Mi ò rí orun sùn fún ọjọ́ méje ṣáájú ìdájọ́ ‘tribunal’ lórí ìbò gómìnà – Bala Mohammed

Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed, ti sọ pe oun ko ri oorun sun fun odidi ọjọ meje gbako ṣaaju idajọ ile ẹjọ to dajọ pe oun gan ni awọn araalu dibon yan gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.

Mohammed wa lara awọn gomina mẹjọ ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naiiria sọ pe awọn ni ipo gomina tọ si gẹgẹ bii ibo ti awọn araalu di lọdun to kọja.

Ọrọ naa lo jade lasiko to n ba wọn alatilẹyin rẹ sọrọ lẹyin idajọ ile ẹjọ ọhun.

O ni “Ai ri oorun sun mi ko ṣẹyin bi awọn adari ẹgbẹ nigba kan ri ṣe pa irọ mọ mi lọdọ Aarẹ lọna ati ji ẹtọ mi.

“Wọn sọ fun Aarẹ pe onijọgbọn ni mi ati pe mo maa da ọpọ wahala silẹ ti mo ba ṣi wa nipo gomina.

“Amọ fun ogo Ọlọrun, a sa gbogbo ipa wa, a si bori lẹyinorẹyin.

“Wọn ṣe ohun gbogbo ti wọn le ṣe lati da aarin emi ati ọrẹ mi, igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima ati Aarẹ Bola Tinubu ru.”

Mohammed gboriyin fun Aarẹ Tinubu pe ko da si ọrọ ipẹjọ naa.

Gomina ọhun tun gboriyin fun ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lori idajọ ododo to ṣe si awọn ẹjọ kotẹmilọrun to wa niwaju rẹ.

O ni ohun to kan ninu ọrọ oun bayii ni bi oun yoo ṣe ri eeyan to koju oṣuwọn ti yoo di ipo naa mu lẹyin saa oun.

Wo ìdí mẹ́ta tí Iléẹjọ́ tó ga jùlọ fí dá Abba Yusuf (NNPP) Kano àti Sanwo-Olu (APC) Eko padà sipò Gómìnà

Ile ẹjọ to gaju lọ ni Naijiria ti kede Gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf gẹgẹ bi ẹni ti o jawe olu bori ninu idibo Gomina ipinlẹ naa.

Eyi sí ti mu opin ba gbogbo awuyewuye to jọ mọ ipo yii.

Abba Yusuf ti ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party NNPP, gẹgẹ bi Adajọ John Okoro ṣe wí lọ ni ibo to pọ julọ ninu idibo ọdun 2023.

Adajọ fi kun un pe ile ẹjọ kotẹmilọrun kuna pẹlu idajọ to gbe le'lẹ to so pe ni se ni ki wọn da ibo Abba Yusuf ti wọn gbe fun alatako rẹ Nasir Gawuna ti APC pada fun.

Nípa ọrọ pe Abba Yusuf kii ṣe ọmọ ẹgbẹ NNPP:

Adajọ sọ pe ẹgbẹ oṣelu rẹ, NNPP nikan lo lasẹ lati sọ ẹni to jẹ tabi ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn.

Nitori naa ile ẹjọ gba ẹjọ kotẹmilọrun ti NNPP pe to sì fọwọ rọ idajọ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ ṣaaju danu.

Ibi ti irinajo pin si ree lori fakinfa to gba ọpọ oṣu nipa ẹni ti ipo Gomina tọ sí laarin awọn oludije mejeeji. ni ipinle Kano

Kini wọ́n sọ nipa idajọ Gomina ipinlẹ̀ Eko?

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti fi onte lu Gomina Sanwo Olu Babajide ti ẹgbẹ oselu APC ni ipinle Eko pe ko maa ba iṣẹ rẹ lọ.

