Wo ohun ti Bàbá Yemi Elebuibon sọ nípa Murphy Afolabi àti bó ṣe kọ́ iṣẹ́ Ifá

Araba Awo ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti sọrọ lori awuyewuye ọrọ ẹsin to ṣẹyọ lẹyin iku gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Murphy Afolabi.

Elebuibon sọ pe ko tọna ki awọn ẹlẹsin kan maa sọrọ nipa ibi ti oloogbe n lọ lẹyin iku rẹ nitori Eledumare nikan lo mọ ẹni ti yoo wọ ina ati ẹni ti yoo ye.

Ọrọ yii jade ninu ifọrọwerọ ti Elebuibọn ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Alaroye.

Agba awo ọhun sọ pe ilu Atlanta, nilẹ Amẹrika ni oun wa lasiko ti oun gba ipe lati Naijiria pe Murphy ti jade laye.

Bi Murphy ṣe kọ iṣẹ awo

Nigba to n ṣalaye bi oloogbe naa ṣe kọ iṣẹ awo, Elebuibon sọ pe oun kọ loun kọ oloogbe naa ni iṣẹ ọhun gẹgẹ bii awọn iroyin kan to n lọ laarin ilu.

O ni “Bi o ṣe jẹ gan ni wipe, baba to bi Murphy, iyẹn Fabunmi Afolabi lo jẹ Araba ijẹta niluu Osogbo... baba rẹ jẹ ọkan ninu agba awo.”

“Nigba ti baba rẹ fẹ jẹ oye, Ọlọrun lo mi bii eroja lati ran baba yẹn lọwọ ki wọn le de ipo ti wọn n fẹ nigba naa.”

“Murphy Afolabi funra rẹ, baba rẹ fi si ọdọ babalawo ni Oyo, Faniyi Omoyeni ni orukọ baba awo to kọ Murphy ni Ifa.”

“Kii ṣe emi ni mo kọ Murphy ni Ifa, baba rẹ si kọ lo kọ emi ni Ifa, ẹni to kọ mi ni ifa ni Faniyi Ajani, to jẹ Agbongbon awo Osogbo to ti dfi oloogbe.”

Elebuibọn ṣalaye siwaju si pe asiko ti oun n ṣe Ifa eto Olokun Asọrọdayọ ni Murphy wa kọ ọgbọn mọ ọgbọn lọdọ oun, o ni o si jẹ ọmọ daadaa, onirẹlẹ ati ẹni to faramọ nnkan ibilẹ.

“Eledumare nikan lo mọ ẹni ti yoo wọ ina”

Ninu alaye rẹ, Elebuibon ni oun ko lodi si bi Murphy ṣe darapọ mọ ẹsin Musulumi.

O fi kun pe lootọ lo kọṣẹ Ifa, amọ ko fi ṣe iṣẹ ṣe, o kan n fi ṣe iṣẹ tiata ni.

“Nigba ti awọn babalawo ti gbọ wi pe o ti yipada si Musulumi, ko si ẹni to ja si, nnkan to fẹ lo ṣe yẹn... ko si ija nibẹ, ẹsin to wu eeyan lo le sin.”

Baba Elbuibon pari ọrọ rẹ pe ko tọna ki eeyan maa ṣedajọ ẹlọmiran nitori ẹsin wọn nitori ko si ẹni to mọ ẹni ti yoo wọ ina.

Ìdí rèé tí àwọn aláwo kò fi sin òkú Murphy Afolabi

Awọn ẹri tuntun ti jade lori iru ẹsin ti gbajumọ oṣere, Murphy Afolabi ṣe ko to o ku.

Lẹyin iku rẹ ni iroyin jade pe o wa ninu ẹgbẹ awo ko to o ku.

Waheeb Ibrahim to jẹ aburo oloogbe Murphy Afolabi sọ fun ileeṣẹ amohunmaworan GBOAH TV pe awọn ko gbọ iroyin pe boya o rẹ Murphy, iroyin iku rẹ nikan ni awọn gbọ́.

Ọgbẹni Ibrahim sọrọ lori awuyewuye kan to waye ṣaaju ki wọn o to o sin oku oloogbe Afolabi.

Lara awuyewuye to waye ni bi Alfa kan ṣe ni oun ko le sin oku tabi kirun si oku Murphy, nitori pe aláwo ni.

Bakan naa ni awọn kan gbagbọ pe bi ẹbi rẹ ṣe kọkọ ni ki wọn o gbe oku rẹ wa si agboole wọn niluu Osogbo fun isinku, niiṣe pẹlu pe o wa lati idile onífá.

Awọn kan ti ẹ sọ pe awọn aláwo ni yoo sin oku rẹ.

Ṣugbọn ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe nibi eto adura ọjọ kẹjọ ti wọn ṣe fun oloogbe ni agboole wọn, Alfa Ibrahim ṣalaye iru eeyan ti Murphy jẹ ninu ẹ̀sìn.

O ni “Murphy gan-an-gan ni Ifa, ti ko si si awo to tun fẹ ṣe mọ lẹyin eyi.

O ṣalaye pe nigba ti awọn wadii lẹnu aburo rẹ kan ti oun naa n gbe niluu Eko, lati mọ boya awọn ni yoo sin oku Murphy, o ni ẹni naa jẹ ko ye awọn pe “Murphy ko ba awọn alawo Eko ṣe”.

“Bakan naa ni awọn alawo ni ile (Osogbo) nigba ti a beere lọwọ wọn , sọ pe Murphy ko ba awọn ṣe.”

Alfa Ibrahim tẹsiwaju pe, iroyin ti awọn gbọ gẹgẹ bi ẹbi ni pe lati ọdun 2022 ni Murphy Afolabi ti n ki ìrun gẹgẹ bi musulumi.

“Koda wọn sọ fun wa pe o gba awẹ (Ramadan) lọdun to kọja, to si tun ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa ninu awẹ ọdun yii.”

O ni idi niyii ti awọn alawo ko fi le sin oku rẹ, nitori o fojuhan pe o ti di musulumi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ọhun lo tun ti mẹnuba a pe ọdun mẹwaa ni oloogbe Murphy Afolabi fi kọ iṣẹ awo niluu Oyo.

O ni inu ẹsin Islam ni Murphy ku si, eyi ti ko fi nii si aburu kankan nitori pe awọn alawo kọ lo sin oku rẹ.

"Baba to bi Murphy Afolabi lo kọ agbaọjẹ awo, Ifayemi Elebuibon niṣẹ awo

Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe Baba Murphy Afolabi lọ kọ Agbaọjẹ ninu awo sise Baba Ifayemi Elebuibon nisẹ awo tí Murphy Afolabi naa si pada lọ kọ isẹ awo parí lọdọ Baba Ifayemi Elebubon gẹgẹ bí awọn mọlẹbí ni agboole wọn ṣe ṣalaye.

Baba Murphy Afolabi lo ọgọfa ọdun le mẹrin (124years) laye ko to kú.

Murphy Afọlabi ṣalaye fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lọdun 2021 pe, ere itage ti agba oṣere ati agbaṣaga, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbubọn maa n ṣe kaakiri ilu Osogbo nigba naa ni o gbin irugbin ifẹ ere itage ati iṣẹ sinima si ọkan oun tofi di eyi to gbẹrẹgẹjigẹ ti gbogbo aye fi mọ oun.

O ni igba ti oun de ilu Eko loun darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Ọgbẹni Fasasi Ọlabankẹwin ti ọpọ m si Dagunro Alakija oogun.