Wo àwọn obìnrin Gaza tó n bímọ pẹ̀lú ìrora nítòsí ibi tí àdó olóró ti ń búgbàmù

    • Author, Yogita Limaye
    • Role, BBC News, Jerusalem

''Ọmọ mi ko ti i gba orukọ rara nitori ogun , ọmọ ọjọ mẹrin ni''

Bayii ni ọmọbinrin kan, Keifaia Abu Asser, sọ lori ẹní ìko to jokoo le ni kọrọ ibugbe ti ajọ Iṣọkan Agbaye ba a wa niluu Rafah, eyi to wa ni Guusu Gaza. Keifaia ṣaa n ra ọmọ ìkókó obinrin to faṣọ pupa we naa mọra ni.

Kedere lo han pe o ti rẹ ẹ. Nibi gbogbo laye, akọbi ọmọ ko rọrun lati bi, ṣugbọn eyi ti Keifaia n koju ni tiẹ yii kọ sisọ.

Apa Ariwa Gaza ni wọn ti bi Keifaia, ẹni ọdun mẹrinlelogun to sa kuro nile pẹlu awọn ẹbi rẹ nigba tawọn ologun Isrẹli kilọ fawọn araalu naa, pe ki wọn tete sa kuro nibẹ fun alaafia wọn.

Keifaia ti fẹrẹ bimọ nigba yẹn.

" Niṣe ni mo n sa kiri lati ibi kan sibom-in. O ti rẹ mi patapata. A kọkọ sa lọ si ibudo ogunlende Nuseirat, ṣugbọn wọn n ju ado oloro nitosi wa. Mo ri awọn oku ti wọn ja jala-jala, ẹ wo o, o lagbara pupọ." Bayii lọmọbinrin naa ṣalaye fun akọroyin BBC kan ni Gaza.

Keifaia atawọn ẹbi rẹ jẹ ọkan ninu ẹgbẹrun idile ti wọn ti sa kuro ni Ariwa Gaza, awọn naa si n fẹsẹ rin ọpọlọpọ maili gẹgẹ bi awọn yooku. Ibẹru awọn to n ju ado oloro wa lọkan wọn, ki wọn ma lọọ ju u lojiji ko si pa wọn run.

" Gbogbo igba lẹru maa n ba mi, emi ti mo loyun, eyi si lewu pupọ fun ọmọ inu mi "

Awọn ẹbi Keifaia pada de ọsibitu Kuwait kan to wa ni Rafah, ṣugbọn titipa ni wọn ba ẹka igbẹbi, ni wọn ṣe gbe e lọ si ilewosan Emirati to wa nitosi.

" Nnkan ko dẹrun nibi ti wọn gbe mi lọ, nitori awọn obinrin to n bimọ nibẹ naa ti pọju. Ibi gbogbo ni wọn ti n wa lati Gaza. Ariwa, Guusu ati gbogbo ibi yooku ni wọn ti n ko wọn wa."

"Oogun ara riro to wa lati tọju wa ko to nnkan, igba ti inira nla ba mu alaboyun kan ni wọn n fun wọn, awọn ti inira wọn ba si le gan-an ni wọn n fun "

Ni ti Keifaia, oun ko gba oogun atura kankan to fi bimọ.

Ajọ Iṣọkan Agbaye (UN), ṣalaye pe ko si nnkan kan teeyan le tọka si bayii mọ nipa eto ilera Gaza, wọn fi kun un pe ida mẹta awọn ileewosan ni wọn ti wa ni titipa, eyi to n ko obitibiti iṣẹ ba iwọnba awọn ọsibitu to ṣi n ṣiṣẹ

Afojusun wọn jẹ ka mọ pe ẹgbẹrun lọna aadọta alaboyun (50,000) ni wọn ti wa ninu idaamu bayii, pẹlu bi nnkan si ṣe ti daru to yii naa, alaboyun ọgọjọ yoo bimọ lojumọ kan ṣoṣo

Ọpọlọpọ alaboyun ni ko lanfaani igbẹbi si ọsibitu mọ, nitori iku aboyun to n waye rẹpẹtẹ n kọ awọn ileewosan gan-an lominu gidi. Ko sepo ti wọn yoo fi tan ẹrọ amunawa, ko soogun atawọn irinṣẹ tawọn dokita agbẹbi nilo.

Ola Abu Oali, jẹ ọkan ninu awọn eeyan to koju iṣoro.

Ola ṣalaye fun Majdi Fathini, akọroyin BBC kan ni Gaza, o ni, "Ọmọ ọsẹ meji lọmọ mi. Asiko ogun ni mo bi i, inu ileewe yii naa ni mo bi i si. Mo ni ọmọkunrin mi-in yatọ si eyi ti mo ṣẹṣẹ bi yii, inu ileewe to kun akunfaya fawọn eeyan yii naa la jọ n gbe ni Rafah, ajọ Iṣọkan Agbaye lo fi ṣe wa loore.

"Ara awọn ọmọ mi mejeeji ko ya bayii, inu wọn ri gbẹndu, wọn si n ṣegbọnsẹ gbuuru. Ni gbogbo igba ti mo ba n fun ọmọ mi lọyan, niṣe lo maa n bi. Mo ti gbe ọmọ mi keji lọ sileewosan lẹẹmẹta pe ki wọn ba mi fa omi si i lara, ṣugbon ko ti i siyatọ kankan lara rẹ''

Ai si omi to mọ jẹ ọkan lara awọn iṣoro to n koju awọn eeyan ti ko rile gbe mọ ni Gaza bayii. Ajọ UN sọ pe omi lita mẹta lo n kan ẹnikọọkan lojumọ lati fi ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe.

'' Ko s'omi, ọmọ mi o rọyan mu. Ileegbọnsẹ ta a n lo buru jai, o maa n run gboo ni, niṣe la si maa n tò ko too kan wa lati lo o" Bẹẹ ni Ọla ṣalaye.

Obinrin mi-in toun ati Ola jọ n gbe ninu ileewe naa ni Wafaa Yousef Fakhry Ahmed, alaboyun ni. O sọ pe ẹru n ba oun pupọ nitori ọmọ inu oun.

Alaboyun yii sọ pe oun ko ni i pẹẹ bimọ mọ, ẹru si n ba oun pẹlu ayika alaimọ toun yoo bimọ naa si, nibi ti ko si omi teeyan tiẹ le fi ṣe nnkan to kere ju lọ.

Ọmọ Gaza ni Asma, Olu ilu naa lo n gbe tẹlẹ, ṣugbọn abẹ atibaba kan loun atawọn ọmọ rẹ mẹta n gbe bayii ninu ọgba ọsibitu Al Aqsa.

Inu oyun lo wa lasiko togun de, o lọ sileewosan Al-Shifa lati yẹ ara rẹ wo boya alaafia ni kogun naa too gbilẹ. Nibẹ lo ti ri i pe ọpọlọpọ aboyun loyun n bajẹ mọ lara latari ijaya ti wọn n koju latọdọ awọn to n ju ado oloro.

" Ka maa ji si ara riro ti di nnkan ojoojumọ fun wa bayii, ibugbe iyọnu ati inira la n ji si, bẹẹ ni awọn oku ta a n fojoojumọ ri nilẹ n daamu ọkan wa .

'' O ti su mi, mo fẹẹ kogun yii dawọ duro. Ki lẹṣẹ awọn ọmọde wọnyi ti wọn fi n jiya bi eyi, ki lọmọ mi ti ko ti i daye to ṣi wa ninu mi ṣe''

Bẹẹ ni Asma fomije beere ibeere ti ko rẹni kan fesi si ọhun.