You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo b'áwón èèyàn ṣe ṣayẹyẹ Kérésìmesì káàkiri àgbáyé
Lọdọọdun, awọn Kristẹni to le ni biliọnu meji kaakiri agbaye maa n kora wọn jọ lati ṣe ayẹyẹ ibi Jesu Kristi.
Eyi maa n waye ni gbogbo ọjọ karundinlọgbọn oṣu kejila ọdun.
Lati orilẹede Naijiria de awọn apa ibo mi-in l'Afrika, Europe, Asia, America ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn ọmọ lẹyin Jesu ti ṣ'ajọyọ fun ti ọdun yii naa.
Ayẹyẹ ọjọ ibi yii lo n waye lẹyin ẹgbẹrun meji ọdun o le ti wọn ti bi Jesu si Bethlehem, ni Guusu Jerusalem.
Bakan naa ni ayẹyẹ yii maa n ni gbọngbọn ninu nitori awọn idi kan, bẹrẹ lati ori awọ pupa ati awọ ewe ti wọn maa n lo lati sami ọdun Keresimesi, titi de ori awọn nnkan mi-in ti wọn fi n da ara oriṣiiriṣii lasiko isinmi yii.
Akoko ifẹ, ireti, ayọ, akojọpọ ati ififunni ni asiko Keresimesi.
Koda, lati ọjọ ti Keresimesi ti ku ọla ni awọn mi-in ti maa n bẹrẹ ajọyọ tiwọn.
Eyi ni diẹ ninu aworan awọn eeyan to ṣayẹyẹ ọdun Keresi ni 2024 yii, lati fi sami ibi Jesu Kristi.