Ohun tí a mọ̀ lórí ọkùnrin kan tó kú sílé ìtura kan ní ìpínlẹ̀ Ondo rèé

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olanreawaju.

Ní ilé ìtura kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Ondo West ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lálẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá, ọdún 2022.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ ilé iṣẹ́ BBC News Yorùbá lọ́wọ́ nígbà tí a kàn sí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmilayo Odulami ní lẹ́yìn tí ọkùnrin náà wẹ̀ tán láti máa lọ sílé rẹ̀ ló dédé ṣubú lulẹ̀ tó sì dágbére fáyé.

Odulami ní nígbà tí obìnrin tí wọ́n jọ lọ sí ilé ìtura ri pé ọkùnrin náà kò mí mọ́ ló figbe ta láti fi pe àwọn aláṣẹ ilé ìtura ọ̀hún sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

Ó ní èyí ló mú àwọn alásẹ ilé ìtura náà láti kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá Enu-Owa tí wọ́n sì ti gbé òkú ọkùnrin ọ̀hún lọ sí ilé ìgbóòkúsí ilé ìwòsàn University of Medical Sciences, Ondo fún àyẹ̀wò tó péye.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó gba ìgboro wí pé mágùn ló pa ọkùnrin náà, Odunlami ní kò sí ohun kankan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé mágùn lọ pa ọkùnrin náà.

Bákan náà ló ní àwọn kò ì tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bóyá olóṣèlú ni ọkùnrin ọ̀hún.

Odunlami fi kun pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan múlẹ̀ àti pé ní kété ni ìwádìí àwọn bá ti jáde ni àwọn máa fi àbọ̀ ìwádìí àwọn síta.