You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
‘’Gómìnà Akeredolu kò kú o! ó wà láàyè’’
Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe ko si otitọ ninu iroyin to n kaakiri nipa iku gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu.
Ninu atẹjade ti ijọba fi lede gba ọwọ kọmiṣọnna fun iroyin, Abilekọ Bamidele Ademola-Olateju lo fi iroyin naa lede.
O rọ awọn ara araalu ipinlẹ Ondo lati da iroyin ẹlẹjẹ naa nu nipa gomina ipinlẹ Ondo.
Ọpọlọpọ iroyin lo ti n jade lori ilera gomina naa ati ọpọlọpọ awuyewuye.
Nibayii, gomina ko si ni ipinlẹ Ondo, ti ko si gbe ijọba silẹ fun igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa.
Lai fi ti iroyin to n ja ranyin ranyin se, kọmiṣọnna fun eto iroyin naa ni Akeredolu ti n se iṣẹ rẹ bo se yẹ, ki awọn ẹlẹgan gbẹnu dakẹ.
Amọ o ni lootọ ni aarẹ n se gomina naa.
‘’A ti gba iroyin orisirisi nipa ilera gomina Oluwarotimi Akeredolu, ti awọn eniyan si n pe lori aago lori ilera gomina naa.’’
A ti pinnu lati maṣẹ da awọn ọlọtẹ lohun, ti wọn si setan lati doju ijọba yii bolẹ.
Bio tilẹ jẹpe lootọ ni gomina naa wa lori idubulẹ aisan, amọ oun se isẹ rẹ bi iṣẹ lai wẹyin, ati ni akoko to yẹ.
Ijọba ipinlẹ Ondo wa kesi awọn araalu lati mase fi ti iroyin ẹlẹjẹ se.
Amọ ẹgbẹ oselu PDP ti kesi gomina ipinlẹ Ondo, Akeredolu lati kọ iwe fi ipo silẹ nitori ilera ti ko se deede.