Jaye Kuti: Ẹ dẹ́kun irọ́ pípa, orúkọ ọkọ mi ni àwọn ọmọ mi n jẹ kìí ṣe Ajibola Pasuma

BBC Yoruba wa gbajugbaja oṣerebinrin ni, Jaye Kuti kan lati ṣe ifọrọwanilenuwo pẹlu rẹ.

Durojayeola,, Banjoko, Durosinmi, abegbọ, aja ati bẹẹ bẹẹ lọ ni orukọ abiku ti Obi Jaye Kuti sọ ọ nitori pe o ti waye ni ọpọ igba ki Olodumare to fun un ni oore ọfẹ lati baye pe.

Oṣere yii ṣalaye ni kikun fun BBC nipa ajọṣepọ oun ati ogbontarigi akọrin fuji ni, Pasuma Alabi.

Kini Jaye Kkuti tunsọ nipa iriri re?

Durojaye Kuti sọ nipa irinajo rẹ lati agbegba sabo Geri ti Obi rẹ bii si nipinle Kano titi to fi de si Mushin nipinle Eko.

Bakan naa lo mẹnuba iṣẹ oojọ to ti ṣe sẹyina ti awon ọja bii iyọ, kerosiini, ogi ati bẹẹ bẹẹ lọ to ti ri gẹgẹ bii ọmọ to lọwọ aje.