You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kélé òfin gbé afurasí akẹ́kọ̀ọ́ fásítì UI tó fipá bá akẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ n'Ibadan
Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ akẹkọọ kan to wa ni ipele ikeji eto ẹkọ ni ẹka imọ nipa ofin ni fasiti ilẹ Ibadan, UI, lori ẹsun fifi ipa ba ọmọbinrin akẹkọọ kan to ṣẹṣẹ wọle si ipele akoko lopọ ninu ọgba ile ẹkọ naa.
Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe ọmọbinrin naa lọ kawe alẹ pẹlu awọn akẹkọọ 'binrin mii ni igbaradi fun idanwo.
Ina dede lọ ni iyara ti wọn ti n ka iwe, eyii lo si mu ki ọmọbinrin naa jade lọ sun si ibi ile kan ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ n lo ninu ọgba ile ẹkọ naa, nibi ti afurasi naa ti ri i to si fi ipa mu un mọlẹ.
Ọmọbinrin naa ṣe alaye fun awọn akọroyin wi pe loju orun ni oun ti taji nigba ti oun ko fiiri ọwọ kan to n rin kiri ni ara oun, ṣugbọn afurasi naa fun un lọrun mọlẹ, ti o si jẹ ki o nira fun un lati kigbe sita.
O ni ori ko oun yọ nigba ti akẹkọọ kan dede rin kọja nibi iṣẹlẹ naa, eyii lo si mu ki afurasi naa sa lọ.
Ṣugbọn ọmọbinrin naa fi ara pa nibi ọrun, ete ati ni oju ara rẹ.
Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ, ẹni ti o jẹ alukoro fun ile ẹkọ giga naa, Arabinrin Joke Akinpelu fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, gẹgẹ bi o ṣe fi kun ọrọ rẹ wi pe iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
O ni lati ọjọ ti iṣẹlẹ naa ti waye ni kele ofin ti gbe afurasi naa, ti wọn si ti fi ọrọ naa to alakoso ọrọ awọn akẹkọọ leti.
Akinpelu ni gbogbo eniyan ni yoo lanfani si abajade iṣẹ iwadii naa nigba to ba yọri.