''Ìgbà tí mo ti jẹ ọba, ni àwọn obìnrin tó fẹ́ ẹ́ fẹ́ mi ti pọ̀ si nítorí ẹwà mi''

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Laipẹ yii ni Ọba Olusola Osolo, Olofin Adimula ti Ado Odo, nipinlẹ Ogun, di gbajugbaja kaakiri ori ayelujara ni Naijiria, paapaa lori Tiktok, Instagram ati Facebook.

Kii ṣe fun laburu o, ko ṣeyin bi awọn eeyan , ni pataki julọ awọn obinrin, ṣe n kan saara si ẹwa oriade naa.

Bi awọn kan ṣe n ki Ọlọrun kuuṣẹ lori ẹwa kabiesi, ni awọn miran n rawọ ẹwẹ si I lati fi wọn ṣe aya.

Koda, wọn fun Ọba Osolo ni orukọ tuntun, Kabsbaby.

Eyi lo mu ki BBC tọ kabiesi ọhun lọ, lati foju gan-an ni ẹwa to pọ to bẹẹ, ti gbogbo ọmọge lori ayelujara ṣe n fẹ ko jẹ ti wọn.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa ni Oba Olusola Osolo ti sọ pe, gbogbo awọn ọrọ ifẹ ati iwuri ti wọn n kọ nipa ẹwa oun, ni oun ri.

O ni koda, orukọ tuntun ti wọn fun oun, oun ti gba a mọ ara orukọ.

"Lati igba t imo ti wa ni ewe, ni awọn obinrin ti ma n ṣuru mọ mi, nitori ẹwa ti Ọlọrun fun mi. Amọ, o tun ti lọ soke ni ida meji lati igba t imo ti di ọba."

Oriade naa ko ṣa i sọ pe oriṣiriṣi ọrọ ti wọn n kọ ranṣẹ si oun kọkọ mu ki oun fẹ ẹ pa ori ayelujara naa ti, amọ, awọn ọdọ layika oun tun sọ pe, ki oun ma ṣe bẹẹ.

"Mo ti wa lori ayelujara ki n to jẹ ọba, lati igba ti mo ti jẹ ọba si ni mo ti n lo o fun igbelarugẹ aṣa Yoruba.

"Lara imọran ti awọn onimọ nipa ayelujara, gba mi ni pe, dipo ki n kuro nibẹ nitori awọn obinrin to n dẹnu ifẹ kọ mi, ki n kuku maa lo anfaani naa lati fi maa la wọn lọyẹ lori awọn ewu to wa ninu awọn ọrọ ti wọn n sọ ati ihuwasi wọn.

Iha wo ni olori rẹ kọ si bi awọn obinrin mii ṣe n fẹ ba a pin ọkọ?

Ọba Osolo ṣalaye pe ko si eyi to pamọ si iyawo oun, ninu gbogbo nnkan ti awọn obinrin n kọ nipa oun.

"Iyawo mi paapaa ma n sọ pe oun mọ pe maa ṣi fẹ iyawo si, ṣugbọn o bẹ mi ki n jẹ ki oun gbadun mi diẹ si ki n to ṣe bẹẹ."

Ọba alaye naa tẹsiwaju pe tako iroyin to n lọ pe oun ti gbẹsẹ le awọn obinrin kan, o ni eyi ko ribẹẹ rara.

O ni Ọlọrun nikan lo n ran oun lọwọ lati maa ko ara oun ni ijanu lori ọrọ obinrin, nitori pe, awọn to n fẹ ki oun fẹ wọn, ti pọ ju agbara oun lọ.