin naa tipẹ.

"Ọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2025 ni iṣẹlẹ yii waye lasiko ti ọpọ n yọ ọdun tuntun.

"Ohun ti a gbọ ni pe ọkunrin to gun eeyan pa yii ati iyawo rẹ ni wọn ti yago fun ara wọn tipẹ nitori ede ayede to waye laarin wọn.

"Ti wọn si pinnu lati ma gbe ni ọtọọtọ fun bi ọdun kan bayii ṣugbọn ilu Osogbo ni wọn jọ wa.

"A gbọ pe pasitọ yii ma n lọ ba wọn pari ija loorekore ṣugbọn boya ọkọ obinrin wa kẹfin pe nkankan n lọ laarin pasitọ ati iyawo rẹ gẹgẹ bii o ṣe sọ fun wa.

"Ara ta lo si gba ọna ile obinrin to jẹ iyawo rẹ lọ nitori o gbọ pe pasitọ wa ni ile obinrin naa.

"O sọ fun wa pe oun ba pasitọ ni ori bẹẹdi iyawo rẹ, to si gun pa lẹsẹkẹsẹ pẹlu erongba pe pasitọ n fẹ iyawo rẹ."

Opelola tun jẹ ko di mimọ pe ọkọ ati iyawo ni wọn ti wa ni ahamọ bayii ti iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Oro ni Adebowale da mi, mo jẹri ọkọ mi pe ki n se agbere – Iyawo oloogbe

Iyawo oloogbe, Bummi Olaribigbe sọ fun BBC pe oro ni wọn da oun nitori ọkọ oun fẹran ọmọ ijọ.

Bummi ni ọmọ ijọ ni Adebowale to ṣekupa bisọọbu tẹlẹri, to si jẹ pe wọn sun mọ ara to fi jẹ pe wọn finu tan ara wọn.

"Ọkọ mi jẹya, ko ti se nkankan fun awọn ọmọ mi, eyikeyi ko ti se igbeyawo.

"Adebowale parọ mọ ọkọ mi, ki i se sina, mo le gbe ẹri rẹ jẹ, o kan fẹran awọn ọmọ ijọ."

"Ọkọ mi jẹ ẹnikan to ma n ko ẹmi le eeyan. Adebowale yii wa lara awọn eeyan to ni ki ọkọ mi le mi jade sita.

"Ohun to ba sọ fun ọkọ mi ni ọkọ mi ma n gbọ nitori o gbagbọ gan an. Adebowale yii lo jẹ ki ọkọ le mi le mi sita.

"Ohun ti mọ gbọ nipa iṣẹlẹ yii nitori ẹmi ati ọkọ mi o gbe papọ ni pe iyawo ranṣẹ pe ọkọ mi pe ara oun ko ya ti ọkọ mi suure lọ ba, ti Adebowale si ba ọkọ mi ninu ile, to si gun pa.

"Nigba ti a bi iyawo, o ni ọkọ mi ko ba oun ni nkankan."

Damilola to jẹ akọbi ọkunrin fun oloogbe sọ fun BBC pe oun iyalẹnu lo jẹ fun oun nitori awọn rira lọgbọn ọjọ oṣu kejila.

O jẹ ko di mimọ pe iyawo afurasi yii lo n ba oloogbe tumọ ọrọ si Yoruba lasiko iwasu.

"Ko ya mi lẹnu pe Baba mi n pari ija nitori woli ni baba mi, to si ma n tun nnkan se."

Ọkọ gún bíṣọ́ọ́bù tó n parí ìjà láàrin òun àti ìyàwó rẹ̀ pa l'Osogbo

Ariwo nla lo sọ l'Ọjọbọ, ọjọ keji ọdun, nigba ti wọn sọ pe ọkan lara awọn gbajugbaja Biṣọọbu niluu Osogbo, ipinlẹ Osun pade iku ojiji nibi to ti lọ la ija laaarin tọkọ-taya kan.

