Adájọ́ tó n gbẹ́jọ́ Seun Kuti kò yọjú, láwọn alátìlẹ́yìn ba ṣe ìwọ́de níwájú ilé ẹjọ́

Gbajugbaja akọrin ọmọ Fela Anikulapo Kuti, Seun Kuti ko ribi foju kan adajọ to n gbọ ẹjọ rẹ nibi ijoko ile ẹjọ to yẹ ko waye lọjọ Iṣẹgun.

Idi ni pe adajọ naa ko raaye wa sile ẹjọ.

Adajọ Adeola Olatubosun to n gbẹjọ naa ko sọ idi ti oun ko fi yọju.

Wọn ti sun igbẹjọ naa di Ọjọru bayii.

Toun ti bẹẹ awọn ololufẹ ati alatilẹyin Seun Kuti ko ara wọn jọ niwaju ile ẹjọ lati ṣe iwọde ranpẹ fi ẹhonu wọn han.

Iwọde taa n wi yi waye niwaju ile ẹjọ majistereeti to wa ni ilu Eko.

Akọroyin BBC to wa nibi iwọde yi ṣalaye pe awọn to sọrọ nibi iwọde yi ni ko tọ bi awọn ọlọpaa ṣe wọ Seun Kuti lọ sile ẹjọ.

Wọn ni idunkoko mọ ẹmi Seun lo mu ki o gba ọlọpaa naa leti tori naa ọlọpaa kan fẹ halẹ mọ ni pẹlu igbẹjọ yi.

Niṣe ni wọn kesi awọn alaṣẹ lati tu Seun Kuti silẹ lai si idiwọ kankan.

O ti pe nkan bi ọjọ mẹfa tabi ju bẹẹ lọ ti Seun Kuti ti wa ni ahamọ ọlọpaa.

Ọjọ meji ni wọn kọkọ figbe si ahamọ ki wọn tun wa to beere ọjọ mẹrin miran si.

Ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ṣe ikọlu si ọlọpaa ni itako ofin orileede Naijiria.

Lẹni igba ti awuyewuye yi bẹrẹ, ero araalu pin lori boya Seun jẹbi tabi ohun to ṣe ko ti buru ju.

Bawọn kan ṣe n sọ pe ọlọpaa Naijiria naa a maa dunkoko mọ araalu lawọn miran n sọ pe Seun Kuti lo ipo rẹ gẹgẹ bi gbajumọ ilumọọka lọna aitọ.

Seun Kuti fojú ba ilé ẹjọ́, ohun tí adájọ́ sọ rèé

Ilé ẹjọ́ májísíréètì Yaba, ìpínlẹ̀ Eko ti pàṣẹ pé kí Seun Kuti ṣì wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá fún ọjọ́ méjì si tí ìwádìí máa fi parí lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án pé ó gbá ọlọ́pàá létí.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wọ Seun Kuti lọ sílé ẹjọ́ pé àwọn fẹ́ kó lo ọjọ́ mọ́kànlélógún ní àhámọ́ àwọn kí àwọn fi parí ìwádìí tí àwọn ń ṣe lórí ìdí tó fi gbá ọlọ́pàá náà létí.

Adájọ́ Adeola Olatunbosun ní kí wọ́n fi Seun Kuti sí àhámọ́ fún ọjọ́ méjì péré si dípò ọjọ́ mọ́kànlálógún tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń bèèrè.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ sọ fún àwọn ọlọ́pàá láti parí ìwádìí wọn láàárín ọjọ́ méjì yìí kí wọ́n sì gbà Seun Kuti láti máa wá jẹ́jọ́ láti ilé.

Adájọ́ Olatunbosun tún fi kun pé kí àwọn ọlọ́pàá gbé ẹjọ́ náà lé ẹ̀ka tó ń rí sí bíbáni pe ẹjọ́ ti ìpínlẹ̀ Eko fún ìmọ̀ràn tó péye lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó ní ilé ẹjọ́ ti pinnu láti kọtí ọ̀gbọin sí gbogbo nǹkan tí àwọn ènìyàn bá ń sọ tí àwọn yóò sì gbé ìdájọ́ àwọn kalẹ̀ bó ṣe yẹ.

Mílíọ̀nù kan náírà ni ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n fi gba béèlì Seun Kuti lẹ́yìn ọjọ́ méjì tó bá tún lò si ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.

Bákan náà ló nílò onídúró méjì tó ní iye owó náà, tí ọ̀kan nínú wọn sì gbọdọ̀ ní ilẹ̀ ní agbègbè tí ilé ẹjọ́ náà wà.

Ṣaájú ni agbẹjọ́rò Kuti, Adeyinka Olumide-Fusika ti fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọn ò gba ìyàwó Kuti láàyè láti gbé oúnjẹ fún-un tó sì jẹ́ wí pé wọn kò ní ọ̀nà tí wan fẹ́ fi fun ní oúnjẹ.

Seun Kuti sun àgọ́ ọlọ́pàá mọ́jú, yóò fojú balé ẹjọ́ láìpẹ́

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ pe Seun Kuti yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin to jọwọ ara rẹ fun ọlọpaa latari bo ṣe bu ifọti lu ọlọpaa kan lẹnu iṣẹ lọjọ Abamẹta.