Lónìí nilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yóò dájọ́ lórí ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Kano àti ìpínlẹ̀ mẹ́fà míì

Lonii ọjọ kejila, oṣu Kinni, ọdun 2024 yii ni ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun to jẹyọ ibo gomina ni ipinlẹ mẹjọ.

Awọn ipinlẹ mẹjọ naa ni ipinlẹ Eko, Kano, Plateau, Bauchi, Ebonyi, Cross River, Zamfara ati ipinlẹ Abia.

Ni Ọjọ kokanlelogun, osu Kejila, ọdun 2023 ni ile ẹjọ to ga julọ sun idajọ rẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun ibo gomina ipinlẹ Kano si oni.

Ṣaaju ni ọjọ kẹtadinlogu,n oṣu Kọkanla ni ile ẹjọ kotemilorun fontẹ lu idajọ igbimọ igbẹjọ awuyewuye lori ibo gomina ipinlẹ Kano to dajọ tẹlẹ.

Ti idajo na sọ pe gomina Abba Yusuf ti ẹgbẹ NNPP kọ lo wọlé, ti o si kede oludije ẹgbẹ APC, Nasir Gawuna gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu ibo naa.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu ibo Sanwo-Olu gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko

Ni Ọjọru, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 ni ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu ibo gomina ipinlẹ Eko, Sanwo-Olu ti o si yi ẹjọ ti àwọn alatako rẹ lati ẹgbẹ oṣelu LP, Gbadebo Rhodes-Vivour ati PDP, Abdulazeez Olajide Adediran danu.

Ni bi ago mẹta ọsan ni idajọ naa waye nile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Eko.

Ẹwẹ, lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni ile ẹjọ to n ri si awuyewuye to jẹyọ lori ibo gomina ipinlẹ Eko fontẹ lu Sanwo-Olu pe oun lo wọle ibo gomina ipinlẹ naa.

Lẹyin naa ni agbẹjọro Rhodes-Vivour pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.

Bakan naa ni oludije ẹgbẹ PDP ti ọpọ eeyan mọ si Jandor pe ẹjọ kotẹmilọrun onikoko mẹrinlelọgbọn tako iyege Sanwo-Olu ninu ibo gomina ipinlẹ Eko.

Jandor tun beere lọwọ ile ẹjọ wi pe ko wọgile oludije fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu APC ati LP.

Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìbò tó gbé gómìnà Kano wọlé, ó ní Guwana APC ló wọlé

Ileẹjọ kotẹmilọrun to n joko niluu Abuja wọgile ibo to gbe Gomina Abba Kabir Yusuf, ileẹjọ naa dajọ wi pe Nasiru Gawuna oludije ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle ibo ọhun.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu idajọ igbimọ ẹlẹni mẹta to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina ninu eyi ti Adajọ Akintan Osadebay ti wọgile ibo to gbe Gomina Yusuf ni ogunjọ oṣu kẹsan an ọdun yii.

Ileẹjọ Triunal sọ ninu idajọ rẹ pe ibo 165,663 ti Yusuf ni lo jẹ ayederu nitori osisẹ ajọ eleto idibo INEC ko buwọlu iwe ibo naa.

Ajọ eleto idibo INEC kede Yusuf to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu NNPP gẹgẹ ni oludije to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano loṣu Kẹta pẹlu ibo 1,019,602 nigba ti ajọ naa ni ibo 890,705 ni Gawuna ni ninu ibo ọhun.

Ilẹ ẹjọ naa yọ ibo 165,663 kuro ninu gbogbo ibo ti Yusuf pẹlu alaye wi pe ko si ontẹ tabi ibuwọlu lori awọn ibo naa.

Gbogbo ẹsun mẹtẹẹta ti APC fi kan NNPP lori eto idibo ọjọ kọkanla oṣu Kẹta ni igbimọ igbẹjọ naa da APC lare lori wọn.

Lẹyin naa ni Yusu gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ nigba ti ko faramọ idajọ igbimọ to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina.