Wo oyin tó ní ìwo lórí bíi 'Lucifer' tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ní Australia

Oríṣun àwòrán, Dr Kit Prendergast
- Author, Lana Lam
- Role, Sydney
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Awọn onimọ ijinlẹ Sayẹnsi ti ṣawari Kokoro oyin tuntun to ni iwo lori, ti wọn si fun ni orukọ eṣu.
Awọn oniwadii ri oyin Megachile Lucifer nigba ti wọn se ayẹwo ododo kan to jẹ pe Bremer Ranges nikan lo ti ma n hu ni iwọ oorun Australia Goldfields.
Oyin oniwo yii ni o jẹ pe awọn aabo wọn nikan lo ma ni iwo, ti wọn si ma n fi da bobo ara wọn ati lati wa awọn ohun elo fun ile igbe wọn.
Ọnimọ ijinlẹ Sayẹnsi to n lewaju ni oun mọmọ sọ kokoro naa ni Lucifer bi o ṣe n wo ere kan lori sinima .
O fikun kokoro ni kokoro akọkọ ti yoo darapọ ẹgbẹ awọn oyin ni ogun ọdun.
"Awọn aabo yii ni iwo ni bi oju rẹ." Dokita Kit Prendergast lati Fasiti Curtin.
"Nigba ti mo n kọ nipa kokoro yii, mo n wo ere kan lori Netflix, to n jẹ Lucifer lasiko naa, ti orukọ naa si sọ si mi lori, to si ba kokoro oyin naa mu. Mo tun jẹ ololufẹ oṣere to ṣe Lucifer ninu ere naa."
Iwadii, ti wọn gbe sita loju opo Journal of Hymenoptera Research, ni o tun pe fun ida bobo awọn agbegbe ti wọn ti le ṣawari awọn kokoro oyin yii ati ododo ti wọn ma n bale.
"Nitori awọn kokoro tuntun yii jẹ ohun ti a le ṣawari ni agbegbe kekere ti a ti le ri awọn ododo ti wọn ko wọpọ mọ.
"A gbọdọ ri pe a ko fi ẹmi awọn oyin wewu lasiko ti awọn ileeṣẹ kan ba n hu kaakiri."















