You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
UK kéde gbígba àwọn olùkọ́ láti Nàìjíríà, orílẹ̀èdè 8 mìíràn sí iṣẹ́
Orílẹ̀ èdè United Kingdom, UK ti kéde fífi àyè gba àwọn olùkọ́ láti orílẹ̀èdè Nàìjíríà, South Africa, Ghana àti Zimbabwe tó ní ìwé ẹ̀rí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú tí orílẹ̀ èdè UK láti forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́.
Yàtọ̀ sí níní ìwé ẹ̀rí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú tí orílẹ̀ èdè UK, àwọn tó le forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ ti ṣiṣẹ́ olùkọ́ fún ọdún kan ṣáájú.
Bákan náà tún ni orílẹ èdè náà fún àwọn olùkọ́ láti orílẹ̀èdè Ukraine, Singapore, Jamaica, India àti Hong-Kong náà láàyè láti kópa níbi ètò ìgbanisíṣẹ́ ọ̀hún.
Nínú oṣù kejì ọdún 2023 ni ètò ìgbanisíṣẹ́ lábẹ́ ètò tí wọ́n pè ní Qualified Teacher Status, QTS yóò bẹ̀rẹ̀.
Kí ènìyàn tó le ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní orílẹ̀ èdè England, ènìyàn gbọ́dọ̀ ní OTS.
Èyí ni yóò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé olùkọ́ náà ní àwọn ohun tó lẹ́tọ̀ọ́ láti di olùkọ́ tó dáńtọ́ lórílẹ̀ èdè náà.
Gẹ́gẹ́ bí ìkéde UK, àwọn olùkọ́ láti ilẹ̀ adúláwọ̀ ni wọn yóò kọ́kọ́ gba ìwé wọn yẹ̀wò fún QTS.
Ṣáájú àsìkò yìí, àwọn olùkọ́ láti orílẹ̀èdè bíi Gibraltar, Australia, Canada, New Zealand, Switzerland, US, Scotland àti Northern Ireland ni wọ́n máa ń gbà fún ètò náà.
Àtẹ̀jáde tí ìjọba UK fi síta ní ó ṣeéṣe kí àwọn gba àwọn olùkọ́ náà láti orílẹ̀èdè wọn tààrà tí àwọn tí wọ́n ń bá ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ bá fi ààyè gbà wọ́n láti ṣe àtìlẹyìn fún gbígba físà wọn.
Bákan náà ni ìjọba UK tún tẹ̀síwájú pé àwọn máa fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn olùkọ́ káàkiri àgbáyé láti kópa nínú ètò yìí lọ́jọ́ iwájú.
Nínú ìjábọ̀ University College London kan ní bí wọ́n ṣe nílò àwọn olùkọ́ láti ìparí oṣù kẹrin ọdún 2023 yóò lé kún nítorí ọṣẹ́ tí àìsàn Covid-19 tí ṣe fún ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀ èdè UK.
Láti ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 2023 ni àwọn olùkọ́ láti orílẹ̀ èdè mẹ́sàn-án yóò ní àǹfàní láti fi orúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ olùkọ́ lábẹ́ ètò TRA fún QTS.
Àwọn orílẹ̀ èdè náà ni Nàìjíríà, Ghana, Hong-Kong, India, Jamaica, Singapore, South Africa, Ukraine àti Zimbabwe.
Àwọn ìwé ẹ̀rí tí àwọn olùkọ́ nílò láti pegedé fún QTS nìyìí
Kí olùkọ́ àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́sàn-án yìí tó le rí iṣẹ́ olùkọ́ lábẹ́ QTS sí orílẹ̀ èdè UK, àwọn nǹkan tí ẹ̀ka tó ń mójútó ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀ èdè UK kà sílẹ̀ nìwọ̀nyí:
Níní ìwé ẹ̀rí ìkẹ́kọ̀ọ́jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ti UK èyí tí UK ENIC yóò ṣe àyẹ̀wọ̀ rẹ̀ fínífíní.
Ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ olùkọ́ tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí lẹ́bùrù kẹfà àti ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ "English initial teacher training course."
Níní ìwé ẹ̀rí nípa ìlànà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ èyí tó níṣe pẹ̀lú ṣíṣe àfihàn àwọn nǹkan tí ẹ̀kọ́ náà dálé lórí.
Ní ìwé ẹ̀rí láti kọ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.
Ní ìrírí ọdún kan gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ lẹ́yìn tó parí ilé ẹ̀kọ́.
Bákan náà ni níní ìmọ̀ nípa èdè Gẹ̀ẹ́sì àti ìwé ẹ̀rí láti fi hàn pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n lò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé ẹ̀rí wọn.
Tàbí láti gba jókòó ṣe ìdánwò CEFR B2 fún èdè Gẹ̀ẹ́sì (SELT).