Alukoro ileẹṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin abẹle Punch pe olorin naa yoo sun agọ ọlọpaa mọju ko to foju bale ẹjọ.

O ni “Seun Kuti ṣi wa lakata wa, yoo foju bale ẹjọ ti iwadii ẹsun ti a fi kan an bati pari.”

Ṣaaju ni Seun ti kọkọ yọnda ara rẹ fun ọlọpaa ni agọ CID wọn, iyẹn Panti, to wa ni Yaba, niluu Eko.

Afurasi naa ati agbẹjoro agba, Adeyinka Olumide-Fusika, SAN , to fi mọ agbẹjọro mii, Femi Akinyemi, lati ileeṣẹ agbẹjọro agba, Femi Falana, ni wọn jọ kọwọ rin lọ agọ ọlọpaa.

Ọjọ Aje ni ọlọpaa ṣafihan fidio bi Seun ṣe fi ẹsẹ ara rẹ rin wọ agọ awọn, lẹyin naa ni wọn fi aworan rẹ lede, pẹlu mamugaari lọwọ.

Bi Seun ṣe wọ panpẹ ọlọpaa

Ọjọ Abamẹta ni Seun wọ gau lẹyin ti fidio bo ṣe bu ifọti lu ọlọpaa kan lori afara Third Mainland niluu Eko ṣe fa ori ayelujara ya.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu iwa ti Seun wu ninu fidio naa.

Amọ nigba ti Seun yoo sọrọ loju opo Instagram rẹ, o ni ṣe ni ọlọpaa naa gbiyanju lati gbẹmi oun ati mọlẹbi oun.

Ẹwẹ, iroyin kan sọ pe ọlọpaa ti afurasi naa gba loju tọpinpin rẹ lọ sile rẹ lagbegbe Allen Avenue, ni Ikeja, ti afurasi ọhun si fun ni ẹgbẹrun mejila naira lati tun ọkọ rẹ ṣe.

Wayi o, agbẹjọro Seun, Olumide-Fusika, ti bu ẹnu atẹ lu ọlọpaa lori ẹsun pe wọn patẹ onibara oun si ori ayelujara, nibi ti ọpọ araalu ti n sọrọ kobakungbe nipa rẹ.

Olumide-Fusika ni onibara oun ko tii jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an titi di igba ti ile ẹjọ ba ṣedajọ rẹ.

Seun Kuti tó gbá ọlọ́pàá létí l'Eko ti wà láhámọ́

Seun Kuti, ọmọ gbajugbaja akọrin ni Fẹla Anikulapo-Kuti ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa bayii.

Lọjọ Satide ni okiki kan pe Ṣeun Kuti gba eti ọlọpaa kan ti fidio rẹ si tan bi itanṣan oorun loju opo ayelujara ni gbogbo opin ọsẹ to kọja.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi sita loju opo Twitter rẹ lọjọ Aje pe ni kutkutu ọjọ Aje ni Seun jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpaa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa ni Ikẹja.

O fi kun un pe agbẹjọro rẹ pẹlu aṣoju mọlẹbi rẹ kan pẹlu baa kọwọrin wa si ileeṣẹ ọlọpaa.

Gẹgẹbi iroyin ti o tẹ wa lọwọ pẹlu awọn ọlọpaa ti taare Seun Kuti si ẹka ọtẹlẹmuye, SCID Panti ni Yaba fun iwadi lori iṣẹlẹ naa.

'Ṣeun gba Ọlọpaa leti nilu Eko'

Ni ọjọ Satide ni fidio kan jade eyi to ṣe afihan Seun Kuti nibi to ti gba ọlọpaa kan leti lasiko ariyanjiyan kan laarin opopna ni Eko.

Ọkanojọkan ọrọ ẹhonu ati ariyanjiyan lo ti waye lori ọrọ yii ti ọpọ si ti bu ẹnu atẹ lu ihuwasi ọmọ gbajumọ olorin Afrobeat naa ti wọn si ni iwa to ku diẹ kaa to ni o hu ati pe ko si iwa yoowu ti agbofinro le e hu to yẹ ko faaye gba ki eeyan gba a leti bi o ṣe ṣe ninu fidio naa.

Sibẹ awọn miran n woye pe o gbọdọ ni idi pato ti o mu ki Ṣeun Kuti hu iru iwa to hu naa.

Igun awọn wọnyi n sọ eyi labẹ ariwisi ihuwasi awọn ọlọpaa miran loju popo lọpọ igba, eyi ti wọn ni kii bojumu.

Ọlọpaa naa fẹ pa mi ni -Seun Kuti

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter rẹ, Seun ṣalaye pe agbofinro naa gbiyanju lati gba ẹmi oun ati ẹbi oun.

O ni gbogbo ẹri to yẹ nipa eyi ni oun ni lọwọ ati pe ọlọpaa naa le e padanu iṣẹ rẹ bi oun ba lo awọn ẹri yii labẹ ofin.

O fi kun un pe oun ṣetan lati fara han fun iwadii yoowu ti ọlọpaa ba fẹ ṣe lori ọrọ naa.