Falcons Naijiria ń kojú South Africa, Morocco ń kojú Ghana lábala tó kángun sí àṣekágbá ìdíje WAFCON 2024

Lati apa ọtun, Rasheedat Ajibade, Ghizlane Chebbak, Doris Boaduwaa ati Linda Motlhalo ti kalulu n gba bọọlu fun orilẹede rẹ ninu idije WAFCON to n lọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Confederation of African Football

    • Author, Rob Stevens
    • Role, BBC Sport Africa, Casablanca
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọjọ Iṣẹgun, ifẹsẹwọnsẹ alagbara meji yoo waye labala to kangun si aṣekagba ninu idije ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Africa, WAFCON 2024 to n lọ lọwọ lorilẹede Morocco.

Akọkọ ni ti orilẹede wa Naijiria to ti gba ife ẹyẹ naa nigba mẹsan-an.

Naijiria yoo maa wa a ko pẹlu orilẹeede South Africa ti ife ẹyẹ naa wa lọwọ wọn lọwọlọwọ, ni Casablanca, aago marun-un irọlẹ oni ni yoo waye lọjọ Iṣẹgun.

Ikeji si ni ti Morocco ti yoo maa koju Ghana, aago mẹjọ ni yoo waye.

O ṣee ṣe ki iru ohun to ṣẹlẹ nipele aṣekagba idije ọdun 2022 tun waye, nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu Banyana Banyana ti fi agba han Atlas Lionesses, ami ayo meji si ẹyọkan, nigba to ba di irọlẹ Satide.

Fun Morocco ati Ghana, eyi yoo jẹ igba akọkọ ti wọn yoo jawe olubori, nigba ti apapọ ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Africa (Confederation of African Football) ti ṣe afikun owo ti ẹni to ba jawe olubori yoo gba si miliọnu kan dọla ($1m), wọn si ti ṣiṣọ loju ife ẹyẹ tuntun pẹlu.

Ìfigagbága ọ̀tun bẹ̀rẹ̀

Esther Okoronkwo, agbabọọlu Naijiria ree lasiko to n yọ fun ami ayo ti Naijiria gba si àwọ́n pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix

Ni itẹsiwaju idije naa, orilẹede Naijiria fitan balẹ nigba ti wọn fi agba han Zambia pẹlu ami ayo marun-un si odo ni Casablanca .

Ẹlẹsẹ ayo Super Falcons tẹlẹ, Desire Oparanozie, ṣapejuwe bi wọn ṣe gba bọọlu sawọn bi eyi ti ẹnikẹni ko rokan. O ni ṣugbọn oun ri i iyatọ nla ninu ijade wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Awọn agbabọọlu Super Falcons maa n ni erongba lati gbegba oroke, ifẹṣẹwọnsẹ nla-nla ni wọn si ti maa n kopa."

Oparanozie lo ṣalaye bẹẹ fun Sportsworld lẹka iroyin agbaye BBC.

O ni wọn fi han pe Naijiria ni agba nilẹẹ Africa.

Ohun to ku bayii ni ki wọn ri i daju pe ọna ti wọn n gba na awọn yoku ni koboko ami ayo ko bajẹ, nigba ti wọn ba pada si papa iṣere Larbi Zaouli .

" Afojusun wa ni lati maa tẹsiwaju ninu erongba aṣeyọri, awọn idije nla bayii lo maa n tọka bi ilẹ Africa ṣe jẹ gan-an."

Amule fun Super Falcons, Chiamaka Nnadozie, lo sọ bẹẹ fun BBC World Service.

Ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu South Africa ni igbagbọ wa pe yoo tun lagbara .

South Africa to fagba han Senegal pẹlu ami ayo mẹrin si odo, nigba ti wọn fi pẹnariti yanju ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ pari si odo.

Ifẹsẹwọnsẹ naa mu South Africa lomi, pẹlu bi wọn ko ṣe ni ju ọjọ kan lọ lati ṣarajọ pada, ki wọn si tun rin irin ajo lati Berkane.

Ṣugbọn akọnimọọgba Banyana Banyana, Desiree Ellis, sọ pe awọn agbabọọlu oun ko ni i fi iyẹn kẹwọ.

Naijiria fagba han South Africa ninu idije aṣekagba WAFCON ni 2000 ati 2018, ṣugbọn orilẹede naa lu Naijiria ni ami ayo meji si ẹyọkan lọdun mẹta sẹyin.

" Awọn ni ife ẹyẹ naa wa lọwọ wọn lọwọ, iṣẹ pọ lọwọ wọn lati ma jẹ ko bọ" Oparanozie lo sọ bẹẹ.

"Ifigagbaga yii ti wa nilẹ fun ọpọlọpọ ọdun, idije aṣekagba yii yoo si lagbara gan-an fun Naijiria.

" South Africa nikan lo jọ ilu to le dena Naijiria lati ma jawe olubori."

Bẹẹ ni Oparanozie wi.

Àwọn Atlas Lionesses náà fẹ́ẹ́ dé àṣekágbá

Ghizlane Chebbak.

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix

Àkọlé àwòrán, Balogun ikọ agbabọọlu Morocco, Ghizlane Chebbak.

Lẹyin ti wọn koju Mali pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọkan, ikọ agbabọọlu to n gbalejo idije yii naa n foju sọna lati de aṣekagba.

Bẹẹ ni wọn n reti ero rẹpẹtẹ ni papa iṣere wọn to le gba eeyan ẹgbẹrun mọkanlelogun, (21,000) ti wọn yoo maa mu ori awọn ikọ agbabọọlu Atlas Lionesses wu.

" Awọn eeyan to ti wa si papa iṣere ti ran wa lọwọ gan-an lati ibẹrẹ. Bo ṣe maa n ri niyẹn, awa naa si lero pe a maa de ipele aṣekagba."

Akọnimọọgba ,Jorge Vilda lo ṣalaye bẹẹ.

Bakan naa ni orilẹede Ghana ti gbaradi fun ipele kẹrin to gbẹyin fun igba akọkọ lati 2016, lẹyin ti wọn fi pẹnariti bori Algeria ninu idije to kọkọ ba òdo de fun awọn mejeeji ni Satide.

Akọnimọọgba won, Kim Lars Bjorkegren, ṣalaye pe apọju ero ko le da ẹru ba ikọ oun.

"Ero rẹpẹtẹ le ran ọ lọwọ to ba ja si ọjọ ire fun eeyan, ṣugbọn mo mọ pe idakeji naa le ṣẹlẹ pẹlu." Kim lo sọ bẹẹ.