You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nǹkan àràmàǹdà méje tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí wọ́n bí Anabi Muhammad
Ni gbogbo ọjọ kejila oṣu Rabi'ul Awwal ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu musulumi kaakiri agbaaye maa n ṣe ayajọ ọjọ ibi Anabi Muhammad, ki ikẹ ati ọla Ọlọrun maa ba a.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ, ọjọ Aje ọdun 570 ni wọn bi Anabi niluu Mecca, lorilẹede Saudi Arabia.
Idile Ọgbẹni Abdullah bin Al-Muttalib ati Amina bint Wahb iyawo rẹ ni a bi Anabi Muhammad si.
Baba Anabi, Abdullah, ti ku ki Aminat iyawo rẹ to bi Anabi.
Ọdun 675 lẹyin ọdun marun un to bi Anabi ni Aminat iya rẹ naa dagbere faye.
Awọn onimọ nipa ẹsin Islam, Malam Nazifi Alqarmawi ati Malam Bashir Sheikh Tijjani Zangon Barebari ṣalaye fun BBC awọn iṣẹlẹ iyanu to waye nigba ti wọn bi Anabi:
Odi Kisra wo lulẹ
Malam Nazifi sọ pe lara awọn iṣẹlẹ iyanu to ṣẹlẹ ni odi Kisra to wo lulẹ lasiko ti Anabi Muhammad wa ninu oyun.
''Oriṣiiriṣii nnkan lo ṣẹlẹ, fun apẹẹrẹ, odi ijọba Kisra ti ko sẹni to lero wi pe o le wo lulẹ ayafi tawọn oku kan ba ji dide wo lulẹ lasiko ibi Anabi,'' Malam Zangon Barebari lo sọ bẹẹ.
2. Amina iya Anabi ko rọbi rara ko to bimọ
Sheikh Nazifi Al-Qarmawi ni iṣẹlẹ iyanu mii to tun ṣẹlẹ lasiko ibi Anabi ni pe Aminat iya rẹ ko rọbi rara lasiko ti o fẹ bi Anabi.
O ni eyi jẹ iyalẹnu fawọn araalu pẹlu iṣoro tawọn alaboyun maa n koju lasiko ti wọn ba fẹ bimọ.
Imọlẹ tan
Sheikh Nazifi ni iya Anabi sọ pe oun ri imọlẹ kan to tan kaakiri ayika ibi ti oun bi Anabi debi wi pe ko si okunkun kankan lagbegbe naa.
Malam Nazifi ni ''imọlẹ naa tan soju iya Anabi debi pe o le ri awọn orilẹede agbaaye to fi de Basra ati Syria.
Bo tilẹ jẹ pe ilu Mecca lo wa, imọle naa pọ debi pe Aminat le ri awọn ilẹ mii kaakiri aye.''
Aminat ri awọn angẹli atawọn ojiṣẹ Ọlọrun
Lara awọn iṣẹlẹ iyanu to tun waye lasiko ibi Anabi ni pe awọn angẹli, awọn iranṣẹ Ọlọrun atawọn obinrin lati paradise kora jọ pọ lati dunnu lori ibi Anabi Muhammad.
Malam Nazifi ṣalaye pe ''awọn obinrin mẹta kan ṣabẹwo si Aminat ṣaaju asiko ti yoo bi Anabi.
Aminat si beere lọwọ wọn pe nibo ni wọn ti wa, wọn si da a lohun pe awọn wa nitori ọmọ nla ti yoo bi saye ni.
Iya Anabi tun beere lọwọ wọn pe ta a ni wọn gan an?
Wọn si sọ fun un pe awọn ni Asiya iyawo Pharaoh ati Maryam iya ojiṣẹ Ọlọrun Isa.''
Malam Nazifi ni awọn obinrin lati paradise ni wọn.
Anabi fi iwaju ori rẹ kan ilẹ ni idọbalẹ
Sheikh Nazifi tun sọ pe nnkan aramanda mii to tun ṣẹlẹ ni pe Anabi fi iwaju ori rẹ kan ilẹ lasiko ti wọn bi i tan.
''Kete ti iya rẹ bi i tan ni awọn eeyan ṣe akiyesi wi pe o fi iwaju ori rẹ kan ilẹ ti o si dọbalẹ.
O dọbale nigba meji, o si sọ pe ''Allahu Akbar,'' lẹyin naa lo salaamọ.
Sayyada Amina sọ pe oun gbe ọwọ rẹ soke, o si sọrọ bo tilẹ jẹ oun ko mọ nnkan to sọ.
Lẹyin naa ni o ṣin, o si dubulẹ, nigba naa lo sọkun bi ọmọ tuntun.''
Ni baluwẹ ni wọn Anabi si
Sheikh Nazifi fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan awujọ Zomar ṣalaye pe baluwẹ ni wọn bi Anabi si.
''Wọn bi Anabi, wọn si wẹ fun un, ko si si onigbajamọ kankan to ri ihoho rẹ.
Bakan naa ni wọn tun tete ga iwọ rẹ.''
Anabi dide ṣaaju ọjọ suna rẹ
Sheikh Al-Qarmawi ni ki ọjọ suna Anabi to pe ni o ti dide ti o si bẹrẹ si ni ra koro.
Eyi jẹ nnkan iyanu fun ọpọ eeyan nitori kii saba ri bẹẹ pẹlu ọmọ ikoko aṣẹṣẹ bi.