Ìlú kan rèé ní Nàíjíríà níbi tí èèyàn àti ẹranko tí ń pín omi odò mu torí ọ̀dá omi

- Author, Abubakar Maccido
- Role, Reporter
- Reporting from, Kano
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ilu Dutsen Bakoshi jẹ abule kan ni ijọba ibilẹ Shanono nipinlẹ Kano, apa ariwa orilẹede Naijiria ni wọn koju ipenija omi ti wọn n lo fi dana ati mimu, paapa lasiko ẹru.
Ọpọ omi ti awọn eeyan agbegbe yii n mu lo jẹ omi odo ati omi ojo ti wọn gbajọ. Koda lati pọn omi, awọn eeyan abule yii ni lati rin fun odidi wakati kan tabi ju bẹ lọ lati de sibi ti kanga wa.
Ohun to buru ju omi ti wọn n mu, fi dana, naa ni awọn ẹranko n mu.
Gẹgẹ bii awọn eeyan to n gbe ni abule Dutsen Bakoshi se sọ, iṣoro omi yii lo ti wa fun igba pipẹ lai aye awọn baba nla wọn, to ti to aadọta ọdun bayii, ti wọn si ti ke pe ijọba ni ọpọ igba ṣugbọn ko si idahun, ti kos si tun si ayipada.
Araalu ni igba to ṣoro ju ni asiko ẹru, ti awọn eeyan to nilo omi si ni lati rin irin wakati kan lọ si Shanono tabii ijọba ibilẹ Gwarzo, lati lọ wa omi. Lasiko naa, awọn eeyan kan le wa fun ọsẹ kan, ti wọn ko ni ri omi fi wẹ, ti ile yoo si wa ni titi pa lati le fun awọn akẹkọọ ni anfani lati ran mọlẹbi wọn lọwọ.

Fa'iza Yakubu Adam, ọdọmọbinrin kan to n gbe ni abule Dutsen Bakoshi, sọ fun BBC Pidgin pe iṣoro omi ti n ba wọn ja tipẹ, paapa lasiko ẹru.
"A ko ni omi to mọ rara. Ni ojoojumọ ni a n rin si odo lọ pọn omi, to si jẹ pe omi ọhun to b awa lasiko ojo ko mọ rara." O ṣalaye.
O fikun pe ki awọn to le lo omi naa, awọn ni lati gbe awọn igbesẹ kan.
"Fun wa lati le lo omi, a ni lati gbe kana, lati fi eroja kan si ti yoo jẹ ki idọti naa walẹ.
Fa'iza ni iṣoro omi naa ti ṣaaju ki wọn bi oun ni iṣoro omi ti n ba ilu naa finra.
"Ki wọn to bi mi ni abule wa ti n koju iṣoro omi, paapa lasiko ojo ati pe bayii ti omi wa, a ni lati rin fun ọpọ wakati ka to le ri omi mu tabi fi dana."
O fikun pe gẹgẹ bii obinrin, iṣorọ omi n ṣe ọpọ akoba fun igbaaye rẹ lojoojumọ.
"Gẹgẹ bii obinrin, iṣoro yii kan mi pupọ paapa lasiko ẹru. O yẹ ki obinrin ma wẹ ni igba meji si mẹta lojumọ ṣugbọn nigba miiran, mo le ma wẹ nitori ko si omi lati wẹ."

O tun ni ọpọ ile ẹkọ ni abule naa lo ma wa ni titi pa lasiko ẹru nitori iṣoro omi.
"Ni igba ẹru, awọn ile ẹkọ ma wa ni titi pa nitori ki awọn akẹkọọ le lọ ran awọn obi wọn lọwọ."
Ololri abule naa, Ibrahim Ahmad Dutse, sọ BBC pe awọn ti n koju iṣoro omi yii fun igba pipẹ.
"Lati aye awọn baba wa, a ni jẹ omi tipẹ, paapa ki wọn to bi ni iṣoro yii ti wa."
Bo ti lẹ jẹ asiko ojo ni a way ii, ti omi si wa, ko tumọ si pe omi naa jẹ omi to mọ, to si n se akoba fun ilera wa.
"Omi ti a mu yii naa ni awọn ẹranko n mu, to si n fa aisan si wa lara. Ọpọ lo ti ni aarun oni igba meji ati awọn aisan miiran."
Ohun to ba ni lọkan jẹ ni pe ọpọ igba ni wọn ti fi ọrọ yii to ijọba leti ṣugbọn ko si ayipada.
"A ti fi ọrọ to ijọba leti ni ọpọ igba ṣugbọn titi wọ asiko yii, ko si ayipada," o ṣalaye.

Ki ni ijọba sọ?
Ẹwẹ, BBC kan si alaga ijọba ibilẹ Shanono, Abubakar Barau Shanono, to si jẹ ko di mimọ pe oun mọ nipa iṣoro, ti oun si ti lọ si abule naa.
O ni adagun omi mẹfa lo w ani abegbe naa, ti awọn si ti bẹrẹ iṣẹ lori wọn ṣe fun awọn araalu naa, ko ba ti ẹ jẹ fun eyi ti ọdun yii ku.
"A ti kọ lẹta si gomina lori omi adagun, pe ki wọn wa tu omi ṣe lati le fun awọn eeyan ni afani si omi to mọ."
O fikun pe awọn ri iranlọwọ lati ọdọ ẹgbẹ kan ti wọn ti pinnu lati pe omi fun araalu ni Dutsen Bakoshi ati awọn eeyan to n lo pipo dey use dem now.
"A ti kọ borehole meji pẹlu iranlọwọ lati ọwọ awọn ileeṣẹ kan fun awọn agbegbe kan ni Dutsen Bakoshi"


Iṣoro omi lorlẹede Naijiria
Abule Dutsen Bakoshi ṣafihan bi iṣoro ṣe lulẹ lorilẹede Naijiria, ti ọpọ eeyan ko si ni anfani si omi to mọ.
Gẹgẹ bii ajọ, UNICEF, ṣe ṣalaye, omi idọti lo n fa ọpọ aisan ati iku ọmọde ti wọn ko ti to ọmọ ọdun marun un.
UNICEF ni ole ọmọde 70,000 to ti padanu ẹmi wọn nitori eyi.












