Super Tuesday: Kí ni ìtumọ̀ àti pàtàkì rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, EPA
Àwọn olùdibo jákejádò ilẹ Amerika ń gbìyànju láti kopa nínú ètò ìdìbò ọdun 2020 ti yoo wáye ni orílẹ̀-ede Amẹrika.
Lẹ́yin ọdun kan ti asoju ẹgbẹ́ Democratic ti darapọ mọ idije láti dupo pẹ̀lú ààrẹ to wà lori oyè Donald Trump, o ti wá de Super Tuesday bayii.
Ipìnlẹ̀ mẹ́rìnlá ni yóò dìbò láti yan ọmọ ẹgbẹ́ Democrat ti wọ́n ba fẹ́ ko dije nínú oṣù kọkànlá ọdun 2020 lásìkò ìdìbò.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ jẹ́ ká dá ìbọn kọjá, tó bá jẹ́ pé Oluwo kò fìyà jẹ́ mí - Agbowu
- Ilé aṣòfin Oyo àti Ogun buwọ́lu àbádòfin ikọ̀ aláàbò Amotekun
- Nǹkan yan, kò sí àmì ìfẹ́ mọ́! Ìbọ̀wọ́ tàbí ìfẹnukora d‘èèwọ̀ torí Coronavirus
- "Ẹ gbà wá o! òru láwọn adigunjalè fi ń yọ gbogbo ẹ̀yà ara ọkọ̀ wa l‘Eko, dípò kí wọ́n ji gbé lọ"
- ₦200m là ń pa wọlé lóṣooṣù, àmọ́ ẹ̀rọ àmúnáwá 75 tà ń lò, ń gbé owó lọ - Olùdarí UCH
- Coronavirus tún rán oníṣẹ́ ikú sí Saudi Arabia, orí omi ló gbà wọlé!
- Pa Kasumu tó ni ohùn ló lọ,ohùn tó fi sílẹ̀ kò ní parẹ́
Bernie Sander lo n lewaju báyìí nínú idibo to wáye, sùgbọ́n nígbà ti yóò fi di ọjọru, yoo ti ye wa yékeyeke ẹni ti wọ́n yoo yàn láti dije dupo ààrẹ.
Kíni ǹkan to ti n ṣẹlẹ̀?
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Democrats jakejado ilẹ̀ Amerika ti ṣe oníruuru wọlewode, láti ṣe ìpàdé sùgbọ́n ìdìbò gbàngba ni wọn yoo pada ṣe to bá yá.
Aṣeyori Bernie Sander jẹ ǹkan to ya ni lẹ́nu diẹ. Senator Vermont kúna ti ibo rẹ si ja mọ Hillary Clinton lọ́wọ́ ni ọdun 2016.
Ọkan nínú wọ́n to jẹ́ ìgbákeji ààrẹ nigbà kan ri, Joe Biden, ti ròó pin ki o to gbe igba oroke ni South Carolina lọ́jọ́ Satide.
Ẹ̀wẹ̀, ǹkan ti bẹ̀rẹ̀ si ni yatọ ni kéte ti àwọn ti wọn jọ n fi igagbága, bii Pete Buttigieg àti Amy Klobuchar ni àwọn ko ṣe mọ, ti wọn si yan Biden.
Kíní ìdi ti Super Tuesday fi ṣe kókó?
O ní ṣe pẹ̀lú gbogbo àwọn asoju .
Fun àpẹrẹ ti olukopa A ba ri atilẹyin to pọ ni ipinlẹ̀ kan ju asoju B lọ, wọn yoo fun asoju A ni ipò to pọ julọ, ti olukopa keji yoo si ni diẹ.
Awọn asoju pọ̀ ju ara wọ́n lọ ni àwọn ìpínlẹ̀.
To ba ya, àwọn asoju náà ni yóò wa lọ dibo fún olùkopa to ba wù wọ́n, eyi si ni yoo di asoju fun ẹgbẹ Democrat.
Nkan to ṣe pataki ni pe olùkopa kọọkan gbọdọ ni iye ipo to pọ ju ti gbogbo àwọn to ku lọ, awọn àsoju naa si din mẹ́wàá ni ẹgbẹ̀run meji.
Ibi yìí ni Super Tuesday ti jẹ yọ.

















