Murphy Afolabi: Àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn aláwo Osogbo ti kọ́kọ́ gbáradì fún ìsìnkú Murphy àmọ́ ... - Olori Ẹbi

Àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn aláwo Osogbo ti kọ́kọ́ gbáradì fún ìsìnkú Murphy àmọ́ ... - Olori Ẹbi

Olori ẹbi oloogbe Iyiola Lateef Yusuf sọ fun ikọ BBC Yoruba pe, àwọn ko tii mọ boya pe o kọ ile sì ìlu Osogbo ṣugbón agbo ile ni awọn fi ẹnu ko sì lati kọkọ sìnku rẹ sì ko to di pe o yí pada.

Ileeṣẹ BBC News Yoruba kan si agbo ile Ile Fetu Ata ni agbegbe Okanla ni isale Osun niluu Osogbo nipinlẹ Osun nibi Murphy Afolabi ti wa.

“Murphy Afolabi ṣèlérí fún àwọn ẹbí rẹ pe, oun yoo wa sílè láti tún ilé molebi naa kọ leyin ti oun bá ṣe ayẹyẹ ọdún mokandinladota (49 years) tán kò tó di pé ọlọjọ de.”

Awọn molẹbí Murphy Afolabi ati awọn alawo ni ilu Osogbo ti kọkọ gbaradi fun eto ìsìnku gbajugbaja osere tiata naa ki wọn to yi ipinnu wọn pada lati lọ sin oloogbe naa si agbegbe Adamo niluu Ikorodu nipinlẹ Eko.

"Baba to bi Murphy Afolabi lo kọ agbaọjẹ awo, Ifayemi Elebuibon niṣẹ awo, Murphy naa si kọ iṣẹ awo"

Awọn mọlẹbí ti kọkọ ṣe ipade lẹyin ti wọn gbọ pe ọmọ wọn ti jade laye lati tẹ wọ gba oku rẹ, ki wọn si sin in si Ile mọlẹbi niluu Osogbo.

Baba to bi Oloogbe Murphy Afolabi, ti oun naa ti di oloogbe ni Oloye Fabunmi Afolabi, ẹni to jẹ Araba awo agba tí ilu Osogbo ni Ipinle Ọsun.

Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe Baba Murphy Afolabi lọ kọ Agbaọjẹ ninu awo sise Baba Ifayemi Elebuibon nisẹ awo tí Murphy Afolabi naa si pada lọ kọ isẹ awo parí lọdọ Baba Ifayemi Elebubon gẹgẹ bí awọn mọlẹbí ni agbo ile naa ṣe ṣalaye.

Baba Murphy Afolabi lo ọgọfa ọdun le mẹrin (124years) laye ko to kú.

Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni àgó mẹ́san-an àbọ̀, ó ṣubú ni àgó mẹ́wàá àlẹ̀ - Golugo

"Irọ ni iroyin kan to n ja kiri pe awọn alawo ti ge ori ati eti Murphy Afolabi lẹyin to jade laye."

Gbajugbaja oṣere tiata, Adekola Tijani ti ọpọ mọ si Golugo ti sọrọ nipa bi irinajo gbajugbaja oṣere tiata to di oloogbe, Murphy Afolabi se wa sopin lọjọ Aiku ọsẹ yii niluu Eko.

Golugo, lasiko to n ba Ileeṣẹ BBC News Yoruba sọrọ nibi eto isinku oloogbe naa to waye ni Adamọ niluu Ikorodu ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun nitori oun pẹlu Murphy sọrọ ọgbọn isẹju sẹyin ki oun to gbọ iroyin pe o subu.

“Emi ati Murphy sọrọ ni ago mẹsan abọ, o ṣubu ni ago mẹwaa ni wọn pe mi pe o ṣubu".

“Mo ni ki lo sẹlẹ, wọn ni ki n ṣaaa maa bọ, bi mo ṣe de ibẹ, mo ni ki a gbe e sinu ọkọ ka maa lọ ile iwosan ṣugbọn Murphy ti dakẹ ki a to de ile wosan

“Ko si nnkan ti a le ba Ọlọrun fa nitori a ko gbọn ko Ọlọrun, ọdọ Ọlọrun ni a ti wa, ọdọ rẹ naa ni a maa pada si. Gbogbo nnkan Murphy lo ti di ohun igbagbe.

“Ọmọ kekere ni Murphy, a jọ bẹrẹ ni, emi ni mo baa ya sinima rẹ akọkọ, nnkan da emi ati Murphy papọ gan".

Ọdun marun un ni Murphy fi gba mi sile - Nofisat Olayiwola

Pẹlu omije loju ni Osere tiata, Nofisat Olayiwola ti ọpọ mọ si Ọmọ Ẹja fiṣsalaye ibaṣepọ rẹ pẹlu Oloogbe Murphy Afolabi nibi eto isinku rẹ.

Nofisat ni igba ti oun fẹ ṣe sinima rẹ akọkọ, oun ko ni owo kankan lọwọ ṣugbọn oloogbe ni ki oun lọ mu iyekiye ti oun ba ni wa lati fi se sinima to di ilumọọka naa.

“Murphy ni ki lọ mu iyekiye wa, o dẹ ya sinima ọhun, apa kini ati ikeji niluu Osogbo.

“Mi o le gbagbe Murphy laye, mi o ni ile niluu Eko, Murphy lo tẹwọgba gba mi sile rẹ fun ọdun marun un".

Ọpọ awọn osere tiata ni wọn ya wọ ileegbe oloogbe niluu Ikorodu lati ṣe adura ikẹyin fun un.