You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ori mi kọ̀! Mi o lè díje dù ipò ààrẹ takò Tinubu ní 2027- Wike
Minisita olu ilu Naijiria Nyesom Wike tipa ilu mọ awọn alehesọ lẹnu pẹlu bo ṣe loun ko le laelae dije tako aarẹ Tinubu lọdun 2027.
O fẹsi yi ni idahun si awuyewuye kan ṣe n waye pe o ṣeeṣe ki Minista olu ilu Naijiria yi gbe apoti ibo lọdun 2027.
O ni eleyi ko le waye nitori ọga oun ni Tinubu n ṣe.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun 2023 yii ni Wike sọrọ yii nibi ifọrọwerọ kan to waye l’Abuja.
Nyesom Wike sọ pe oun oun jẹ ọmọlubai to niwa ati pe iwa rere ko gbọdọ sọnu nitori oṣelu.
‘’ Tinubu lo sọ mi di minisita Olu-ilu Naijiria, mi o si ni i gba kẹnikẹni da ilana ọṣelu wa wo lulẹ.
‘’Mo niwa, awọn eeyan ko kan mọ ni.
Nigba ti ibeere waye pe ki lo lero pe yoo ṣẹlẹ ni 2027 Wike to fi igba kan jẹ Gomina ipinlẹ Rivers to si tun ti jẹ Minisita eto ẹkọ Naijiria ri sọ pe:
''Emi gẹgẹ bi ẹni to korira aisọ ọdodo, mi o le dije tako ọga mi ni 2027.''
O ni oun duro lori otitọ, oun ko si ni ṣatilẹyin fun aiṣododo.
‘’Wọn ti dunkoko mọ mi titi, wọn lawọn yoo ṣegba, awọn yoo ṣawo. Wọn gbiyanju oriṣiriṣi ọna, titi kan lilo ọga agba ologun.’’
‘’Ifẹ otitọ ti mo ni lo jẹ ka da ẹgbẹ G5 to polongo ibo aarẹ fun Tinubu silẹ’’
Nyesom Wike sọ ọ di mimọ pe oun pẹlu awọn gomina mẹrin mi-in ninu ẹgbẹ PDP, ko deede da ẹgbẹ G5 to polongo ibo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu silẹ.
O ni ifẹ otitọ toun ni lawọn fi polongo pe k’ iṣakoso agbara bọ sibo mii.
''Mi o fẹẹ sọrọ nipa Gomina ipinlẹ Rivers, ṣugbọn beeyan ko ba ti i nipo atowo, iwa oniwa lo maa n hu''
Nigba to n sọrọ lori ija oun ati Gomina Rivers bayii, Siminalayi Fubara, Wike to jẹ gomina ilu naa tẹlẹ, sọ pe oun ko fẹẹ sọrọ nipa rẹ.
O ni ṣugbọn ''bi eeyan kan ko ba ti i lowo ati ipo, iwa oniwa ni yoo ma hu.''
Wike sọ pe ''iwọ fun eeyan nipo agbara ati owo, igba naa ni wa a mọ iru ẹni ti i ṣe gan-an. Ti o ko ba ti i fun eeyan nipo atowo, ma sọ pe o mọ ọn o’’
Wike sọ pe o ba ni ninu jẹ pe laarin oṣu mẹta pere, ẹnikan si foju oloore rẹ gungi lai bikita.
O ni Gomina naa kọyin sẹgbẹ oṣelu to ti i lẹyin to si gbe e depo.
‘Dandan ni NIN abi BVN fawọn to ba fẹẹ ṣe C Of O’
Nipa iwe ‘Emi ni mo nilẹ’ (C of O) to gbe gba ọna igbalode, Wike sọ pe dandan ni kawọn eeyan ṣafihan iwe NIN to n kede wọn bii ọmọ Naijiria ati BVN to jẹ mọ ti banki.
O ni aabo to peye ni igbesẹ naa wa fun.
‘’ Awọn kan n ṣayederu iwe ‘Emi ni mo nilẹ’. Bi ileeṣe ko ba ni NIN, wọn yoo lo BVN.
Awọn eeyan pupọ ni ko ti i forukọ silẹ, ohun to maa jẹ ki wọn lọo forukọ silẹ ree.
‘’Awọn ti wọn ti ni C of O tẹlẹ ko ni i sanwo mọ’’
Minista fun Abuja naa ṣalaye pe awọn baba ati iya onile ti wọn ba ti ni iwe C of O tẹlẹ ko ni i sanwo mọ, owo diẹ ti wọn yoo kan fi fidi ohun ti wọn gbe dani naa mulẹ ni wọn yoo san.
Awọn yoo si fi NIN abi BVN si i.
“ Owo ti wọn maa san ko le ju fifti taosan lọ, abi ọndrẹdi taosan to ba jẹ ileeṣẹ. Iranlọwọ gidi leyi jẹ nipa aabo, yoo si tun pawo wọle funjọba’’ ni Wike wi.