You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìgbà mẹ́wàá tí bààlúù àwọn ológun ṣèṣì ju àdó olóró sí ààrin ìlú
O ti pe ọdun kan geerege bayii ti baaluu awọn ologun ilẹ Naijiria kan ṣeṣi ju ado oloro si abule Tudun Biri, ni Kaduna, lasiko tawọn araalu naa n ṣayẹyẹ ọdun Mauludi.
L'Ọjọruu, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kejila ọdun 2024 yii, baaluu ologun ilẹ Naijiria miran tun ṣe bẹẹ niluu kan ti wọn n pe ni Silame, nipinlẹ Sokoto.
Eeyan mẹwaa lo doloogbe latari eyi, ọpọ eeyan lo si farapa.
Olu ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ti fi atẹjade sita nitori iṣẹlẹ yii, ninu rẹ ni wọn ti sọ pe ikọlu naa ṣeṣi ni.
Wọn ni awọn agbesunmọmi to wa nibẹ lawọn fẹẹ kọlu, asiko naa si ni ijamba ṣe araalu.
Ṣugbọn awọn amoye nipa aabo, koro oju si iwa awọn ologun yii.
Iwoye wọn ni pe awọn ologun Naijiria ko ṣe ododo nipa ọna ti wọn fi n koju Boko Haram ni Ariwa-Ila-Oorun orilẹede yii.
Bakan naa ni wọn ni akoyawọ ko si ninu iṣẹ awọn ṣọja yii nipa ọna ti wọn n gba koju aisi aabo, to fi di pe araalu ti ko mọwọ-mẹsẹ lo n ba ogun lọ ninu ilee wọn.
Eyi ni onka igba mẹwaa ti ọkọ ofurufu ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ti kọlu araalu, ti wọn ni o ṣèṣì ni:
1) Abule Silame – ipinlẹ Sokoto, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila, 2024
Ko din ni eeyan mẹwaa to ba ikọlu yii lọ, nigba ti awọn ṣọja Naijiria kọlu abule Silame ati awọn mi-in nipinlẹ Sokoto.
Gẹgẹ bi olori ijọba ibilẹ ibẹ, Abubakar Muhammad, ṣe fidi ẹ mulẹ fun BBC.
O ni: ''aarọ yii ni wọn pe mi, pe wọn ti ju ado oloro. Mo ṣe iwadii mo si ri i pe ootọ ni."
''Baaluu ologun meji lo du ado oloro si awọn abule naa. Ikọ ologun oju ofufurufu atawọn ti ilẹẹlẹ ni wọn ṣe ikọlu naa."
Abubakar fi kun un pe àgbá nla to kun fun ọta ni awọn ọmọ ogun ofurufu gbe wọ agbegbe naa.
O ni yatọ si eeyan mẹwaa to ku, awọn mẹfa mi-in tun fara ṣeṣe.
2) Abule Tudun Biri – ipinlẹ Kaduna, ọjọ kẹta, oṣu Kejila ọdun 2023
Eeyan marundinlaadọrun-un (85) lo di oloogbe, gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kaduna ṣe fidi ẹ mulẹ lẹyin ikọlu yii.
Ẹrọ kan ti awọn ologun n lo ni wọn lo ju ado oloro saarin awọn to n ṣe ọdun Mauludi.
Olukọ ileekewu kan, Bello Shehu Ugara, ṣalaye pe oru ni wọn ju ado oloro naa.
"Awa naa lọ sibẹ lati ran awọn eeyan lọwọ, nibi ta a ti n ṣe bẹẹ ni baaluu ologun tun ti pada wa, wọn si ju ado oloro lẹẹkan si i."
Bello ṣalaye pe awọn obinrin ati awọn ọmọde lo ku ju ninu ikọlu yii.
3) Abule Buhari- ipinlẹ Yobe, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, 2021
Ileeṣẹ ologun ofurufu kede leyin iṣẹlẹ yii, pe ọkọ baaluu awọn ṣeṣi kọlu awọn araalu Buhari, nijọba ibilẹ Yunusari, ipinlẹ Yobe.
Wọn ni awọn araalu kan ku ninu iṣẹlẹ naa.
Awọn to ṣoju wọn sọ pe ko din ni eeyan mẹwaa to ku, ti ọpọ si tun farapa pẹlu. Awọn obinrin ati awọn ọmọde si ni ikọlu naa kan ju bi wọn ṣe sọ.
Ileeṣẹ ologun kọkọ sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ, ṣugbọn lọjọ keji ni wọn fi atẹjade sita, ti wọn ṣalaye aṣiṣe to fa ikọlu naa.
4) Rann – ipinlẹ Borno, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, 2017
Eeyan ọgọrun-un kan ati mẹẹẹdogun (115) ni a gbọ pe wọn ku ninu ikọlu yii, nigba ti ọkọ ofurufu Naijiria ṣeṣi kọlu ibudo awọn ogunlende to wa ni Rann, nipinlẹ Borno.
