Falana léwájú agbẹjọ́rọ̀ ìpínlẹ̀ Eko láti ṣe ìwọde ìfìyàjẹni láti ọwọ́ Ọlọ́pàá

Agbẹjọro agba to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti kesi ileeṣẹ Ọlọpaa lati gbe iwadii kalẹ fun bi ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe n fìya jẹ awọn agbẹjọro nipinlẹ Eko.

Falana sọ eyi lasiko to n lewaju ifẹhonhan ti ẹgbẹ awọn agbẹjọro, ẹka ti ipinlẹ Eko gbe kalẹ lati tako bi ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe tí agbẹjọro kan, Olumide Sonupe mọle.

Awọn agbẹjọro wa lati ẹka ajọ NBA márùn-ún, ti wọn bẹrẹ ìwọde ni ọfisi wọn ní Ikeja, ti wọn si morile ọfisi ileeṣẹ Ọlọpaa níbi Kọmisọna ileeṣẹ Ọlọpaa, Adegoke Fayoade ti ba wọn sọrọ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Falana ni NBA setan lati dabo bo eto awọn Agbẹjọro, to si jẹ ko di mimọ pe NBA tí kọwe fun Iwadii.

"Gbogbo ẹka NBA marun-un parapọ lati se ìwọde tako ifiyajẹni ileeṣẹ Ọlọpaa ti awọn Agbẹjọro ati araalu n koju.

"NBA n pe fun Iwadii lori ohun to sẹlẹ. Inu wa dun pe Kọmisọna fun ileeṣẹ Ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ sugbọn a n fẹ kọwe lati pese abo fun akẹgbẹ wa."

Alaga ajọ NBA ti Ikeja, Seyi Olawumi ni awọn ṣe ìwọde naa lati tako bi ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe fiya jẹ awọn Agbẹjọro.

"Iwode alaafia lati tako ifiyajẹni lati ọwọ ileeṣẹ Ọlọpaa si awọn ọmọ ẹgbẹ wa ti wọn sisẹ wọn fun awọn onibara wọn.

Kí lo sẹlẹ saaju?

Agbẹjọro Sonupe lo dero ile iwosan lẹyin ti Ọlọpaa tí mọlẹ lasiko to n gbiyanju lati gba beeli onibara rẹ agbegbe Alimosho ni Ọgbọnjọ oṣu Kejila ọdun 2023.

Gẹgẹ bii alaye Agbẹjọro naa, ọjọ meji lo lo ni ahamọ ileeṣẹ Ọlọpaa lẹyin ti DPO pàṣẹ pe ki wọn ti mọlẹ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni Kọmisọna ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Eko pàṣẹ pe ki DPO naa rọọkun nile.

Bakan ninu atẹjade tí Agbẹnusọ fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi lede salaye pe DPO ti pàṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.