Ilé ẹjọ́ Ilorin dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún ọkùnrin mẹ́ta tó fipa bá ọmọ Fásitì Ilorin lòpọ̀

"Blessing ò na ọmọ rí o, òun ló ṣí géètì fún mi láàrọ̀ àmọ́ bí mo ṣe bá òkú rẹ̀ nírọ̀lẹ̀ já mi láyà - Dupe Shittu, ẹ̀gbọ́n Blessing

Ohun ti ẹni ti akẹkọbinrin Fasiti Unilorin ti awọn akẹkọọ ọkunrin mẹta gba idajọ lori fifipa baa lopọ to fi ku sọ fun BBc Yoruba ree lẹyin ọjọ diẹ ti iṣẹlẹ laabi naa waye ninu ile rẹ ni Ilorin.

Gbogbo igbiyanju lati ba baba Blessing Olajide sọrọ lo ja si pabo tori iru ipo ibanujẹ ti gbogbo mọlẹbi wa lasiko naa.

Amọ nitori oriṣiriṣi awuyewuye to n jade lasiko naa ni ẹgbọn rẹ yii ṣe gba lati ba BBC Yoruba sọrọ.

Ni bayii ti idajọ ti wa jade, bo tilẹ jẹ pe ọmọ naa ti ku, inu ẹbi ṣi dun diẹ pe iya idajọ ko jẹ awọn.

Ninu ifọrọwanilẹnu taa ṣe pẹlu rẹ, o ṣalaye iru ọmọ ti Blessing jẹ ati bi iku rẹ ṣe ya awọn lẹnu.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun Fasiti Ilorin ba wa sọrọ nipa igbesẹ ti wọn ti gbe.

Iroyin ni Dupe Shittu fi si ori Status ti oju opo Watssap rẹ pe "bo tilẹ jẹ pe o pẹ inu wa dun si idajọ to jade.

Ile ẹjọ giga kan ni ilu Ilorin ipinlẹ Kwara ti ni ki wọn yẹgi fun eeyan mẹta fun ifipabanilopọ ati ṣiṣekupa Olajide Blessing Omowumi to jẹ ọmọ ile ẹkọ onipele kẹta ni ile iwe giga Fasiti ti Ilorin.

Adajọ Yusuf Adebayo tun kede pe awọn mẹta kan ko mọwọ mẹsẹ laarin awọn mẹjọ ti wọn ko to n farahan ni ile ẹjọ lati ọjọ yii lori ẹsun fifpabalopọ ati pipa obinrin naa.

Adajọ naa Ibrahim Yusuf da awọn mẹta lẹbi: Abdulazeez Ismail, Ajala Oluwatimileyin and Oyeyemi Omogbolahan fun sun igbimọ pọ paniyan atu idigunjale to si ni ki wọn so wọn lokun lọrun titi ẹmi yoo fi bọ lọrun wọn.

Bakan naa ni Adajọ ni afurasi keji jẹbi ẹsun ifipabanilopọ to si ran an lọ si ẹwọn ọdun mẹrinla eyi ti yoo ṣe mọra wọn nigba ti olujẹjọ kini, kẹrin ati ikaarun fori ko ẹwọ̀n ọdun mẹta mẹta fun ẹsun ole jija.

Ṣaaju ni ile ẹjọ ti kọkọ da afurasi kẹfa, ikeje ati ikẹjọ silẹ; ; Abdullateef Abdulrahman, Daud Bashir Aderayo and Akande Taiye Oladoja latari pe wọn ko ri ẹbi kankan lọrun tiwọ́n nipa iṣẹlẹ ọhun.

Amọ awọn mẹtẹẹta ti wọn jẹbi ẹsun ti wọn si ti dajọ iku fun naa jẹ ọmọ ile ẹkọ Yunifasiti Ilorin pẹlu arabinrin ti wọn balopọ to si ku.

Ẹ jẹ ka rán yín leti ohun to ṣẹlẹ tẹlẹ

Iroyin ni ẹgbọn Omowumi ṣaadede ba oku rẹ ninu ile ti wọn ti dii lọwọ ati ni ẹnu nigba toun pada de lati ibi iṣẹ lọjọ naa lọhun. Eyi ni ohun ti ọlọpaa sọ.

Bakan naa ninu atẹjade oju opo Twitter Gomina ipinlẹ naa, Abdulrahman Abdulrazaq, o ni “iru iwa to lodi, tak kete si ipejọpọ ọmọniyan to si buru jai ko ribi de si rara lọkan eeyan to ni inu rere.”

“Gbogbo wa lao pawọpọ lati ja ija yii titi de ojutu”.

Bakan naa ni Ọlọpaa ṣalaye pe awọn to ṣe iṣẹ laabi naa kọ lẹta kan silẹ to ka bayii pe: “Fasiti Ilorin kii dariji”, wọn si fi eyi si ẹgbẹ oku arabinrin naa ki wn to kuro nile wọn.

Ẹwẹ, ẹni to jẹ bii aburo iya oloogbe, Omolara Kuteyi sọ fun awn oniroyin lasiko ti igbjọ naa n lọ lọwọ pe “lara awọn afurasi ọhun jẹ oju mimọ fun mọlẹbi wọn.”

“Nigba ti wọn ko wọn wọle, ao mọ pe awọn to ṣe aburu yẹn niyẹn. Adugbo kan naa ni awọn mẹtẹta jọ n gbe gẹgẹ bii alabagbe. Lara wọn naa jẹ akẹkọọ Fasiti Ilorin.”

Iyaafin Kuteyi ṣalaye pe latori foonu lawọn ti ri aṣiri leyi to jẹ pe wn ta fun ọkan lara awọn afurasi naa.

“Wọn lọ pẹlu foonu naa. Foonu hun naa ni wọn lo fi wadii wọn pada.”