You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
E ṣàánú wa! Omi ti fẹ́ gbé wa lọ! – Àwọn olùgbé agbègbè Lekki pariwo síta
Awọn agbegbe ilu kereje ni ijọba ibilẹ Lekki ati Ibeju-Lekki nipinlẹ Eko ti ke gbajari sita lori bi ẹkun omi ṣe n gba ilẹ lọwọ wọn ati bi o ṣe n ba ohun ini wọn jẹ.
Ninu atẹjade ti awọn ilu mẹrin Igbekodo/Sirinwon, Apakin, Itamarun ati Oriyanrin fi lede ni wọn ti sọ pe ohun abami lo n ṣelẹ si wọn ni agbegbe naa.
Wọn ni ojoojumọ lati bi ọdun kan ni ẹkun omi ti n da wọn laamu, to si n ba nkan ini wọn jẹ.
Wọn ni awọn n bẹbẹ naa ki awọn eniyan ma ba sọ ẹmi wọn nu ati ounjẹ ojo wọn.
Awọn agbegbe yii ni ileeṣẹ Dangote petrochemicals industries ati Refinery company.
Bakan naa ni ileeṣẹ Lagos Deep Seaport ati Lekki Deepsea port, to fi mọ Lagos Free Trade Zone wa ni agbegbe yii.
‘’Ẹ ran wa lọwọ, omi n gbe ile wa lọ’’
Awọn baalẹ ni agbegbe naa ni ọwọ ti Atlantic Ocean fi n rọ wa si eti okun naa kọja keremi nitori okun to daa bi 150km si wọn tẹlẹ ko ju 40km lọ mọ.
Wọn ni eyi ko ṣẹyin bi omi naa ṣe n kun si ni ojoojumọ, to si n ba oko wọn jẹ.
Wọn ni ọpọlọpọ ọkọ oju omi, ohun ti wọn fi n sin ẹja ati awọn oko wọn ni omi ti gba lọ.
‘’Ti a ko ba ṣọra gbogbo agbegbe naa ati ilu ni omi yoo gbelọ tan patapata.’’
Lati bi osu mejila si isinyin ni ẹkun omi ti n ṣẹlẹ ni ojoojumọ’’
Ti a ba so ọkọ oju omi mọlẹ, ki a to de ibi ni afẹmọjumọ omi a ti gba a lọ.
‘’Gbogbo igi ọpẹ, igi agbọn to fi mọ awọn ohun ọgbin to wa ni eti okun ni omi ti gbe lọ.’’
''Tẹlẹ ti a ma n ri ẹja ko ninu omi nitori ilẹ, eyi ko ṣeeṣe mọ nitori awọn ẹja ti wa ninu okun lọhun, ti a ti de ibi ti wọn wa si ṣoro fun wa.''
''A n fi asiko yii kesi ijọba ipinlẹ Eko lati jọwọ ran wa lọwọ ki wọn wa ọna abayọ si idojukọ yii.''
Wọn bẹ ijọba ki wọn ri pe imọ ẹrọ to peye ni wọn n lo ni agbegbe naa lati dẹkun ẹkun omi to n waye nibẹ lojojumọ.
Awọn ijọba ibilẹ ti ọrọ naa kan ni ki wọn jọwọ ṣe bi o ti t ati bi o ti yẹ pẹlu bi wọn ṣe ṣe ni agbegbe Ilekki, Oshoroko, ati Idotun ti omi ko fi dawọn ni aamu mọ.