Taa ni Aisha Achimugu, gbajúmọ̀ oníṣòwò, tí EFCC kéde pé òun ń wá?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń rí si ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà ìyẹn Economic Financial Crimes Commission, EFCC ti kéde pé àwọn ń wa gbajúmọ̀ obìnrin kan tó tún jẹ́ adarí iléeṣẹ́ Felak Concept Group, Aisha Achimugu.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi sórí ìkànnì ayélujára wọn lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ni wọ́n ti kéde pé àwọn ń wá obìnrin náà fẹ́sùn lílẹ̀dí àpòpọ̀ láti hùwà ọ̀daràn àti kíkó owó ìlú lọ sí ilẹ̀ òkèrè.

Àtẹ̀jáde náà tí agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale fi léde rọ àwọn èèyàn tó bá ní ìmọ̀ nípa lbí wọ́n ṣe le nawọ́ gán obìnrin náà láti tó àwọn létí tàbí lọ fi tó àgọ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní agbègbè wọn létí.

Ìwádìí Achimugu kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Atiku tàbí Sanwo-Olu - EFCC

EFCC ṣe àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé ìwádìí arábìnrin Achimugu tí àwọn ń ṣe kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar àti gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajid Sanwo-Olu.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Atiku sọ̀ pé àwọn ìjábọ̀ kan ń fẹ̀sùn kan òun pé ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fún òun lówó láti ṣe ìpolongo ìbò lọ́dún 2023 látọwọ́ Aisha Achimugu.

Àmọ́ àtẹ̀jáde tí EFCC fi léde ní nǹkan tí àwọn ń ṣe ìwádìí Aisha Achimugu fún kò nííṣe pẹ̀lú Atiku tàbí gómìnà Sanwo-Olu rárá.

EFCC ní ẹ̀sùn lílẹ̀dí àpòpọ̀ lórí ìwà ọ̀daràn àti kíkó owó ìlú lọ sí ilẹ̀ òkèèrè ni àwọn ń ṣe ìwádìí Achimugu fún àti pé òhun ló fà á tí àwọn kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá.

Wọ́n ní láti ọdún 2022 ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí Achimugu àmọ́ tó lọ sí ilé ẹjọ́ láti ṣe ìdádúró EFCC láti má nawọ́ gán òun, pe òun fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, fi òun sí àhámọ́ tàbí ṣe ìwádìí òun.

Agbẹnusọ EFCC sọ pé ní ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ni ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja da ẹjọ́ náà nù, tó sì fún àwọn láṣẹ láti ṣe iṣẹ́ àwọn.

Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ni agbẹnusọ Atiku Abubakar fi àtẹ̀jáde kan síta pé Atiku Abubakar tó jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP níbi ètò ìdìbò 2023 kò fìgbà kankan ṣèpàdé pẹ̀lú Sanwo-Olu débi tí yóò gba owó lọ́wọ́ rẹ̀.

Àtẹ̀jáde náà sọ pé àwọn rí ìròyìn tó jẹ jáde pé gómìnà Sanwo-Olu fún Atiku lówó tó jẹ́ owó ìjọba ìpínlẹ̀ Eko nípa gbígbe gba ọ̀dọ̀ Aisha Achimugu.

Ta ni Aisha Achimugu?

Ní oṣù Kìíní, ọdún 2024 ni òkìkí Aisha Achimugu kàn lórí ayélujára nígbà tó fi ilé pọn ọtí fi ọ̀nà rokà fún odidi ọjọ́ méje láti fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́ta ọdún rẹ̀.

Ní Calivigny Island, Grenada àti Silversands ní ìlú Abuja, olú ìlú Nàìjíríà ni ayẹyẹ ọjọ́ méje náà ti wáyé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóṣèlú Nàìjíríà, tó fi mọ́ àwọn èèkàn ìlú, tó fi mọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babjide Sanwo-Olu ló péjú síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà tó wáyé ní Crribean Island, Grenada.

Aisha Achimugu, lórí ìkànnì ayélujára rẹ̀, júwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò obìnrin, òun ni adarí iléeṣẹ́ FELAK CONCEPT GROUP, iléeṣẹ́ tó kó àwọn iléeṣẹ́ mẹ́jọ lẹ́ka epo rọ̀bì, ìmọ̀ ẹ̀rọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Òun náà tún ni alága iléeṣẹ́ Bluewave Exploration and Production Limited.

Achimugu OFR, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lójú òpó ayélujára rẹ̀ ti gba àmì ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi tó fi mọ́ àmì ẹ̀yẹ FORBES, iléeṣẹ́ tó ń pèsè epo rọ̀bì tó dára jùlọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kìíní, ọdún 1974 ni wọ́n bí Aisha Achimugu.