Àwọn afurasí mẹ́rin kó sí àhámọ́ ọlọ́pàá fẹ́sùn pé wọ́n pa darandaran ní Ogun

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn afurasí mẹ́rin kan ti wà ní àhámọ́ àwọn fẹ́sùn wí pé wọ́n pa darandaran kan ní ìlú Ijagunre, ìjọba ìbílẹ̀ Imeko-Afon, ìpínlẹ̀ Ogun.

Darandaran ni wọ́n tún ní wọ́n kun wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa á tán.

Ṣáájú ni ọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ogun ti kọ́kọ́ tẹ méjì nínú àwọn afurasí ọ̀hún tí wọ́n sì fà wọ́n lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.

Ìròyìn tún ní àwọn ìpínlẹ̀ Oyo ló nawọ́ gán àwọn afurasí méjì yòókù, tí àwọn náà sì fà wọ́n lé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun lọ́wọ́.

Agbenusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi tó fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ní ọjọ́ Ajé ní àwọn afurasí ni ìrètí wà wí pé wọ́n nínú ikú darandaran tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Umaru Aliyu.

Oyeyemi ní orúkọ àwọn afurasí náà ni Akinyele Adebayo, Gbalo Idosu, Abiala Segun àti Kareem Lana.

Ó ní ẹbí olóògbé náà kan, Umaru Jakake ló lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé òun àti ẹ̀gbọ́n òun ni àwọn ń da ẹran jẹ̀ nínú oko gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn kí àgbẹ̀ kan tó dá àwọn lọ́nà pé àwọn kò gbọdọ̀ dá ẹran gba oko òun.

Jakake ní èyí ló mú kí àwọn darí àwọn ẹran àwọn gba ibòmíràn àmọ́ àgbẹ̀ náà kò fi àwọn lọ́rùn sílẹ̀ tó sì pe àwọn méjì mìíràn kúnra tí wọ́n ń lé àwọn kiri nínú igbó.

Ó ní bí òun ṣe sálọ nìyẹn àmọ́ tí àwọn kò rí ẹ̀gbọ́n òun mọ́.

Agbenusọ ọlọ́pàá ní ìwádìí tí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn ṣe ni wọ́n fi nawọ́ gán àwọn afurasí ọ̀hún àmọ́ tí àgbẹ̀ náà sì ti na pápá bora.

Oyeyemi ní àwọn ọlọ́pàá ti ṣàwárí orí àti àwọn ẹ̀yà ara olóògbé náà.

Bákan náà ló ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Olanrewaju Oladimeji wá kan sáárá sí àwọn ẹ̀ka tó ṣàwárí àwọn afurasí náà.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ó rọ̀ wọ́n láti ṣe àwárí àwọn tó kù tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó fi kun pé ní kété tí ìwádìí bá ti parí ni àwọn afurasí náà yóò fojú ba ilé ẹjọ́.