Shina Olaribigbe Greatness ni wọn pe orukọ Biṣọọbu ọhun, ẹni ti wọn lo jẹ olori ijọ Rapture Empowerment International, to wa niluu Osogbo.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn sọ pe Olaribigbe Greatness yoo maa pari ija laarin tọkọ-taya naa ti wọn ko tii darukọ wọn, ṣugbọn ti wọn pada gbẹmi rẹ nibi ija wọn.

Ọkọ obinrin naa ni wọn sọ pe o fi ibinu fa ọbẹ yọ, to si fi gun Olaribigbe pa nibi to ti n ba iyawo rẹ ni gbolohun asọ lọwọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣọọṣi Olaribigbe Greatness ni iyawo naa n lọ, ati pe ọkan lara awọn ogbufọ inu ijọ ni obinrin ọhun jẹ.

Iroyin sọ pe obinrin ọhun ti wa lori idubulẹ aisan fun igba diẹ, ti wọn si ni Biṣọọbu ọhun lọ si ile rẹ lati lọ ọ sẹ abẹwo si i, ko to o ti ipasẹ bẹẹ pade iku ojiji.

Ko pẹ ti wọn sọ pe olori ijọ REI naa de ile obinrin ti wọn l'oun pẹlu ọkọ rẹ ko jọ gbe papọ naa, ni wọn sọ pe ọkọ rẹ wọle de, to si ba a lori ibusun iyawo rẹ to jokoo si.

Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ọkunrin yii ti sọ ija lu iyawo rẹ, ti wọn si ni Biṣọọbu yii n gbiyanju lati pẹtu sii ninu.

Gbogbo ọrọ ti wọn ni Olaribigbe n ba ọkunrin naa sọ ko wọ ọ leti rara, to si lọ fibinu wa ọbẹ, eyi to pada fi gun Biṣọọbu naa ni igba-aya mọ ibi ọkan.

Loju ẹsẹ nibẹ ni wọn sọ pe Olaribigbe ti fidi janlẹ, to si ku. Obinrin naa ko fi ọrọ ọhun bo rara, to fi tete pariwo sita faraye.

Awọn ara agbegbe naa to sare debẹ la gbọ pe wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa ẹkun Dugbe to pada mu tọkọ-taya naa lọ si agọ wọn lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.

Ọlọpaa sọrọ

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akọroyin, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola jẹ ko di mimọ pe ọwọ ti tẹ tọkọ-taya naa, wọn si ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo.

Opalola ni tọkọtaya ọhun ko jọ gbe papọ labẹ orule kan naa, ati pe ofin ko tii tu wọn ka latigba ti wọn ti pinya.

Siwaju sii lo ṣalaye pe ori bẹẹdi obinrin naa ni Alufa Olaribigbe jokoo si lasiko ti ọkọ rẹ wọle de, eyi to fa ibinu to fi gun un pẹlu ọbẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "Tọkọ-taya ni wọn, ṣugbọn wọn ko jọ gbe papọ. Kii ṣe pe ofin ti tu wọn ka. Gbogbo igba ni pasitọ naa maa n ba awọn mejeeji pari ija.

"A gbọ pe pasitọ naa lọ sile arabinrin ọhun, ti ọkọ obinrin naa si ba a nibẹ. Wọn sọ fun wa pe ọkunrin naa lo gun pasitọ ni igba-aya. A tun gbọ pe ori bẹẹdi obinrin naa ni pasitọ ọhun jokoo si lasiko ti ọkọ rẹ wọle de.

"Ọpọ igba ni ọkọ obinrin naa gun pasitọ yii titi to fi ku. A gbọ pe ọkọ obinrin naa n fura wi pe o ṣee ṣe ki pasitọ naa maa ba iyawo oun lajọṣepọ."

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeeji yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii awọn ba tubọ pari.

Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin wakati diẹ ti iroyin jade pe Alufaa ijọ Katoliiki kan, Fada Joseph Enyinnaya yinbọn pa ọmọdekunrin kan, lori ẹsun wi pe o ju banga sinu ọgba ile ijọsin nipinlẹ Imo.