You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Tinubu yan Femi Gbajabiamila gẹ́gẹ́ bí olorí òsìṣẹ̀ rẹ̀, Chief of Staff
Aarẹ orilẹede Naijiria,Bola Ahmed Tinubu ti kede Agbẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin Naijiria, Femi Gbajabiamila gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ rẹ.
Bakan naa ni aarẹ yan igbakeji gomina ipinlẹ Jigawa tẹlẹri,Ibarahi Hassan Hadeija gẹgẹ bi igbakeji olori awọn oṣiṣẹ.
Aarẹ Bola Tinubu gbe igbeṣẹ naa lasiko to n ṣepade pẹlu ajọ Progressive Governors Forum(PGF).
Bakan naa ni aarẹ darukọ gomina ipinlẹBenue tẹlẹri, George Akume gẹgẹ bi Akọwe ijọba apapọ (SGF).
Awọn miran to tun wa nibi ipade naa ni Babajide Sanwo-Olu (Lagos), Abdullahi Sule (Nasarawa), Umar Namadi (Jigawa), Inuwa Yahaya (Gombe), Yahaya Bello (Kogi), Ọjọgbọn Babagana Zulum (Borno), ati Mai Mala Buni (Yobe).
Awọn miran ti wọn tun wa nibẹ ni Uba Sani (Kaduna), Dikko Radda (Katsina), Father Hyacinth Alia (Benue), AbdulRahman AbdulRazaq (Kwara), Dapo Abiodun (Ogun), Umar Bago (Niger), Aliyu Ahmed (Sokoto), Francis Nwifuru (Ebonyi) ati Bassey Otu (Cross River).
Awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn ko si nibi ipade naa ni Oluwarotimi Akeredolu (Ondo), Biodun Oyebanji, ati Dr Nasir Idris (Kebbi).
Awọn miran ti wọn wa nibẹ ni igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Kashim Shettima, Tijjani Umar ati alaga ajọ EFCC tẹlẹri, Nuhu Ribadu.
Ipade yii jẹ ipade akọkọ laarin Aarẹ Tinubu ati awọn gomina labẹ ẹgbẹ APC ni ọṣẹ yii, ti wọn si tun sọrọ nipa yiyan adari ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin, iyansipo awọn minisita ati ọrọ ọwọngogo epo bẹntirol.