Ẹ jẹ̀bùrẹ́, ìyanṣẹ́lódì kò lè so èso rere kankan - Sanwoolu rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí NLC

Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwoolu ti rọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, NLC láti fọwọ́ wọ́nú, fiyè dékùn, kí wọ́n má lọ fún ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n ń gbèrò.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni NLC ti darí àwọn òṣìṣẹ́ ní gbogbo ẹ̀ka láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì láti fi ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí ìjọba yọ.

Sanwoolu ní àsìkò yìí kọ̀ ní ó yẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ máa wo iṣẹ́ níran rárá.

Níbi ètò ìsìn láti fi kásẹ̀ ètò ìbúrawọlé fún sáà kejì rẹ̀ ní ilé ìjọsìn Cathedral Church od Christ ni Sanwoolu ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn òṣìṣẹ́ ọ̀hún.

Ó ní wíwo iṣẹ́ níran kò ní wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ náà nítorí gbogbo àwọn olùdíje sípò Ààrẹ lásìkò ìpolongo ni wọ́n sọ wí pé àwọn máa yọ ìrànwọ́ yìí tí àwọn bá dé ipò.

Ó fi kun pé nǹkan tí Ààrẹ Tinubu ṣe yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn olùdíje náà yóò ṣe tó bá jẹ́ wí pé àwọn náà ni ipo náà já mọ́ lọ́wọ́.

Gómìnà náà ní ó pọn dandan kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe sùúrù pẹ̀lú ìjọba Tinubu, kí wọ́n sì ṣe àtìlẹyìn fún un kó le se àṣeyọrí.

Sanwoolu ní òun tó yẹ kó jẹ́ àfojúsùn báyìí ni bí àyípadà ọ̀tun yóò ṣe dé bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Ó tún rọ NLC láti má ṣe ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ìrànwọ́ orí epo tí ìjọba yọ náà.

Ẹgbẹ́ òsìṣẹ́, NLC yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì káàkiri Naijiria ní Ọjọ́ ‘’Wednesday’’

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti kede pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi bẹrẹ lati Ọjọru ọṣẹ to n bọ, iyen Ọjọ Keje, Osu Karun un, ọdun 2023.

Eyi n waye latari ọwọngogo epo bẹntirol to gbode kan kaakiri orilẹede Naijiria.

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Joe Ajaero lo kede iyanṣẹlodi naa lẹyin ipade pajawiri awọn igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa ni ilu Abuja.

O ni ijọba paapaa ajọ NNPC ni di Ọjọru, ọṣẹ to n bọ lati da iye epo bẹntirol pada si iye to wa tẹlẹ.

Ajaero ni ti wọn ko ba gbe igbeṣẹ lori rẹ, awọn yoo bẹrẹ ifẹhọnuhan alailopin kaakiri orilẹede Naijiria.

Ko gbọdọ si iṣẹ ni Ọjọru, ọṣẹ to n bọ- NLC

Bakan naa ni ẹgbẹ NLC ọhun ti fi atẹjade ranṣẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ kaakiri Naijiria wi pe ki wọn yan iṣẹ lodi ni Ọjọru.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti ni awọn yoo da gbogbo iṣẹ duro ni ọjọ naa kaakiri orilẹede naa.

Wọn ni eyi n waye lati mu ki ijọba da iye epo pada si iye to wa tẹlẹ,ki wọn to yọ iranwọ epo patapata.

Wọn kesi gbogbo ẹka wọn ni Naijiria to jẹ ti ijọba ati ti aladani lati fi ọwọ so wọpọ pẹlu wọn lasiko yii.

Ẹgbẹ NLC ni awọn n reti ti gbogbo ẹka wọn ni ipinlẹ lorilẹede Naijria darapọ mọ iyanṣẹlodi naa ni Ọjọru.