Kókó ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà mẹ́fà tó wà nínú àbá tí ilé aṣojú-ṣòfin wọ́gilé torí ẹ̀hónú aráàlú

Oríṣun àwòrán, House of Reps/Facebook
Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti yari fun igbesẹ ile igbimọ aṣoju-sofin kan, eyi to daba lati gbe awọn ofin tuntun sita.
Opo awọn ọdọ lori opo ayelujara X lo ti fi ẹhonu wọn lori aba naa, ti wọn pe fun wiwọgile ni ẹsẹkẹsẹ.
Agbẹnugan ile igbimọ aṣoju-sofin, Abass Tajudeen lo gbe aba naa sita, to si ni ohun ni erongba pe aba naa yoo dẹkun awọn iwa kan to lodi si ofin.
Abass ni oun ko fi aba yii ba ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan wi, to jẹ pe oun gbe aba naa jade fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
“Aba yii fẹm gbe ogun ti iwa ibajẹ ati kudiẹkudiẹ eto abo, awọn orilẹede bii United Kingdom, Spain, India, Turkey, Canada, Australia ati awọn mii ti gbe igbesẹ yii.
Sugbọn ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti kọyin si aba naa
Ki gan lo wa ninu abadofin naa?
Awọn ofin to wa ninu abadofin to da wahala silẹ lori ayelujara naa re
- Ẹnikẹni to ba tabuku si nnkan idanimọ tabi kọ lati kọ orin orilẹede Naijiria ati adura, tabi tabuku si ile ijọsin, ti da ẹsẹ nla, ti yoo si san owo itanran milọnu marun un naira tabi ko lọ ẹwọn ọdun mẹwaa, tabi mejeeji
- “Abala kejidinlogun abadofin naa ni ẹsẹ nla ni ki ẹnikẹni ṣe ikọlu si olori agbegbe, ti ẹṣin, olori ijọba ibilẹ, ipinlẹ tabi ti ijọba apapọ, ti ile ẹjọ ba ni ẹnikẹni jẹbi ẹsun naa, yoo san milọnu marun un naira, tabi ko lọ si ẹwọn ọdun meji, tabi mejeeji
- Ẹnikẹni to hu iwa to fihan pe o kẹyin si orilẹede Naijiria, to si n se atilẹyin fun orilẹede mii, lai se otitọ pẹlu orilẹede Naijiria, ti da ẹsẹ nla, ti irufẹ eeyan bẹ yoo san owo toto milọnu marun un naira tabi ko lọ si ẹwọn ọdun mẹwaa
- Ẹnikẹni to ba n sisẹ pẹlu awọn ileeṣẹ to n dunkoko mọ ominira orilẹede Naijiria, tabi ki ẹnikẹni gba lati darapọ mọ iru ileeṣẹ bẹẹ ti tapa si ofin, ti yoo si san owo itanran toto miliọnu mẹta tabi ko lọ ẹwọn ọdun mẹrin
- Ẹnikẹni to ba kuna lati tẹle tabi tabuku si ofin orilẹede Naijiria yoo lọ ẹwọn ọdun mẹta, to ba tun wa sẹ si ofin ni ẹẹkan si, yoo lọ ẹwọn ọdun meje tabi ko san owo itanran milọnu marun un, tabi mejeeji
- Ẹnikẹni to ba sọrọ tabi se ohunkohun lati jẹ ki eeyan mii tabi ẹgbẹ gbe igbesẹ to n pe fun ipinya orilẹede Naijiria, tabi da wahala silẹ, ti tapa si ofin ti yoo si an owo itanran toto milọnu mẹwaa, tabi ko lọ ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn tabi mejeeji.
Ofin yii tun tọka si awọn ẹsun mii, fun apẹẹrẹ nini ajọsepọ pẹlu awọn ẹgbẹ okunkun ati awọn janduku ni ile tabi ni oke okun, fifa sunkẹrẹ fakẹrẹ ni ilana ti ko ba ofin mu, gbigbe igi dana, kikede ofin konile-gbele ati awọn ẹsun mii.
Ki awọn ọmọ Naijiria sọ nipa abadofin naa?
Orin orilẹede Naijiria lo jẹ ohun akọkọ to n leke tabili lori ayelujara X lorilẹede Naijiria, ti ọpọ eeyan si n bu ẹnu atẹlu aba naa.
Fọnran gbajumọ ajafẹtọ ọmọniyan, Aisha Yesufu jade sita nibi oṣu diẹ sẹyin nibi to ti kede pe oun ko ni kọ orin orilẹede tuntun ti Aarẹ Bola Tinubu buwọlu.
Yesufu ni o san ki oun lọ si ẹwọn fun ogun ọdun ju ki oun kọ “orin orilẹede Tinubu”
“Ile igbimọ aṣoju-sofin ro pe awọn le fi tipatipa mu wa? Awọn alawada,” O sọ lori ọrọ kan to gbe sori ayelujara.
Bakan naa, agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan, Inibehe Effiong sọ fun BBC pe abadofin yii lo jẹ eyi ti ko mu ọpọlọ dani.
O tun gbe sori opo ayelujara X rẹ, “ A ni lati ja tako abadofin yii. Ti wọn ba fi le buwọlu ofin yii, a ti dagbere fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria.”
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ni abadofin naa waye nitori iwọde to waye kaakiri orilẹede Naijiria, bẹrẹ lati ọjọ kinni si ọjọ kẹwaa nitori ebi ati inira to wa ni ilu.
Abẹnugan ile wọgile abadofin ọhun
Abẹnugan ile igbimọ aṣoju sofin I’Abuja ti wọgile abadofin ‘Counter Subversion Bill’ ti o gbe wa siwaju ile .
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti ọpọ araalu lori ayelujara bẹrẹ si ma binu si abadofin ni olori ile gbe wa pẹlu erongba lati fofin de awọn ileeṣẹ, ajọ, awọn agbebọn, janduku ati awọn ẹgbẹ mii.
Abadofin yii ni ọpọ eeyan ni gbagbọ pe yoo se akoba fun ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria.
“Abẹnugan ile igbimọ aṣoju-sofin ti pinnu lati wọgile abadofin to gbe wa siwaju ile ati awọn aba mii to ni ajọsepọ pẹlu rẹ,”
eyi lo wa ninu atẹjade ti agbẹnusọ abẹnugab ile, Mus Krishu fi lede ni ọjọ kẹrinla oṣu kẹjọ ọdun 2024.
“Abẹnugab ile, Abbas Tajudeen jẹ eeyan to fẹran ilu, ti yoo si ma se nnkan to rọ awọn araalu lọrun.’















