You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òní ni àyàjọ́ ọdún ọlọ́jọ́ ní Ile-Ife
Gẹgẹ bi igbagbọ awọn ọmọ Yoruba, irinwó ati ẹyọ kan ni awọn Òrìṣà to wa ní Ilé-Ife, ipinlẹ Osun àti pe gbogbo wọn ni wọn ni ọjọ́ ti wọn maa n bọ wọn.
Ọdún Ọlọjọ jẹ ọdún kan pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá lati fi ṣami ọjọ ti Olodumare da ile aye, bẹẹ si ni o jẹ ọdún tó ti pẹ ni ilẹ̀ Yorùbá.
O jẹ ọdun to maa n waye ni iranti Ogun to jẹ akọbi Oduduwa.
Saaju ayajọ ọdun yii Ọọni Ile Ife yoo tyi wa ni igbele ọjọ meji nibi ti yoo ti maa se adura fun iran Yoruba ati orílẹ ede Naijiria lapapọ.
Lẹyin eyi ni Ọọni maa jade sita pẹlu Afe Are eyi ti igbagbọ wa pe ohun ni Oduduwa kọkọ dé.
Laaarin oṣu Kẹsan-an si oṣu Kẹwaa ọdun ni ọdun Ọlọjọ maa n waye.
Ọpọlọpọ àwọn eniyan kaakiri agbayer ni wọn maa n pejupese si Ile-Ifẹ lati ṣayẹyẹ ọdun Ọlọjọ.