Òkùnkùn birimù ní Nàìjíríà bí iná mọ̀nàmọ́ná ṣe dẹnu kọlẹ̀ fún ìgbà kẹ́rin lọ́dún 2024

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn araalu tun ti wa ninu okunkun birimu kaakiri orilẹede Naijiria, lẹyin ti ina mọnamọna tun dẹnu kọlẹ.
Igba kẹrin ree ti ina mọnamọna yoo denu kọlẹ kaakiri Naijiria lọdun 2024 ti a wa ninu rẹ yii.
Ina ọba to tun dẹnu kọlẹ̀ yii lo ti sọ olu ilu Naijiria, Abuja ati at'awọn ipinlẹ sinu okunkun.
Ni ọjọ kerin oṣu Keji ni ina mọnamọna kọkọ dẹnu kọlẹ lọdun 2024 yii.
Ina mọnamọna tun ṣe bẹẹ o tun dẹnu kọlẹ ni ọjọ kejidinlogbon oṣu Keta.
Eyi to ṣẹlẹ kẹyin ni o waye lọjọ keedogun oṣu Kẹrin ọdun yii bakan naa.
Ni ago mẹta ọsan ana tii ṣe ọjọ Abameta, ọjọ kẹfa oṣu Keje ni ina ọba tun dẹnu kọlẹ fun igba kẹrin lọdun 2024 yii.
Ileeṣẹ apinnaka ti ipinlẹ Kaduna to n pin ina fun ipinlẹ Kaduna, Sokoto, Kebbi ati Zamfara ti kọkọ fi atẹjade kan sita lati tọrọ aforijin lọwọ awọn onibara wọn.
Wọn ni inu okunkun ti wọn wa ko sẹyin bi ina mọnamọna Naijiria ṣe dẹnu kọlẹ.
Ileeṣẹ apinnaka IBEDC to wa niluu Ibadan to n pina fun ipinlẹ Ekiti, Oyo, Ogun, Osun ati Kwara ni ijamba iba to ṣẹlẹ nile iṣẹ apinnaka lo fa aisi ina ọba lọwọ yii.