Ṣaaju ni oṣiṣẹ kan nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Borno ti kọkọ sọ fun BBC, pe eeyan 236 lo ku, ati pe abule Rann lawọn ti sinku wọn.
Ṣugbọn lẹyin –o-rẹyin ni alaga ibilẹ Kala-Balge sọ pe eeyan 115 lo ku.
O ni aṣiṣe onka ni awọn araalu ṣe tẹlẹ ti wọn fi sọ pe 236 ni.
5) - Doma – ipinlẹ Nasarawa, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kin-in-ni 2023
Ikọlu awọn ologun yii pa awọn eeyan kan ti gbogbo wọn jẹ mọlẹbi kan naa.
Abule Doma lo ti ṣẹlẹ, nipinlẹ Nasarawa.
O kere tan, eeyan mejidinlọgbọn (28) ni wọn di oloogbe labule Rukubu, nijọba ibilẹ Doma, eyi to paala pẹlu ipinlẹ Benue.
Awọn darandaran kan ni wọn ko maaluu lati Benue lọ si apa ibo mi-in, awọn ni ologun fẹẹ koju ti wọn fi pa araalu mejidinlọgbọn.
6) - Maize Harvesting Quarter – ipinlẹ Borno, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, 2021
Ọpọ araalu lo ku ninu ikọlu yii, nigba ti ikọ to n dọdẹ ẹgbẹ agbesunmọmi, ISWAP, ṣina ado oloro bolẹ labule Kwatar Daban Masara, to wa ni apa Lake Chad.
Ẹka iroyin AFP sọ pe o kere tan, apẹja ogun (20) lo ba ikọlu naa lọ.
Ṣugbọn ikọ ologun ofurufu sọ pe eeyan kan ṣoṣo lo doloogbe, mẹfa si farapa.
Ṣugbon awọn iroyin kan sọ pe eeyan aadọta si ọgọta lo ku ninu ikọlu awon ologun naa.
7) - Mainok – ipinlẹ Borno, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, 2021
Ọpọ eeyan ni iroyin sọ pe wọn tun di olooogbe lọjọ yii, nigba ti baaluu ologun ṣina bole niluu Mainok, ti i ṣe kilomita marundinlọgọta si ilu Maiduguri.
Eeyan ọgbọn (30) ni awọn ẹṣọ alaabo kan fidi ẹ mulẹ pe wọn ku, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ologun ko kede nnkan kan.
Nigba to ya ni ileeṣẹ ologun ofurufu naa kede pe awọn n ṣewadii iṣẹlẹ naa lọwọ.
A gbọ pe awọn ISWAP pa ṣọja pupọ, eyi ni wọn fẹẹ gbẹsan rẹ to si ja siku ọpọ araalu.
8) - Mutumji –ipinlẹ Zamfara , ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila,2022
Baaluu ileeṣẹ ologun kan pa eeyan mẹrinlelọgọta (64) lọjọ yii. Abule Mutumji, nijọba ibilẹ Maru, ipinlẹ Zamfara lo ti ṣẹlẹ.
Ilu yii jẹ ọkan lara awọn ibi ti ikọlu ti maa n ṣẹlẹ deede.
Ṣugbọn lọjọ ikọlu yii, ẹmi alaiṣẹ araalu bọ.
Wọn ni eeyan mejila lo tun farapa, bẹẹ ni awọn agbebọn naa kagbako iku pẹlu.
9) - Kunkuman Bayan Dutse – ipinlẹ Katsina, ọjọ keje, oṣu Keje, 2022
Akọsilẹ sọ pe eeyan kan ku ninu ikọlu yii, mẹrinla si farapa yanna yanna.
Awọn agbebọn to n yọ ijọba ibilẹ Safana lẹnu ni awọn ologun fẹẹ kọlu
Awọn araalu sọ pe baaluu ologun lo ju bọmbu le awọn lori nigba ti wọn n wa awon agbebọn.
Ṣugbon ileeṣẹ ologun loun ko pa araalu, wọn ni agbebọn 24 lawọn pa.
10) Nachade – Ilẹ Olominira Niger, ogunjọ, oṣu Keji, 2022
Awọn ṣọja ṣeṣi pa ọmọde meje laaye ọtọọtọ, wọn si ṣe awọn maru-un mi-in leṣe ninu ikọlu kan to waye lọjọ yii lagbegbe Maradi, nilẹ Olominira Niger.
Gẹgẹ bi gomina agbegbe ibẹ ṣe ṣalaye fun ẹka iroyin French news agency.
Gomina agbegbe Maradi, Chaibou Aboubacar, ṣalaye pe awọn gbagbọ pe ikọ ologun ṣeṣi ju ado oloro naa sori awọn ọmọde ni, ki wọn le dọdẹ awọn agbebọn to n kọja lẹnu aala ilu naa ni.